Ukraine crisis: Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Ireland kan ṣì ń gbìyànjú ọ̀nà àti sá àsálà kúrò ní Ukraine

Racheal Diyaolu

Oríṣun àwòrán, Racheal diyaolu

Ọmọ ilu Carlow ni Ireland ni Racheal Diyaolu, ẹni ọdun mọkandinlogun, o si jẹ ara omilẹgbẹ akẹkọọ ilẹ okeere to wa ni ilu Sumy nitosi aala ilẹ Ukraine ati Russia.

Lati igba ti Russia ti ṣigun wọ Ukraine loṣu to kọja ni ilu Sumy ti wa labẹ ikọlu.

Racheal sọ fun BBC News NI pe nṣe loun n di ọkan oun si gbogbo ewu ti oun n la kọja

Ni ọjọ Aje, awọn mọlẹbi kan to jẹ ọmọ ilẹ Scotland lo gbe e lọna ati sa asala kuro ni Ukraine.

Racheal ni Irufẹ igbiyanju ati jade kuro lorilẹede Ukraine kan ti kọkọ waye lọjọ Aiku. Nṣe lawọn ọmọogun Russia n yinbọn ikilọ si ọkọ to gbiyanju lati gbe e nigba ti wọn n gbiyanju ati wọ ilu Sumy.

Aworan awọn eeayn nibi kan ti ado oloro ti bọ si

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọmọ orilẹede Ireland mejilelaadọta lo wa ni Ukraine

Ileeṣẹ ọrọ okeere nijọba Ireland ṣalaye fun BBC News NI pe oun mọ pe awọn mọ orilẹede naa mejilelaadọta lo ṣi wa lorilẹede Ukraine.

Ni ọjọ Aiku, awọn ọlọfintoto ajọ UN sọ pe ọtalelọdunrun o le mẹrin eeyan lo ti ku sinu ikọlu Russia naa lati igba to ti bẹrẹ lọjọ kẹrinlelogun oṣu keji ọdun 2022 ṣugbọn wọn ni awọn mọ pe o ṣeeṣe ki iye wọn ju bẹẹ lọ.

Àkọlé fídíò, Èdè Yorùbá dùn ún gbọ́ àti láti sọ, mo sì fẹ́ràn kí n máa sọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà

Ni oṣu kejila dun to kọja ni Omidan Diyaolu fi orilẹede Ireland silẹ lọ kawe ni Ukraine.

Lati igba ti ikọlu naa si ti bẹrẹ lo ti n fara pamọ si awọn aja ilẹ abo lọwọ ikọlu ogun ti wọn kọ si fasiti rẹ nigbakugba tawọn fere olobo ikọlu ba ti dun.

Igbakeji olotu ijọba Ukraine ṣalaye fun BBC pe nṣe ni Russia n kọlu awọn agbegbe taraalu wa, titi kan ileewosan, jẹleosinmi atawn ileẹkọ.

Omidan Racheal Diyaolu

'Mi o tii sọ ireti nu'

Akẹkọọ imọ iṣegun naa ṣalaye pe oun gbiyanju lati maṣe sọ ireti nulori pe oun yoo ṣi pada de ile layọ ati alaafia.

Àkọlé fídíò, Dapo Abiodun ò sọ fún mi pé òun á dupò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì o, èmi nàá ò kẹ̀rẹ̀ nínú òṣèlú láti kékeré - Modele Sarafa-Yusuf

"O nira fun iya mini patakijulọ, ojojumọ lo n kaya soke to si n gbiyanju lati gbọ ohun mi"

Omidan Diyaolu tun ni, "ohun to dara ju ti mo le e ṣe ni lati fi ara balẹ nigbakugba ti mo ba n baa sọrọ lori ẹrọ lọna ati lee fi i lọkan balẹ pe alaafia ni mo wa."

Awọn ẹbi omidan Diyaolu ti n ke si ijọba fun iranwọ lọna ati gbe ọmọ wọn wa sile.

Àkọlé fídíò, Láti sẹ́ńtúrì kẹrìnlá ni ìfaǹfà ti ń wáyé láàárín Russia àti Ukraine

Amọṣa ileeṣẹ ọrọ okeere nijọba Ireland ṣalaye pe awọn ko fẹ sọrọ lori eeyan kan ni pato.

Sugbọn o fidi rẹ mulẹ pe awọn n sọrọ pẹlu awọn ọmọ orilẹede Ireland to wa ni Ukraine lọwọ yii.

Akẹkọọ imọṣegun kan latorilẹede Ireland n gbiyanju ati fi orilẹede Ukraine silẹ lẹyin to ti wa niipamọ fun ọpọlọpọ ọjọ nilu Sumy lẹkun ila oorun Ukraine nibi ti Russia ti n rọjo agba oloro.