Ìtàjẹ̀sílẹ̀, rògbòdìyàn: ọ̀gá ọlọ́pàá ní àwọn kò tẹ ẹ̀tọ́ àwọn olùwọ́de mọ́lẹ̀.

Oga olopaa pata ni Naijira, IGP Kayode Egbetokun

Oríṣun àwòrán, Kayode Egbetolun X handle

Àkọlé àwòrán, Oga olopaa pata ni Naijira, IGP Kayode Egbetokun
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Lẹyin ti iwọde ebi n pa wa di rogbodiyan, ti itajẹsilẹ si waye lawọn ipinlẹ kan lorilẹede yii, awọn eeyan ti n naka aleebu si ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa lori ohun to ṣẹlẹ naa.

Ṣe iroyin ti n sọ ọ di mimọ pe ko din ni eeyan mẹtadinlogun to ti ku bayii latari iwọde ọjọ akọkọ ninu ọjọ mẹwaa ti wọn fẹẹ ṣe.

Awọn ipinlẹ bii Kano, Gombe, Borno, Yobe, Jigawa, Bauchi, Abuja, Kaduna ati Niger ni rogbodiyan ti bẹ silẹ, wọn sọ iwọde naa di ole jija, ẹmi awọn eeyan kan si ba a lọ.

Ẹrọ tajutaju ti awọn ọlọpaa yin si awọn eeyan lasiko iwọde naa niluu Abuja tun jẹ idi kan ti awọn araalu fi n sọ pe ọlọpaa ko huwa ọmọluabi fun awọn oluwọde.

Ati pe ẹmi awọn eeyan to bọ ko ṣẹyin awọn agbofinro yii.

Koda, fidio kan ṣafihan ibi ti wọn ti mu akọroyin kan ti wọn si fiya jẹ ẹ.

Lati tan imọlẹ si ọrọ naa, ọga ọlọpaa pata lorilẹede yii, IGP Kayọde Ẹgbẹtokun, fi atẹjade sita kan lọjọ keji, oṣu kẹjọ ọdun 2024.

Wo awọn awijare ọlọpaa Naijiria.

Ṣaaju iwọde yii ni a ti fi ikilọ ọlọkan-o-jọkan sita, pe awọn kan ti n ko awọn ọdọ jọ lati da wahala silẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bẹẹ lawọn kan n sọ pe iwọde wọọrọ lawọn fẹẹ ṣe, ṣugbọn iṣesi wọn ko jọ bẹẹ. Wọn ko si fẹẹ sowọpọ pẹlu ọlọpaa lati ri i pe ifẹhonuhan naa ko di rogbodiyan.

* Bi a ṣe ri eyi la ti ni ki wọn fagile iwọde ọhun. Awọn kan taku pe awọn yoo ṣe e ni, a ni ki wọn duro loju kan, ka le baa da aabo bo wọn ati dukia wọn.

* Ara fu wa pe awọn kan ṣi fẹẹ fa wahala, nitori wọn ko fẹran ijọba to wa lode yii.

*Ṣugbọn pẹlu ifura naa, a fi iwa ọmọluabi ati ọgbọn iṣẹ ti a kọ, ṣiṣẹ wa. Awọn ọlọpaa wa kaakiri lati ri i daju pe ko si rogbodiyan.

*Ṣugbọn o ṣe wa laanu pe ole jija ati jagidijagan ni awọn kan sọ ifẹhonuhan tiwọn da.

Awọn ti wọn fẹẹ wọde ko yọju, awọn ọmọ-ita waa gbode kan, wọn n ja awọn ọmọ Naijiria lole.

Meji naa ni ero awọn wọnyi, ole jija ati biba dukia ijọba ati ti araalu jẹ.

Wọn ti ṣọṣẹ nla ni Kano, Borno, Yobe, Kaduna, Gombe, Bauchi, FCT Abuja, Niger, Jigawa. Wọn ti ba awọn agọ ọlọpaa jẹ kiri, wọn ti gbiyanju lati wọle ijọba, wọn ji nnkan ijọba, wọn fọ ile ikẹru si, wọn si ba ọpọlọpọ nnkan jẹ.

