Ìjọba Nàìjíría láwọn ṣetán láti kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó há sí Sumy ní Ukraine kúrò sùgbọ́n...

awọn akẹkọọ Naijiria to wa ni Ukraine
Àkọlé àwòrán, Aworan awọn akẹkọọ Naijiria to wa ni Ukraine

Awọn akẹkọọ orileede Naijiria to ha si Ukraine ti n wa iranwọ ijọba ilẹ wọn lati moribọ kuro nibi ikọlu laarin Russia ati Ukraine.

Ninu fọnran fidio kan to gba ori ayelujra niṣe la ri tawọn akẹkọọ Naijiria n kegbajare pe ''a fẹ pada sile'' ''a fẹ pada sile''.

Awọn ọdọ wọnyi sọ pe akẹkọọ fasiti Sumy lawọn ati pe awọn ko ni omi, ina ọba ati pe ounjẹ awọn ti fẹ ẹ tan.

Ọkan ninu awọn akẹkọọ yi sọ ninu fidio naa pe ''o to ọjọ mẹta taa tiwẹ kẹyin''

Igbe wọn yi n waye lẹyin ọjọ diẹ ti awọn alaṣẹ Naijiria sọ pe awọn ti bẹrẹ ijiroro pẹlu awọn il to yi Ukraine ka pe ki wọn jẹ ki awọn ọmọ Naijiria tẹsiwaju eto ẹkọ wọn lọdọ wọn.

Ẹwẹ awọn akẹkọọ to dari de si Naijiria sọ fun BBC pe niṣe ni awọn ọrẹ awn to ṣẹku ni Ukriane n sọ pe awọn kan n beere ẹgbẹrun kan dọla kawọn to e kuro nibẹ.

Igbesẹ ijọba Naijiria lori ọrọ yi

Ileeṣẹ okere lorileede Naijiria sọ pe awọn ṣetan lati bẹrẹ si ni ko awọn ọmọ Naijiria to wa ni fasiti Sumy ni Ukraine kuro lọjọ Aje tii ṣe ọjọ Keje oṣu Kẹta ọdun 2022.

Lọjọ Aiku to sọ bi nkan ti ṣe ri, Minisita fọrọ il okere Geoffrey Onyeama sọ pe awn ti gba iyọnda lati ko awọn akẹkọọ to ha silu yi kuro.

O ni ipenija tawọn n kojuni bawọn yoo ṣe gbe awọn akẹkọọ kuro ni Sumy.Lọsẹ to kọja ni wọn bẹrẹ si ni ko awọn ọmọ Naijiria pada ti ipele mẹrin si ti pada sile.

Ẹwẹ akọwe agba ileeṣẹ okere Naijiria, Gabriel Aduda sọ pe awọn n jiroro pẹlu Minisista eto ẹkọ Romania lati gba awọn akẹkọọ Naijiria to fẹ tẹsiwaju ẹkọ wọn nibẹ.

Aduda sọ pe bẹẹ lawọn tun ba Poland, Hungary, Greece Slovakia ati Lithuania sọrọ kawọn akẹkọọ yi le lanfaani tẹsiwaju pẹlu ẹkọ wọn.

Bí àwọn ọmọ Nàìjíríà tó fẹ́ lọ ran Ukraine lọ́wọ́ lójú ogun ṣe tàdí mẹ́yìn rèé nígbà tí wọ́n gbọ́ "wàá san $1,000

Iroyin ikede ileeṣẹ orilẹede Ukraine to wa ni Naijiria pe ki ẹnikẹni to ba fẹ rinrinajo lọ si Ukraine gbudọ sanwo lati lọ ba wọn doju ogun kọ ikọ ogun Russia ti n fa ọpọlọpọ awuyewuye lori ayelujara.

Eyi waye lẹyin ti ileeṣẹ naa kede pe ọmọ Naijiria to ba fẹ lọ gbudọ san ẹgbẹrun kan Dollar na fun tikẹẹti ati iwe irina.

Yatọ fun owo yii, awọn nkan mii ti ileeṣẹ ọhun ni ki wọn mu wa ni aridaju pe wọn ni iriri ogun jija, fọto aworan oju wọn atawọn nkan mii to wulo.

Ki ni $1,000 yii wa fun?

Gẹgẹ bi awọn oniroyin ṣe jabọ, awọn oṣiṣẹ jẹ ko di mimọ pe owo naa da lori iṣoro to wa ninu eto irinajo lọ si Ukraine lati igba ti wọ́n ti ti awọn ibode irina ofurufu.

Wn ni ọna kanṣoṣo lati wọ Ukraine ni fifo gba awọn orilẹede to ni ibode papọ mọ Ukraine to si jẹ ko di mimọ pe awọn orilẹede yii wa ni ajọ EU torinaa, wọn yoo nilo iwe irina visa lati lọ sibẹ tori o nira lati gba ibode ọna ilẹ wọle fun awọ́n ọm Naijiria.

Gbogbo anogo yii ko ba ọpọ ọmọ Naijiria lara mu ti wọn si n pariwo pe iye owo irinajo yii lọ si Ukraine ti gara ju.

NEFERTITI loju opo Twitter ni eeyan f fi ara rẹ ji lati lọ doju ija kọ awọn ọmọ ogun Russia, lati lọ ku fun yin, ẹ tun ni dandan ko san owo $1,000, o kan dabi ikorira atinuwa fun alawọ dudu ni".

Twitter

Oríṣun àwòrán, @fistladyship

Odinala Ndi Igbo ni tirẹ ni airiṣẹ ati bi ilu ṣe le koko ni Naijiria lo mu ki awọn ọdọ Naijiria lọ yabo ileeṣẹ orilede Ukraine l'Abuja lati fi ara wọn ji lọ ja ogun pẹlu Russia.

Esi lori Twitter

Oríṣun àwòrán, Enyinnayaibeka

Fasakin Gabriel ni "ọpọ ọmọ Naijiria lo n wa gbogbo ọna ati sa kuro nilu koda bo ṣe pe ki wọn lọ jagun, wọn ko ka a kun". O ni ẹgbẹ oṣelu APC ti pin orilede yii.

Esi lori Twitter

Oríṣun àwòrán, fashakin87

Ẹlomiran loju opo Twitter tilẹ ni ṣe lo yẹ ki gbogbo awọn adari Naijiria lọ sin ẹya ara wọn bi ẹni ku.

Esi lori Twitter

Oríṣun àwòrán, chukwunemerem28