Timothy Adegoke: Wo ohun tí ìyàwó Timothy jẹ́rìí nípa ọkọ rẹ̀ nílé ẹjọ́

Iyawo Timothy ati Adedoyin

Ìyàwó olóògbé Timothy Adegoke, Arabinrin Bolatito Adegoke jẹri fún ilé ejò pé ọkọ òun ki n jẹun níta lẹyin ti agbẹjọro olujẹjo Williams Ajayi béèrè lọwọ rẹ bóyá ọkọ rẹ jẹun kò tò lọ sùn ni ile ìtura ni ilu Ile Ifẹ àti pé bóyá ó ṣe aré kánkán tẹ́lẹ̀ rí.

Arabinrin Bolatito Adegoke ati Egbọn Oloogbe Olugbade Adegoke sọ fún ilé ejọ́, igbese tí wọn gbé lẹyin ti wọn kò rí Oloogbe Timothy Adegoke pé lórí èrò ibaraẹnisọrọ.

Arabinrin naa tẹnu mọ ọ pe ọkọ oun, Timothy Adegoke kín ṣe ẹni tó má n jẹun níta àti pé àwọn sọ̀rọ̀ nígbà tí ó wà ní ìrìnàjò náà.

"Ọko mi ò jẹun níta rí, a mọ ara wa gaan kódà, èmi ni mo bẹẹ kòtò jẹun níta torí ó má sọ fún mi pé ó di gba ti oun bá délé kín òun tó jẹun."

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ó yẹ kí Buhari pé Igboho bíì bàbá s'ọ́mọ ni; Láyé! Kò sẹ́ni tí kò ni jèrè i
Adedoyin nile ẹjọ

Arabinrin Bolatito Adegoke fi kún un pé ọkọ rẹ, Timothy Adegoke kò ṣe aarẹ kánkán rí látìgbà tí àwọn tí ṣe ìgbéyàwó, kódà orí ó fọ ọ rí láti ìgbà náà."

"Ko si nnkan ti wọn le sọ nipa ilera ọkọ mi ti mi ko mọ nitori o jẹ ẹnikan ti kii fi ọrọ tabi ilera rẹ pamọ fun mi."

Ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun ti ni oun ko gba beeli Ramoni Adedoyin lẹyin ti awọn agbẹjọrọ rẹ fi ipo ilera rẹ ṣe awijare idi to yẹ ki wọn fi gba beeli rẹ.

Ẹwẹ̀, adajọ Adepele Ojo sọ pe awọn gbe igbesẹ yii nitori Ramon Adedoyin ati awọn mẹfa yooku ni anfaani lati gba itọju ninu ọgba ẹwọn.

Ile ẹjọ Osogbo

Amọ o ni gbigba beeli wọn ko jọ ọ rara bayii.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ni ọsẹ to kọja to yẹ ki awọn mọlbi Adedoyin yọju lati wa da si ẹjọ, wọn kọ lati yọju amọ, gbogbo igun tọrọ kan lori ẹjọ yii lo ti foju han bayii.

Adajọ naa fi kun un pe awọn olujẹjọ kọ lati fi aridaju kan pe ọgba ẹwọn ti wọn wa ko ni irinṣẹ to tọfun itju ilera wọn ti wọn fi f tori rẹ bere fun beeli.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, irufẹ ẹsun ti wọn fi kan wọn jẹ ko di mimọ pe ile ẹjọ gbudọ ṣọra gidi nipa gbigba iru beeli yii.

Àkọlé fídíò, Dapo Abiodun ò sọ fún mi pé òun á dupò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì o, èmi nàá ò kẹ̀rẹ̀ nínú òṣèlú láti kékeré - Modele Sarafa-Yusuf