Àwọn olùwọ́de tún ṣe ìwọ́de fún ọjọ́ kejì nílùú Eko lórí ìfẹ̀hónúhàn #EndBadGovernance

Ètò káràkátà ti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbéra padà ní ìpínlẹ̀ Eko, ẹkùn gúúsù ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà bí ìwọ́de #EndBadGovernance ṣe wọ ọjọ́ kejì.
Ìwọ́de náà lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀ lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Kìíní, oṣù Kẹjọ tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ àkọ́kọ́, àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò wà káàkiri gbogbo agbègbè láti ri pé kò sí wàhálà níbi ìwọ́de náà.
Àmọ́ àwọn èèyàn kò tètè jáde fún ìwọ́de àti pé iye àwọn tó jáde lọ́jọ́ Ẹtì dínkù jọjọ sí ti ọjọ́ àkọ́kọ́.
Ní ìpínlẹ̀ Eko, àwọn olùwọ́de ní àwọn kò ní wọ inú Freedom Park tí ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n lò fún ìwọ́de náà bí wọ́n ṣe ni pé àwọn kò ní ìgboyà pé ààbò wà fún àwọn nínú páàkì náà.

Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn olùwọ́de mìíràn tí wọ́n ní àwọn kò faramọ ìwọ́de táwọn èèyàn náà ń ṣe dúnkokò mọ́ àwọn olùwọ́de náà.
Àwọn ọlọ́pàá tó wà ní agbègbè náà ni àwọn máa ṣe àrídájú rẹ̀ pé àláfíà jọba ni gbogbo agbègbè tí ìwọ́de ti ń wáyé.
Lára àwọn nǹkan tí àwọn olùwọ́de náà ń bèèrè fún mí fífí òpin sí ọ̀wọ́n gógó, àìsí ààbò tó péye, ìgbógunti ìwà àjẹbánu àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ní ìròyìn sọ pé wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn ni àwọn ìpínlẹ̀ ẹkùn àríwá Nàìjíríà lọ́jọ́bọ̀ táwọn mìíràn sì farapa.
Ọ̀pọ̀ àwọn ìpínlẹ̀ ní ẹkùn àríwá ni ìjọba ti kéde òfin kónílé ó gbélé.


Wo àwọn ìpínlẹ̀ tí ilé ẹjọ́ ti kéde àwọn ibi tí ìwọ́de òní kò gbọdọ̀ dé

Oni ọjọ kinni, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 ni iwọde ‘ebi n pa wa’ gberasọ kaakiri Naijiria.
Iwọde naa lo n waye latari ọwọngogo to gbode ni Naijiria lẹyin ti ijọba Aarẹ Bola Tinubu kede pe oun ti yọ owo iranwọ epo bẹntiro.
Wayi o, bi ọpọ araalu ṣe n mura lati ṣe ifẹhonuhan naa lawọn ijọba bẹrẹ si n ke si awọn araalu kan naa lati maṣe darapọ mọ iwọde ọhun.
Ijọba ni oun ti gbe igbesẹ lati mayedẹrun fun awọn eeyan, nitori naa, ko nilo ki wọn ṣe iwọde.
Amọ ṣa, lẹyin ti gbogbo akitiyan ijọba lati bẹgi dina iwọde naa ja si pabo, o ti gba ile ẹjọ lọ lọna ati paṣẹ awọn ibi ti iwọde naa yoo de.
Ninu erongba ijọba, igbesẹ naa jẹ ọna lati dena irufẹ rogbodiyan to waye lasiko iwọde EndSARS.
Wo awọn ipinlẹ ti ile ẹjọ ti paṣẹ ibi ti iwọde ko gbọdọ de.
Ipinlẹ EKo

Ọgbọn ọjọ, oṣu Keje ni ile ẹjọ giga kan niluu Eko paṣẹ pe awọn eeyan le ṣe iwọde, amọ o ni iwọde naa ko gbọdọ kọja Gani Fawehinmi Freedom Park to wa ni Ojota, ati Peace Park, to wa ni Ketu.
Adajọ Emmanuel Ogundare lo paṣẹ naa lẹyin ti adajọ agba ipinlẹ ọhun, Lawal Pedro, SAN, bẹ ẹ lọwẹ.
Pedro ni igbesẹ naa ṣe pataki lati daabo bo ẹmi ati dukia araalu.
O fi kun pe rogbodiyan to waye ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 ko tun gbọdọ ṣẹlẹ mọ.
Ipinlẹ Ogun
Nipinlẹ Ogun, ile ẹjọ giga kan nibẹ ti sọ pe awọn oluwọde ko gbọdọ kọja agbegbe mẹrin pere lasiko iwọde wọn.
Ile ẹjọ ọhun tun ni iwọde naa ko gbọdọ ju aarin aago mẹjọ aarọ si marun un irọlẹ lọ.
Adajọ Oluwasina Ogungbade sọ pe iwọde naa ko gbọdọ kọja papa iṣere MKO Abiola, Abeokuta; Ansar-ud-Deen Comprehensive High School, Ota; Remo Divisional High School, Sagamu; ati papa iṣere Dipo Dina to wa niluu Ijebu-Ode.
Ipinlẹ Kwara
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Gẹgẹ bii Eko ati Ogun, ile ẹjọ giga Kwara ti sọ ibi kan ṣoṣo ti iwọde ko gbọdọ kọja.
Ninu atẹjade kan loju opo X ijọba ipinlẹ naa, nibi to fi iwe aṣẹ ile ẹjọ naa si, o ni awọn oluwọde ko gbọdọ kọja Metropolitan Square to wa niluu Ilorin.
O ni ẹnikẹni to ba kọja ibi ti oun darukọ yoo jẹ iyan rẹ niṣu.
Ilu Abuja
Adajọ Sylvanus Oriji ti paṣẹ pe awọn oluwọde ko gbọdọ kọja papa iṣere MKO Abiola to wa niluu naa.
O ni yatọ si iwaju papa iṣere ọhun, ẹnikẹni ko gbọdọ ṣe iwọde lagbegbe miran.
Minisita to n ri si ọrọ FCT, Nyesom Wike lo gbe ọrọ naa lọ sile ẹjọ.












