Ìjọba fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní gba owó orí fún níní ológbò, ìdí rèé

Aworan Olongbo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọpọ eeyan to ni Olongbo lo ti bẹrẹ si ni fapajanu lori erongba ìjọba lati bẹrẹ si ni ma gba owó orí fun nini Olongbo lorilẹede Kenya.

Igbesẹ yii ni ijọba n gbe lati bẹrẹ iforukọsilẹ awọn Olongbo yii labẹ orúkọ olowo wọn.

Yoo na olowo Olongbo ni 200 shillings lọdọdun lati gba iwe àṣẹ lati ni Olongbo, ti yoo si ma tun pese ẹri pe Olongbo naa n gba abẹrẹ ajẹsara.

Gẹgẹ bii o se wa ninu abadofin to wa niwaju ile ẹjọ, awọn olowo Olongbo gbọdọ rí pe awọn mojuto Olongbo ni ọna ti ko ni fi awọn eeyan yooku lara pẹlu ariwo.

Ofin ni o wa lati pese igbeaye to rọrun fun awọn Olongbo sugbọn ọpọ eeyan lo si nilo alaye lori ofin tuntun naa.

Bẹẹ ba gbagbe, ìwọde awọn GenZ lo ṣẹsẹ parí ni Kenya nibi ti awọn oluwọde ọdọ ti ọpọ mọ si ‘Gen Z’ ti yabo ile igbimọ aṣofin niluu Nairobi ti i ṣe olu ilu orilẹede Kenya.

Awọn ileeṣẹ tẹlifisan kan ṣafihan bi awọn oluwọde ṣe n gbe ifẹhonuhan lọ si ile aṣofin laarin gbungbun ilu Nairobi lori owo ori ti ìjọba fun kun burẹdi.

Naomi Mutua, ẹni to ni ọpọ Olongbo, to si n pe ara rẹ ni 'Iya Olongbo' sọ fun BBC ni o yẹ ki ijọba ba awọn ajọ ati awọn olowo Olongbo sọrọ ko to di pe wọn gbe ofin jade.

O ni ifilọlẹ gbígba abẹrẹ ajẹsara fun awọn Olongbo lo jẹ nnkan to dara pupọ sugbọn o ni oun ko mọ bí ìjọba ṣe fẹ mu wa si imusẹ.

O le ni ẹgbẹrun meji eeyan to ti padanu ẹmi wọn lati ibi pe aja tabi Olongbo buwọn je.

Mutua ni ohun akọkọ to yẹ kí ofin naa mojuto ni bi igbeaye gbadun awọn Olongbo yoo se gboro si.

Orilẹede Kenya ti wá ṣe agbekalẹ apero kan lati fun awọn olowo Olongbo ni aye lati sọrọ lori ofin naa.

Olori ajọ to n risi igbayegbadun awọn ohun ọsin, Emma Ngugi ni ohun to dara ni ofin naa sugbọn oun ko lero pe o le mojuto igbaaye gbadun awọn Olongbo.

O ni o ṣeese ki ọpọ eeyan le awọn Olongbo wọn síta nitori owo ori..