* Bi kootu ṣe paṣẹ pe ki wọn ma ṣe iwọde kọja papa iṣere l’Abuja, awọn eeyan naa ko gba. Wọn tu si oju popo, sibẹ, awọn ọlọpaa tun pese aabo fun wọn.

Ko sibi kan ti a ti tapa sofin ijọba tabi tẹ ẹtọ awọn eeyan oluwọde mọlẹ.

Aworan ile kan to n jona lasiko iwode naa

Oríṣun àwòrán, BBC

Aworan awon oluwode

* Ni awọn ilu bii Abuja, Kaduna, Kano ati Gombe pẹlu awọn mi-in, wọn ṣe awọn agbofinro leṣe gan-an ni. A gbọ pe wọn pa ọlọpaa kan, ọpọ si farapa yanna-yanna.

* A si kuku ti sọ tẹlẹ, pe awọn amookunṣika le ja iwọde yii gba lati ṣe jamba fawọn ero to ba kora jọ.

Niluu Eko lanaa, olobo ta wa pe ohun to fara jọ nnkan oloro abugbamu wa lagbegbe Bank Anthony Way, n’Ikeja. Awọn eeyan wa sare debẹ, wọn ba a bẹẹ, wọn si dẹkun ohun ti ko ba fa ijamba nla naa.

* Lonii, nipinlẹ Borno, eeyan mẹrin lo ku nigba ti ibugbamu waye laarin awọn to n fi ẹhonu han, eeyan mẹrinlelọgbọn si tun farapa, ẹsẹ kan aye-ẹsẹ kan ọrun ni pupọ ninu wọn wa bayii.

*A n rọ gbogbo ọmọ Naijiria to n tẹle ofin ilẹ yii, lati maa gbọ ikilọ awa ọlọpaa, ki wọn si maa tẹle e. Ki wọn ma ṣe gbọ ikilọ wa ni agbọ-gbọn-eti nu, nitori oye lagba n wo la fi n gbe ikilọ tiwa jade.

* Lori eyi to n ṣẹlẹ lọwọ yii naa, ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti paṣẹ pe ki gbogbo ẹkùn rẹ wa lojufo. A ti da awọn ọlọpaa sita lati tete dahun nibi gbogbo ti araalu ba ti nilo aabo.

A duro ṣinṣin lori dida aabo bo ẹmi ati dukia awọn eeyan, ki ofin si fẹsẹ mulẹ bo ṣe yẹ.

* Ni ti awọn ẹgbẹ ti wọn n sa sabẹ ẹtọ lati fi ẹhonu han, ti wọn waa n da omi alaafia ilu ru, ki wọn maa ranti pe ofin to faaye gba wọn lati fi ẹhonu han naa lo paṣẹ fun wọn lati tẹle aṣẹ ijọba ilẹ wọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti gbaradi lati koju iṣẹlẹ to ba n ṣẹlẹ lasiko yii, to ba si di dandan lati beere fun iranlọwọ latọdọ awọn agbofinro yooku, titi to fi mọ awọn ologun, a maa beere fun un.

* A rọ gbogbo araalu Naijiria lati ma ṣe kaya soke, ki wọn ran ọlọpaa ati awọn agbofinro yooku lọwọ lasiko to lagbara yii. Awa naa yoo si ri i daju pe a n sa gbogbo ipa wa lati ri i pe alaafia n jọba lorilẹede wa.

*Ẹ ṣeun.

Bayii ni IGP Kayode Egbetokun wi ninu atẹjade rẹ.

Ṣugbọn pẹlu awijare awọn ọlọpaa yii naa,ọpọ eeyan lo ṣi n bu ẹnu atẹ lu wọn lori ayelujara latari iwọde to di rogbodiyan lọjọ akọkọ to bẹrẹ ọhun.

Aworan awọn ọlọpaa ati ọkọ̀ wọn