Mercy Aigbe and Adekaz: Ìyàwó àkọ́fẹ́ Adekaz ní òun jọ̀wọ́ ọ̀kọ òun fún Mercy báyìí, ohun táwọn èèyàn ń sọ rèé

Adekaz, Mercy, Funsho

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ohun to n mu ori ayelujara gbona janjan lọwọlọwọ lagbo awọn oṣere Yoruba ni itahun sira laarin gbajugbaja oṣere Mercy Aigbe ati iyawo akọfẹ oniṣowo fiimu Adekaz, iyẹn Funsho Adeoti.

Gbogbo awọn ololufẹ Mercy Aigbe to fi mọ awọn ti ko gba tirẹ lo ti bọ soju ayelujara lati sọ erongba wọn lori ọrọ yii. Koda ọrọ naa ti yi si fa ki n fa a kuro lọwọ awọn tọrọ kan sọwọ awọn ti ko kan gbọngbọn.

Awọn mii ni Mercy ti itumọ orukọ rẹ n jẹ aanu ko fi aanu han rara. "Oju gba mi ti fun ẹ, iya isalẹ isọnu..."

Ẹlomiran tilẹ pe e ni ashẹwo to n da ile onile ru.

Àkọlé fídíò, Dapo Abiodun ò sọ fún mi pé òun á dupò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì o, èmi nàá ò kẹ̀rẹ̀ nínú òṣèlú láti kékeré - Modele Sarafa-Yusuf
Atẹjade Mercy Aigbe

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Lẹyin iroyin kan to jade nipa bi iyawo akọfẹ Adekaz ṣe tu gbogbo aṣiri nkan to wa laarin oun, Mercy ati ọkọ rẹ sita ni ohun gbogbo hande si awọn ololufẹ awọn eeyan yii.

Titi debi pe ọrẹ timọ timọ loun ati Mercy Aigbe ati pe oun loun pe e gẹgẹ bi ọrẹ sibi ayẹyẹ ọjọ ibi ọkọ oun nigba naa lọhun amọ ti o ni Mecy ni irọ ni gbogbo ẹ ni Funsho fi sita.

Àkọlé fídíò, Èdè Yorùbá dùn ún gbọ́ àti láti sọ, mo sì fẹ́ràn kí n máa sọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà

Alaye ti Mercy ati ọkọ rẹ ṣe ninu fidio to gba ori ayelujara kan yii gan lo tun wa bu epo bẹntiroo si ina to ti n jo lọlẹ tẹlẹ.

Ninu esi ti Mercy fọ sita, o ṣalaye bi awọn eeyan ṣe rọ ọ to si gba lati ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ileeṣẹ iroyin igba-de-gba kan pe ko fi tanmọlẹ si ohun to wa nilẹ ko si sọ tirẹ amọ to ni lẹyin ifọrọwanulẹnuwo ọhun, awọn eeyan mii tun ti korajọ ti wọn n sọ pe ko ba ma ti ṣalaye ohunkohun tori ohun to ba wu u lo lẹtọ lati ṣe ni igbe aye rẹ.

Ohun to fi pari atẹjade rẹ ṣafihan pe ọrọ naa tilẹ ti su u bi awọn eeyan ṣe n ṣe.

"Iṣoro lo jẹ (Mercy) ninu igbeyawo mi fun ọpọlọpọ ọdun amọ nibayii, inu mi dun lati jẹ koo mọ pe ibẹrẹ opin niyi fun ẹ. Emi ti ṣetan, o ti di tirẹ, maa jẹgbadun ẹ. Mo ti kọja gbogbo eleyi nitemi".

Ẹwẹ, lẹyin alaye Funsho Adeoti, o tọka si Adekaz ati ale rẹ to ti di iyawo pe wọn lee tẹsiwaju ninu ohun gbogbo ti wọn n ṣe, awọn eeyan tu sori ayelujara lati bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ to ti di ranto mọ awọn oni nkan gan lọwọ.

Esi si igbeyawo Mercy Aigbe ati Adekaz

Oríṣun àwòrán, OTHERS

"Alailojuti ni Mercy, Gbọkọ-gbọkọ ati ni ti wọn ja gba, O yẹ ki oju ti Mercy, alailoju ti meji, o han lara rẹ gan pe ara n lọ ẹ tikọ tikọ...", eyi ati ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ ni awọn ti ko gbe lẹyin ohun ti Mercy Aigbe ṣe n sọ.

Esi si igbeyawo Mercy Aigbe ati Adekaz

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ni idakeji ẹwẹ, pẹlu irufẹ awọn fọto ti oṣere Mercy wa bẹrẹ si ni fọn sori ayelujara to fi mọ awọn oriṣiriṣi orukọ to maa n pe ara rẹ to fi n da awọn eeyan lọrun nipa igbeyawo rẹ bii, Alahaja Meena, Agbeke Aya D'Owner, Hajia Adeoti, niṣe lawọn ololufẹ rẹ tun n fọ́ fun un gidi ti wọn si n kokiki rẹ pe ko ma da awọn ọta lohun ko maa jaye ori rẹ lọ.

Esi si igbeyawo Mercy Aigbe

Oríṣun àwòrán, OTAHERS

Koda lara awn ololufẹ Mercy Aigbe kan ti ni ọkọ rẹ n wọ ohun loju o pẹlu awọn aworan to n fi sita am awọn mii ti ba Mercy fun un lesi.

Esi si igbeyawo Mercy Aigbe

Oríṣun àwòrán, OTHERS