Mercy Aigbe,Adekaz, Asiwaju Couture: Ìwọ àti 'Side Chick' ẹ lè se ohun tó wù yín sùgbọ́n....- Funsho Adeoti

Aworan Kazeem Adeoti ati Mercy Aigbe

Oríṣun àwòrán, Mercy Aigbe

Orọ̀ igbeyawo gbajugbaja oserebinrin, Mercy Aigbe àti Kazeem Adeoti ti n bi Ige ati Adubi lori ayelujara.

Arabinrin Funsho Adeoti Iyawo Kazeem Adeoti, gbajugbaja oludari ileeṣẹ to n gbe fiimu jade ti fesi lori ifọrwanilẹnuwo ti ọkọ re ṣe laipẹ yi nibi to ti sọro nipa ibagbepọ wọn ṣaaju ki iyapa to waye.

Nibo ni iyawo Adekaz ti sọ̀rọ̀ naa?

Loju opo rẹ ni Instagram ni arabinrin Funsho ti ọpọ mọ si Asiwaju Coutoure fi ọrọ yi si,.

O ni irọ pata ni Adekaz pa nipa bi oun ti ṣe gba pe yoo ni iyawo miran.

Bẹẹ, lo sọ pe ko si igba kankan ti oun gba pe ki o gbe iyawo miran wọ inu igbeyawo wọn.

Funso tun so pe:

Ka èsì tí ìyàwó ilé ọkọ tuntun Mercy Aigbe dá padà lórí fífẹ ìyàwó míìràn leè

''Kazim o yẹ ko sinmi lati maa parọ pe igbeyawo wa ladun o loyin, nitori emi Oluwafunso Asiwaju Couture ati iwọ ko ni igbeyawo to dun rara''

O tẹsiwaju pe ki Adekaz ati alẹ rẹ maa ṣe ohun to wu wọn ṣugbọn ko ma ṣe bọ si oju opo ayelujara lati tabuku ''emi ati awọn ọmọ mi''

Funso tẹsiwaju pe oun ko ni fi ara oun wọlẹ pẹlu rẹ nipa iwa ti ko ni laaye to n wu.

Aworan ọrọ oju opo asiwajucouture

Oríṣun àwòrán, Instagram/asiwajucouture

Ki ni Adekaz sọ ninu ifọrọwerọ to fa yanpọn yanrin bayii?

Ninu fonran fidio naa ni Adekaz ti so pe:

''Musulumi ni mi, ẹsin mi si gbami laaye lati fẹ iyawo meji.

Bayi mo ti f iyawo meji.

Mo ni iyawo meji to rẹwa.

Ko si si wahala kankan''

Eleyi taa le mu ni koko ọrọ ree ti Adekaz sọ to ṣeeṣe ki Funsho Adeoti maa binu si ninu esi to fọ loju opo Instagram.

Ifọrọwanilẹnuwo ti a n wi yi leleyi ti Kazeem Adeoti ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin Media Room Hub nibi ti Kazeem Adeoti ati Mercy Aigbe ti sọrọ nipa igbeyawo wọn ati iṣẹ to pa wọn pọ.

Aworan Kazeem Adeoti ati Mercy Aigbe

Oríṣun àwòrán, Screen shot Media Room Hub

Adeoti salaye ninu rẹ pe ''Mọlẹbi mi wa ni ilẹ Amẹrika mo si maa n lọ yọju wo wọn nitori ibi ni iṣẹ mi wa.''

''Bi awọn eeyan ba n sọ pe wahala wa boya nitori pe wọn ko ri wa papọ ni.

Lootọ a ni aigbọraẹniye diẹ ṣugbọn gbogbo nkan ti pada bọ̀ sipo.''

Ni idahun si ibeere ti akọroyin bi i pe se oun ati ọko Mercy tẹlẹ, Lanre Gentry jijọ jẹ ọrẹ, o ni '' a ko fi igba kankan jẹ ọrẹ tẹlẹ ri.''

Àkọlé fídíò, Èdè Yorùbá dùn ún gbọ́ àti láti sọ, mo sì fẹ́ràn kí n máa sọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà

Waa sinmi ni ọdọ Kazim jẹ fun mi-Mercy Aigbe

Ọrọ Mercy Aigbe ninu ifọrọwanilẹnuwo naa nii ṣe pẹlu iṣẹ rẹ ati ajọṣepọ nidi iṣẹ toun ati Kazeem jijọ ni.

Yatọ si pe o ṣapejuwe Kazeem gẹgẹ bi ẹni ti awọn jijọ ni ibaṣepọ to mọranyin, o ni awọn ri pe awọn ni ohun to jọra ni iwa lo mu ki awọn fẹ ara wọn.

Aworan Kazeem Adeoti ati Mercy Aigbe

Oríṣun àwòrán, Screenshot/Media Room Hub

O ni ''igba kigba to ba wa pẹlu mii, ọkan mi maa n balẹ pẹlu rẹ. Amọ nigba to ni ki n fẹ oun, o mu ọpọ idunnu ati ifọkanbalẹ wa si igbe aye mi.''

''Mo mọ pe titi lae lao jijọ wa pẹlu ara wa.Waa sinmi ni mo de bayi.Mi o lọ si ibi kankan mọ''