"Àlàyé rèé tí mó ṣe yọ ike tí mo fikún ìkébè mi, kó lè tóbi"

Ara meeriri, mo ri ori ologbo lori atẹ ree o, abi ki ni ka ti pe iṣẹ abẹ oore koore lati se afikun ikebe tabi yọ kuro nibẹ.
Gbajumọ ọmọ orilẹede Kenya kan, Vera Sidika ti kede pe oun ti tu idi onike ti oun ṣe pẹlu iṣẹ abẹ lati mu ki idi oun tobi sii.
Vera ṣe afihan ayipada to ṣe si ara rẹ yii loju opo Instagram rẹ.
O ni nigba ti oun ro awọn ijamba ilera ati wahala to lee ti tidi ikebe abaadi naa yọ fun oun, lo mu ki oun lọ yọ ike ti oun fi si idi oun.
O ṣalaye lori instagram rẹ pe “lootọ ni ijamba ati ewu wa pẹlu iṣẹ abẹ gbingbin ike si idi lati tobi sii.
Wahala rẹ si maa n kọja afẹnusọ, bẹẹ ni awọn eeyan kan kii sii ru u la.”
"Mo ti gba lati fẹran ara mi bi Ọlrun se da mi laisi afikun kankan"
O fi kun un pe , “asiko ipenija nla niyi fun mi. Mo nilo lati ṣe iṣẹ abẹ yii.
Ohun iyalẹnu ni ṣugbọn mo ti gba lati fẹran ara mi bi mo ṣe ri laisi afikun kankan.
Sidika jẹ gbajumọ ni Kenya nitori idi nla to ni ṣugbọn arabinrin naa, to ti bi ọmọ kan ṣalaye pe oun pinnu lati yan igbaye-gbadun alaafia laayo dipo idi nla.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
"Ọrọ mi yoo jẹ arikọgbọn fawọn to ba n gbero lati sisẹ abẹ"
Vera to jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgbọn sọ pe ọpọlọpọ igba loun maa n ri awọn aworan awọn eeyan ti iṣẹ abẹ ayipada ara ti ja si wahala nla fun.
“Mo maa n ro o pe boya tori pe dokita to ba wọn ṣe e ko gbona to ni ṣugbọn kii ṣe bẹẹ, atubọtan wa, igba to ba kan eeyan leeyan to maa mọ.”
Vera Sidika sọ pe ero oun ni pe ọrọ oun yoo jẹ arikọgbọn, ti yoo mu igbe aye ọtun ba awọn eeyan to ba n gba a lero lati ṣe iru nnkan bayii.
Irinajo Vera Sidika lori ọrọ ara rẹ
Lọdun 2019, Vera Sidika pinnu lati dẹkun ara bibo.
Nigba to di oṣu kejila ọdun 2020 lo fihan loju opo Instagram rẹ pe agbelẹrọ ni eyin oun o.
O ni “awọn kan n sọ pe mi o le duro de igba ti maa pe aadọrun ọdun, ki n to ka gbogbo eyin mi.
Mo ti lọ ka gbogbo eyin mi o nitori pe agbelẹrọ lasan lawọn eyin mi ti ẹ n ri.”
Ọrọ ẹya ara rẹ ti fa ọpọlọpọ awuyewuye lori oju opo tik-tok lorilẹede Kenya atawọn orilẹede miran.
O sọ nipa bi o ṣe fọn ọmu rẹ, ko tobi sii ati bi dokita ṣe fọn ọmu rẹ naa, ki oun lee fun ọmọ to bi lọdun to kọja lọyan mu.
Ipinnu Vera lati yọ ike to fi si idi ara rẹ n waye lasiko ti awọn ilumọọka miran n lepa ati ṣe atunṣe ẹya ara wọn.

Oríṣun àwòrán, Vera sidika/ instagram
Bi awọn to n fọn idi wọn ṣe n pọ sii ati wahala atubọtan ti wọn n koju
Vera Sidika kii ṣe akọkọ ti yoo ṣe iṣe abẹ lati fọn idi wọn ko le tobi sii.
Ni oṣu keje ọdun 2020, gbajumọ obinrin oniṣowo kan, Ọmọtọla Taiwo ti ọpọlọpọ eeyan mọ si ‘Omohtee’ sọ fun BBC nipa awọn ohun to n laa kọja lẹyin to lọ ṣe iṣẹ abẹ si idi rẹ ko le e tobi.
O sọrọ nipa awọn omi to n jade lara rẹ ati irora to n laa kọja lẹyin oṣu mẹfa to ṣe iṣẹ abẹ yii.
Dokita oniṣẹabẹ atiṣun ara kan lorilẹede Cameroun, Dokita Oben Sammy sọ fun BBC pe “ọkan lara awọn wahala iṣẹ abẹ ara ni ohun ti wọn n pe ni ‘thromboembolism’.
Eyi si lo tumọ si pe ọra ara yoo wọ inu ẹjẹ tabi ki omi maa korajọ sinu wọn, ti awọ ara eeyan si lee ku patapata.”
O fi kun un pe iṣẹ abẹ atunṣe ara dara ṣugbọn o ni ọpọlọpọ wahala.”
Gẹgẹbi ohun ti ẹgbẹ awọn dokita oniṣẹ abẹ atunṣe ẹya ara, British Association of Aesthetic Plastic Surgeons sọ, idi Brazil ti wọn n pe ni Brazilian Butt lo n mu iku lọwọ julọ.












