Wo àwọn kókó tí arààlú ń fẹ́ kí Tinubu mẹ́nubà ṣùgbọ́n tí Aàrẹ kò sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀

Aworan Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Tinubu/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Nigba ti iroyin jade pe Aarẹ Bola Tinubu yoo ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lọjọ Aiku, ọjọ kẹrin oṣu kẹjọ ọdun 2024 yii, ireti ọpọ eeyan ni pe ohun ti yoo yanju iṣoro araalu ti yoo si dẹkun iwọde ni Aarẹ yoo sọ.

Ṣugbọn bi igba ti ireti awọn ọmọ Naijiria ja sofo ni ọrọ naa ri lara awọn eeyan nigba ti Aarẹ Tinubu pari ohun to fẹẹ sọ.

Ẹsẹkẹsẹ ni awọn to n wọde ti sọ pe awọn ko ni i fopin si ifẹhonuhan to n lọ lọwọ lorilẹde yii, nitori Tinubu ko mẹnuba bi iṣoro ebi to n pa araalu yoo ṣe dopin.

Wọn ni Aarẹ ko loun yoo da owo ori iranwọ to yọ pada, owo to jẹ latigba ti Tinubu ti yọ ọ ni inira ti ba gbogbo ẹka pata ni Naijiria .

Ọpọ eeyan lo n sọ pe Tinubu n pọn ara rẹ le ninu ọrọ to sọ naa, o n ka ohun to ṣe ti araalu ko ri, ko si sọrọ sibi naira ti ko niye lori mọ, ọwọngogo ọja, aisi owo lọwọ araalu, ebi, ìṣé ati oṣi, ai si aabo to gbalẹ kankan ati bẹẹ bẹẹ lọ.

BBC Yoruba ṣe atupalẹ aroye ati ẹhonu awọn ọmọ Naijiria loju opo ayelujara kiri, wọnyi ni abọ ohun ti araalu reti ninu ọrọ Tinubu ṣugbọn ti Aarẹ ko sọ.

Ero araalu loju opo BBC Yoruba
Ero araalu loju opo BBC Yoruba
Ero araalu loju opo BBC Yoruba
Ero araalu loju opo BBC Yoruba
Ero araalu loju opo X

Oríṣun àwòrán, X

Ero araalu loju opo X

Oríṣun àwòrán, X

Wọ̀nyí ni èrò díẹ̀ nínú àwọn èèkàn ìlú lórí ọ̀rọ̀ Ààrẹ

Amofin agba Femi Falana:

Amofin agba nilẹẹ Naijiria to tun jẹ ajafẹtọọ ọmọniyan, Femi Falana, sọ pe ọrọ Aarẹ Tinubu ko tiẹ gba ibi kankan yanju ohun ti awọn afẹhonuhan n wi rara.

O ni bi Aarẹ ko ṣe sọ pe oun yoo da owo iranwo ori epo to yọ pada ko tun nnkan ṣe.

Ninu atẹjade kan ti Amofin Falana fi sita lọjọ Aiku naa lo ti ni bijọba ba gbogun ti awọn to n jẹ ajẹbanu lẹka epo rọbi, ti wọn si bẹrẹ si i fọ epo nibudo ifọpo ilẹ yii, ko ni i si idi kankan fun owo iranwọ to da wahala silẹ yii.

Falana sọ pe bijọba ṣe fi ọrọ awọn oluwọde naa gun lagidi yii le mu ki wọn maa tẹsiwaju ninu ifẹhonu han wọn.

Ọjọgbọn Wole Soyinka: Ninu ọrọ Ọjọgbọn Wole Soyinka, o ni Aarẹ Tinubu kuna lati koju ohun ti awọn oluwọde n beere fun.

Ifẹhonuhan n waye nitori iya to n jẹ araalu, Soyinka sọ pe awọn ilana ti Tinubu la kalẹ ko le yanju ohun ti araalu n fẹ.

O ni o buru bawọn agbofinro ṣe n koju awọn to fi ẹhonu han, o si ti yẹ ki Naijiria kọ ilana iru eyi silẹ patapata.

Aworan Ọjọgbọn Wole Soyinka

Oríṣun àwòrán, Others

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP: Ẹgbẹ oṣelu alatako, Peoples Democratic Party (PDP), sọ pe ijọba APC ko ka ọrọ awọn ọmọ Naijiria kún rara.

PDP sọ pe awọn lawọn jẹ ki Tinubu sọrọ, sibẹ, o ṣeni laanu pe ọrọ ti ko tan iṣoro Naijiria lo tun ti ẹnu Aarẹ jade.

Wọn ni kedere lo han pe nnkan ti daru mọ awọn APC lọwọ, o si yẹ ki wọn gba pe awọn ti kuna nibi ojuṣe wọn si araalu.

PDP pe Aarẹ Tinubu lati ri si iṣoro epo rọbi, ọwọngogo ounjẹ, atunṣe owo naira ati ipese ounjẹ fun araalu.

Ohanaeze Ndigbo: Apa kan ẹgbẹ awọn ẹya Igbo, Ohanaeze Ndigbo, sọ ninu ọrọ tiwọn pe bi Tinubu ba loun yoo da owo iranwo epo, sọbsidi pada ni, awọn oluwọde ko ba fagile ẹhonu wọn .

Ninu atẹjade ti Ohananeze Ndigbo fi sita lọjọ Aiku naa, eyi ti Akọwe wọn, Mazi Okechukwu Isiguzoro buwọ lu nu wọn ti ni bi Tinubu ba yanju iṣoro sọbsidi yii, nnkan yoo pada sipo ni Naijiria.

Kòròfo ni ọ̀rọ̀ ti Tinubu bá aráàlú sọ- Atiku Abubakar

Alaaji Atiku Abubakar to du ipo aarẹ pẹlu Tinubu ni 2023, sọ nipa ọrọ Aarẹ Tinubu korofo lasan ni.

Yatọ si pe ọrọ Aarẹ ko tẹ araalu lọrun, ohun kan tun wọn tun n sọ ni pe ọrọ ọhun ti lu sita lori ayelujara ki Tinubu too ka a rara. Wọn ni Aarẹ wulẹ waa mu ọmọ Naijiria ṣere pẹlu akoko wọn ti wọn fi tẹti si i ni.

Aare Bola Tinubu ati Alaaji Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, Facebook