Wo àwọn ìròyin òfégè tó ń jáde nípa ìwọ́de #EndBadGovernment tó ń lọ lọ́wọ́ ní Naijria

Ọlọkan-o-jọkan iroyin ti ki i ṣe otitọ lo ti n farahan lori ayelujara latigba ti iwọde tako ijọba buruku ti bẹrẹ ni Naijiria lọjọ akọkọ, ninu oṣu kẹjọ ọdun 2024 yii.
Ohun ti awọn afẹhonuhan naa n ke irora fun ju ni pe nnkan ko dẹrun lẹka ọrọ aje orilẹede yii. Ọjọ mẹwaa si ni wọn gbero lati fi ṣe e titi ti ijọba yoo fi dahun si ipe wọn.
Ṣugbọn o jọ pe awọn oluwọde ati ijọba funra rẹ ti gbe awọn iroyin kan ti ki i ṣe otitọ jade lati tako ara wọn.
Àwòrán tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kano fi síta

Oríṣun àwòrán, NG Police
Nigba ti iwọde yii di rogbodiyan nipinlẹ Kano, ti wọn n ji ọja awọn eeyan ko ti wọn si n ba dukia jẹ, awọn ọlọpaa pada mu awọn eeyan kan lorii rogbodiyan naa.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kano, Abdullahi Haruna Kiyawa, fi awọn aworan kan sita to n ṣafihan awọn eeyan tọwọ ba pe wọn ji ẹru ẹlẹru ko lọjọ akọkọ iwọde naa.
Ṣugbọn bi awọn fọto naa ṣe bọ sori ayelujara ni Omoyele Sowore, ajafẹtọọ ọmọniyan ati oludije ipo aarẹ lorilẹede yii, sọ pe irọ ni ọlọpaa Kano pa pẹlu aworan naa.
Sowore kọ ọ si oju opo X rẹ, pe aworan iṣẹlẹ ọdun 2011 ni Alukoro ọlọpaa Kano fi sita ni 2024.
O ni ibanilorukọjẹ ni iwa ti ileeṣẹ ọlọpaa Kano hu pẹlu awọn fọto iṣẹlẹ atijọ ti wọn ṣẹṣẹ gbe jade bii tuntun yii.
Bakan naa ni Sowore tun gbe awọn fọto kan ti ileeṣẹ ọlọpaa Kano fi sita nipa awọn ọdaran si oju opo X tiẹ naa, o si sọ pe fọto ọdun 2011 ni.

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore@ X
Ṣé fọ́tò ìwà ọ̀daràn 2011 ni ọlọ́pàá Kano fi síta ní 2024 lóòótọ́?

Oríṣun àwòrán, NG Police
Ẹka iroyin BBC ṣe iwadii kikun lori ohun ti Sowore sọ yii, a si ri i pe irọ gbuu ni .
Iwadii BBC fi han pe fọto iṣẹlẹ iwọde ebi n pa wa to gbode kan bayii ni Alukoro ọlọpaa Kano, Abdullahi Kiyawa, fi sita.
Ọpọlọpọ fọto awọn tọwọ ba lasiko iwọde yii ni Kiyawa ti fi si oju opo rẹ, eyi ti Sowore sọ pe ọdun 2011 ni ọlọpaa yii ti gbe e si oju opo naa.
Ọdun 2019 ni Abdullahi Haruna Kiyawa di Alukoro ọlọpaa Kano, awọn fọto ti Sowore n pe ni ti iṣẹlẹ atijọ yii ko si si loju opo ọlọpaa naa ni 2011.
Bakan naa, Kiyawa han ninu fọto kan pẹlu awọn afurasi ọdaran tọwọ ba naa, ṣugbọn ni 2019 to di alukoro ọlọpaa Kano ni eyi, ki i ṣe 2011 bi Sowore ṣe wi.
Yatọ si eyi, aṣọ ọlọpaa ti Haruna Kiwaya wọ ninu fọto naa jẹ eyi ti wọn n lo ni 2012, to yatọ si ẹri ti Sowore n tọka si.
Paripari rẹ ni pe ikọ BBC to wa ni Kano naa ya awọn aworan to jẹ oriṣii kan naa ti ọlọpaa fi sita yii, eyi to n ṣafihan awọn ọja ti wọn ni awọn afurasi naa ji ko.
Ileeṣẹ ọlọpaa Kano paapaa ti fi ọrọ lede lori ẹsun ti Omoyele Sowore fi n kan won yii, wọn ni ki ẹnikẹni ma ṣe gba a gbọ rara.
Peter Obi kọ́ ló léwájá ìwọ́de
Iroyin ofege mi-in to tun gbode ni pe oludije funpo aarẹ Naijiria ninu ẹgbẹ Labour, Peter Obi, lo lewaju iwọde to n lọ lọwọ yii niluu Abuja.
Iwadii BBC ko ri ẹri kan to fidi ẹ mulẹ pe Peter Obi lo wa nidii iwọde yii bi awọn kan ṣe n gbe e kiri.
Ikọ iroyin BBC ṣalabapade fidio kan to jade lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹfa ọdun 2024 yii, eyi to n kede atilẹyin fun Santa Ireti Kingibe, ti oun naa wa ninu fidio ọhun.
Ṣugbọn awọn oloṣelu mejeeji yii ti ni fidio naa ki i ṣe tuntun.
Ninu awijare rẹ, Peter Obi sọ pe lasiko ti oun ṣabẹwo si olu-ile ẹgbẹ Labour ni wọn ya fidio naa.
O ni oun lọọ pẹtu si aawọ to n waye laarin ẹgbẹ naa ati ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ (NLC) ni.
" Wọn po fidio yẹn po lati ṣe abosi ni, awọn to si wa nidii ẹ yoo ti gba owo iṣẹ wọn. Iru aiṣododo bayii ko daa ninu ijọba awarawa, nibi to ti yẹ ki otitọ jọba.’’
Peter Obi lo sọ bẹẹ.
Loootọ, Peter Obi faramọ ẹtọ awọn eeyan lati wọde, ṣugbọn ko si ẹri to foju han pe oun lo ṣeto rẹ tabi kopa nibẹ.













