Putin Russia-Ukraine war: Russia na ìka àlébù sí Ukraine,o ní àwọn ló n ṣekú pa aráàlú wọn ní Kherson

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awa ko la wa nidi iṣekupa awọn araalu yin ni Kherson,ado oloro ti ẹ sọ lo ṣeku pa wọn.
Ọrọ ree lati ẹnu orileede Russia lọjọ Aiku si awọn ologun ti Ukraine.
Saaju ni awọn ikọ ọmọ ogun Russia ti sọ ado oloro si agbegbe Guusu ati ila oorun Ukraine ki wọn to fẹsun yi kan orileede Ukraine.
Ẹwẹ, niṣe lawọn araalu kan moribọ kuro ni ileesẹ to n pese irin ni Mariupol ti wọn ha si nitori ikọlu.

Ni bayi, Moscow ti doju ija wọn kọ agbegbe Guusu ati ila oorun Ukraine lẹyin ti wọn ko ribi gba olu ilu Ukraine, Kyiv lẹyin ikọlu ọlọsẹ mẹsan si ibẹ
Igbiyanju wọn lati gba Kyiv yi ti sọ ilu di ahoro ti awọn ile aimọye ti wo to fi mọ ẹgbẹgbẹrun araalu to padanu ẹmi wọn.
Eleyi ko mọ awọn araalu to le ni miliọnu marun un to sa asala lọ si ilẹ miran.
Awọn ọmọ ogun Russia ti ribi bori ilu Kherson ti eleyi si jẹ ki wọn ribi fẹsẹ mulẹ nibi ti ko jina pupọ si Crimea to wa ni ariwa Russia
- Ọmọ Ọba Charles kàn sí BBC lórí àjọ̀dún ọdún 90 tí BBC bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìròyín, Oríadé sọ̀rọ̀ pé..
- 'Mo bá ajá ní ìbálòpọ̀ nítorí ₦1.4m', ka ǹkan tí òfin Nàìjíríà ṣọ nípa ìwà yìí
- Owó ńlá ti fẹ́ ṣe mí léṣe ní London o! Ẹ wá wo bí mo ṣe ń jayé orí mi bíi skódà - Portable
- Ṣé fífi omi gbóná jó ojú ara lẹ́yìn ìbímọ ní anfààní fún obìnrin?
Iroyin to n tẹwa lọwọ ni pe wọn ti gbalẹ ni ọpọ ibi ni ilu Mariupol to wa jẹ ilu to wa ni ibudo ti ọkọ oju omi n balẹ si ni omi okun Azov
Awọn ọmọ ogun Russia fẹ́sun kan tawọn ti Ukraine pe wọn yinbọn lu ile ẹkọ kan, ile ẹkọ jẹleosinmi ati iboji oku.
Ileeṣẹ ologun Russia ni eleyi waye ni abule Kyselivka ati Shyroka Balka lagbegbe Kherson .
Ileeṣẹ iroyin Russia RIA lo n gbe iroyin yi jade ṣugbọn wọn ko sọ ju bẹ lọ gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Reuters ṣe wi.
Ukraine ko ti fesi si iroyin yi tori naa BBC ko le fidi ọrọ mulẹ ni pato lori ẹsun yi

Oríṣun àwòrán, Reuters
Saaju ni Russia ti kede pe awọn bori ni Mariupol ni ọjọ Kọkanlelogun oṣu Kẹrin toun ti bi awọn ọmọ ogun Ukrain ṣe foripamọ nileeṣẹ to n pese irin ni Azovstal
Ajọ iṣọkan agbaye ti beere fun eto kiko awọn araalu kuro nibẹ.Ni ọjọ Abamta, ọmọogun Ukraine kan sọ pe awọn obinrin ati ọmọde ogun ribi jade ni ahamọ nibẹ.















