Russia ṣe ìkọlù ìdájí sí Ukraine, ó tún fóńtẹ̀ lu agbègbè mẹ́rin tó fipá gbà

Ẹmi eeyan kan ti bọ lasiko ti ikọ ọmọ ogun Russia tun se ikọ silu Zaporizhzhia lorilẹede Ukraine nidaji oni Ọjọru.
Gẹgẹ bi gomina ilu naa, Oleksandr Starukh ti kede loju opo Telegram rẹ, akojọpọ iye awọn eeyan to fori sọta isẹlẹ naa si n lọ lọwọ amọ oun ti le fi iku obinrin kan mulẹ pe o ba isẹlẹ naa lọ.
"A ko tii le fidi rẹ mulẹ boya ẹlomiran si ba isẹlẹ naa lọ amọ a dupẹ lọwọ awọn dokita to n doola ẹmi ọkunrin naa.”
Starukh wa fikun pe eeyan meje lo fara pa, to fi mọ ọmọ ọdun mẹta.
Bakan naa lo salaye pe ikọ adoola ẹmi lasiko ikọlu pajawiri ti doola ẹmi eeyan mọkanlelogun to fori sọta isẹlẹ naa.
Russia buwọ́lù agbègbè mẹ́rin tó f'ipa gbà lọ́wọ́ Ukraine
Aarẹ Russia Vladimir Putin ti buwọlu iwe aṣẹ eyi ti Russia fi sọ awọn agbegbe mẹrin kan to gba lọwọ Ukraine di ara ilẹ rẹ.
Eyi waye tohun ti bi awọn ọmọ ogun Russia ṣe n koju ifidirẹmi lawọn aaye kan.
Iwe naa sọ pe ''a ti gba awọn agbegbe Luhansk, Donetsk, Zaporizhzhia ati Kherson wole si ara orileede Russia.''
Sugbọn ni awọn agbegbe meji kan ninu mẹrin naa iyẹn - Luhansk ati Kherson - Ukraine sọ pe awọn ti n gba awọn abulẹ kọọkan pada lọwọ wọn.

Bakanna Ọgbẹni Putin tun buwọlu aṣẹ kan to fidi gbigba ileeṣẹ nkan ija Nuclear to wa ni Zaporizhzhia rinlẹ.
Lọjọ Ẹti to koja, Putin se ayẹyẹ kan ni Kremlin nibi to ti buwọlu awọn iwe adehun pẹlu awọn olori agbegbe ti wọn gba wọnyii.
Igbesẹ naa waye lẹyin to ṣe eto idibo kan to ni awọn araalu fi fi idunnu wọn han si igbesẹ rẹ lati gba awọn agbegbe yi.
Awọn orileede lagbaye ti bẹnu atẹ lu igbesẹ rẹ yi ti wọn si pe ni idibo makaruru.

Amọ ṣa nkan to n ṣẹlẹ lawọn agbegbe yi yatọ si bi Russia ti ṣe sọ.
Idi ni pe awọn ọmọ ogun Ukraine ti n gba ilẹ pada yala ni Guusu tabi ila oorun ilẹ naa.
Serhiy Haidai, Gomina agbegbe Luhansk to jẹ ọmọ Ukraine sọ fun BBC pe lỌjọru awọn abulẹ mẹfa lawọn ri gba pada lọwọ Russia.
Bẹẹ si ni aarẹ Zelensky sọ pe Ukraine ti jagun gba abule mẹta mii si ni Guusu agbegbe Kherson.
Eyi waye lẹyin ọpọ aṣeyọri ni Kherson lọjọ Iṣẹgun to fi mọ gbigba abule Davydiv Brid to jẹ ibi to ṣe pataki gaan.
Ẹwẹ, ilu Zaporizhzhia to wa ni agbegbe Guusu la gbọ pe wọn rọjo ado oloro le lori ni nkan bi wakati kan ki asuba to.
Awọn alaṣẹ lagbegbe naa sọ peado oloro Russia meje se ikọlu si awọn ile igbe kan ati pe awọn eeyan wa labẹ ile to wo .
A ko ribi fidi ọrọ mulẹ lori iye awọn to fara kasa iṣẹlẹ yi.
Akọroyin BBC Paul Adams to wa ni ilu naa sọ pe awọn oṣiṣẹ adoola n tu ile aṣẹku ile alaja marun un kan to dawo lati doola awọn eeyan.
Aarin ilu ni ile to rẹwa yi wa.















