“Gbajúmọ̀ ni mí láàyè ara mi ṣùgbọ́n ṣé bí ọmọkùnrin ṣe ń rí ni mo rí yíì”- ìrora àwọn olùwọ́de Nàìjíríà

Àkọlé fídíò, “Gbajúmọ̀ ni mí láàyè ara mi ṣùgbọ́n ṣé bí ọmọkùnrin ṣe ń rí ni mo rí yíì”
“Gbajúmọ̀ ni mí láàyè ara mi ṣùgbọ́n ṣé bí ọmọkùnrin ṣe ń rí ni mo rí yíì”- ìrora àwọn olùwọ́de Nàìjíríà

Ni Ọjọbọ, ọjọ kini oṣu kẹjọ ọdun 2024, awọn ọmọ Naijiria kan lawọn ipinlẹ kan lorilẹede Naijiria gunle iwọde lati fi ẹhonu wọn han lori bi ilu ṣe le ti ebi ati iṣẹ si n mu awọn eeyan bi omi.

Bi iwọde naa ṣe rinlẹ lawọn agbegbe kan ni a rii ti ko waye lawọn ipinlẹ miran. Lara awọn agbegbe to ti waye, bi o ṣe lọ nirọwọrọsẹ lawọn ibi kan naa lo mu wahala dani lawọn ibomiran. Bi awọn kan ṣe n wọde tako ijọba lawọn kan naa wọde lati fi atilẹyin han fun ijọba Tinubu pẹlu alaye pe o yẹ ki araalu ṣi fun Aarẹ to wa loye lanfani akoko diẹ si lati yanju awọn igbesẹ atunto to n gbe lori ọrọ aje Naijiria.

Ọpọ awọn to jade lasiko iwọde naa ni wọn kerora inira ti wọn n koju lọwọlọwọ.

Bi o tilẹ jẹ wi pe iwọde naa bẹrẹ nirọwọrọsẹ lọjọbọ, nigba ti ọjọ yoo fi kanri ọpọ awọn ipinlẹ ni ọr ti ba ibomiran yọ ti dukia olowo iyebiye ti nu, ti ọpọ ẹmi si faraṣeṣe.

Awọn oluwọde naa ni arọni o wale onikoyi o sinmi ogun lọ lawọn yoo fi ṣe nitoripe yoo tun tẹsiwaju lọjọ Ẹti. Amọṣa awọn agbofinro ati ijọba lẹka gbogbo ti n sọ wi pe, lootọ lawọn oluwọde lẹtọ labẹ ofin lati wọde, amọṣa awọn ko ni la oju awọn silẹ ki awọn kọlọransi ẹda kan lo anfani iwọde naa boju fi da wahala silẹ lawujọ.