Wo òògùn ikọ́ mẹ́rin tó ti gbẹ̀mí ọmọdé 66 l‘Áfíríkà - WHO

Obinrin kan di igo ogun olomi mu

Oríṣun àwòrán, who

Ajọ ilera agbaye ti pariwo sita nipa awọn oogun ikọ mẹrin kan, ti wọn ni o ṣeeṣe ko nii ṣe pẹlu iku ọmọde mẹrindinlaadọrin,mẹrindinlaadọrin lorilẹede Gambia.

Ajọ WHO ni oogun ikọ naa ni wọn ti fihan pe o nii ṣe pẹlu ọgbẹ inu, kidinrin ati iku awọn ọmọde mẹrindinlaadọrin naa.

Ileeṣẹ apoogun kan lorilẹede India ti orukọ rẹ n jẹ Maiden Pharmaceuticals, ni wọn sọ pe o po ogun naa.

WHO ni ileesẹ naa si lo ti kuna lati fi ẹri kalẹ nipa alaafia awọn to lo o.

Oogun ikọ to n jẹ Promethazine Oral Solution, Kofexmalin Baby Cough Syrup, Makoff Baby Cough Syrup ati Magrip N Cold Syrup lo n gbẹ̀mí àwọn ọmọde - WHO

Lasiko ti iroyin yii fi jade, ileeṣẹ apogun naa ko tii sọ ohunkohun lori rẹ.

Ileeṣẹ BBC ti kan si ileeṣẹ apogun Maiden Pharmaceuticals fun alaye tiwọn lori eyii.

Awọn alaṣẹ lorilẹede India ni awọn ti kan si ajọ ilera agbaye, WHO pe ko fi ẹri to so iku awọn ọmọde naa, pọ mọ ogun ikọ ti ileeṣẹ naa ṣe ṣọwọ si awọn.

Ajọ WHO ni orukọ awọn ogun ikọ naa ni Promethazine Oral Solution, Kofexmalin Baby Cough Syrup, Makoff Baby Cough Syrup ati Magrip N Cold Syrup.

Ajọ agbaye naa ṣekilọ pe elo ogun naa lee fa ọgbẹ tabi iku, paapaa laarin awọn majesin.

Aworan awọn ọmọde meji

Oríṣun àwòrán, who

Awọn oogun ikọ asekupani yii ti gba ọna fayawọ kọja sawọn orilẹede Afirika miran"

Ajọ eleto ilera lagbaye wa yan pe wọn ti ri awọn ogun ikọ mẹrẹrin yii lorilẹede Gambia.

Who ni awọn oogun ikọ naa tun ti gba ọja okunkun fayawọ tawọ si awọn orilẹede miran tabi awọn agbegbe miran ni Afirika.

Ajọ WHO da si ọrọ naa nigba ti awọn alaṣẹ lorilẹede Gambia kẹẹfin pe iye awọn to n ni ọgbẹ inu ati aisan kidinrin pọ sii laarin awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun marun un lọ loṣu keje.

Lati igba naa ni awọn alaṣẹ ijọba lorilẹede Gambia ti fofin de lilo ogun olomi naa, to si tun ni awọn eeyan rẹ ko gbọdọ lo oogun ikọ onikoro to jẹ ti ileesẹ apoogun naa.

Ajọ WHO sọ pe ayẹwo ogun naa nibudo ayẹwo igbalode fihan pe “ o ni eroja diethylene glycol ati ethylene glycol ninu wọn pẹlu odiwọn ti ko dara to”.

Awọn alaṣẹ eto ilera lorilẹede Gambia sọ pe loṣu to kọja, ọpọ awọn ọmọde lo ṣalaisi lai sọ iye wọn ni pato.

Aworan awọn ogun kan

Oríṣun àwòrán, who

O le jẹ awọn ogun to ni eroja kotọ ni ileeṣẹ apoogun yii ko ranṣẹ si Gambia - India

Ninu ọrọ to sọ nilu Geneva, oludari agba ajọ ilera agbaye, Tedros Ghebreyesus sọ pe: “Ohun to kọja ibanujẹ ati iporuru ọkan ni iku awọn majesin naa jẹ fun awọn mọlẹbi wọn.”

Ileeṣẹ akoroyinjọ AFP sọ pe gẹgẹbi ohun to jẹyọ ninu lẹta ori ayelujara kan ti ajọ ilera agbaye naa fi sita, ajọ to n ṣe ayẹwo ati amojuto ogun ni India sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ pe awọn ogun to ni eroja kotọ ninu wọn, ni ileeṣẹ apoogun yii ko ranṣẹ si orilẹede Gambia.

Ajọ WHO sọ pe o dara ki gbogbo agbaye mọ nitori pe ileeṣẹ apoogun yii tun lee lo awọn eroja ti ko dara to yii, sinu awọn ogun miran to n pin lorilẹede naa tabi pin kaakiri si oke okun.