Mercy Aigbe and Adekaz: Ṣé lóòtọ́ ni Mercy Aigbe ti sẹ ìgbéyàwó pẹ̀lú Adekaz, àbọ̀ ìwádìí wa rèé

Oríṣun àwòrán, Mercy aigbe
Gbajugbaja oṣerebinrin, Mercy Aigbe ti ṣafihan ọkunrin to ṣe e ṣe ko jẹ olowo ori rẹ tuntun.
Ninu awọn aworan ti oṣerebinrin naa fi si ori Instagram rẹ ni irọlẹ ọjọ Aiku lo lo ṣafihan rẹ pẹlu ọkunrin kan, to si kọ ọrọ sibẹ pe "ọjọ ibi ololufẹ mi ku dẹdẹ.... o seun ti o jẹ eniyan daadaa."
Ṣaaju ni iroyin ori ayelujara kan, Gistlover ti sọ ni owurọ ọjọ isinmi pe Mercy ti ṣe igbeyawo pẹlu gbajugbaja onisọwo to ma n gbe sinima sita, Kazim Adeoti, ti ọpọ eeyan mọ si Adekaz Production.
Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, Ọgbẹni Adeoti ni iyawo kan, Rafiat Adeoti, ati ọmọ mẹrin to n gbe ni orilẹ-ede Canada.
Botilẹ jẹ pe lati asiko diẹ sẹyin ni Arabinrin Mercy ti ma n pe ara rẹ ni Agbekẹ Aya D'owner, ko fi igba kankan sọ sita ri pe oun ti ṣegbeyawo.
Ọdun 2017 ni oun ati ọkọ rẹ, to jẹ oniṣowo ile itura, Lanre Gentry tu igbeyawo wọn ka.
Ọmọ kan ni wọn bi fun ara wọn, yatọ si ọmọbinrin kan ti Mercy ti kọkọ bi ninu igbeyawo rẹ akọkọ.
Ṣugbọn pẹlu ọrọ ti Mercy kọ sita yii, ṣe a le sọ pe lootọ lo ti sẹ igbeyawo pẹlu Ọgbẹni Adeoti?
Awọn nkan ti iwadii wa fihan re e
Nkan akọkọ ni pe a ri fidio kan lori ayelujara Instagram Mercy, to fi sita ni ọjọ kẹrinla, oṣu yii, eyi to ṣafihan ibi ti gbajugbaja olorin Fuji, Wasiu Ayinde ti n kii ni "Agbekẹ Aya D'owner, ti oun naa si n nawo fun.
Amọ nkan ti oju wa ri nipe, Ọgbẹni Adeoti 'Adekaz' naa wa pẹlu Mercy, ti wọn jọ n nawo fun olorin naa.
Ni ọjọ yii kan naa, lo tun fi fidio miran sita pẹlu akọle pe "Iyawo Alhaji". Alhaji Adeoti ni apeja orukọ Adekaz.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Bakan naa, fun bi ọjọ diẹ sẹyin lo ti n pe ara rẹ ni orukọ tuntun kan to jẹ orukọ musulmui, Hajia Minnah, botilẹ jẹ pe Kristiẹni ni.
Sẹ ẹ si mọ pe dandan ni ki obinrin to ba fẹ ọkunrin to jẹ musulumi gba orukọ tuntun lasiko ti wọn ba n ṣe Nikkah, ti ko ba ni orukọ bẹẹ tẹlẹ.
Nkan keji ni pe a tun ṣakiyesi oruka igbeyawo lọwọ rẹ, ninu fidio kan to fi sita ni ọjọ Satide, ọjọ kejilelogun, oṣu yii.
Nkan kẹta ni pe lẹyin wakati diẹ ti aworan ti Mercy fi ki Adekaz ku ọjọ ibi lori ayelujara Whatsapp rẹ jade, ni oun funra rẹ gbe si ori Instagram.
Aworan akọkọ ṣafihan awọn mejeeji ti wọn n fi oju ifẹ wo ara wọn pẹlu ẹrin, ti Mercy si fi ọwọ kọ Adekaz ni ibara idi.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Ko tan sibẹ o, o kọ akọle si aworan naa pe "ọjọ ibi ololufẹ mi ku diẹ, Kazim Adeoti, o sẹun ti o jẹ eniyan rere."
Lẹyin naa lo tun fi aworan mẹrin miran sita.
Ninu ọkan ninu aworan naa ti wọn ya nibi ayẹyẹ kan to jọ igbeyawo oṣerekunrin Lateef Adedimeji ati Bimpe Oyebade, ni Mercy ti gbe ori si aya Adekaz, ti awọn mejeeji si n rẹrin.
Aworan miran tun ṣafihan wọn ti wọn jọ n wo ara wọn tifẹ-tifẹ. Akori ti Mercy kọ si abẹ aworan naa ni pe "mo n reti ki akoko pe, ki n ki ọrẹ mi timọ-timọ ku ọjọ ibi. Mo ṣe ajọyọ oore Ọlọrun ninu aye rẹ, Alhaji Kazim Adeoti.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 3
Oriṣiriṣi ariyanjiyan si lo ti n waye ninu ọrọ ti awọn eniyan n kọ si abẹ awọn aworan naa.
Ni abẹ aworan naa la tun ti ri ti Adekaz fun ra rẹ naa fi ami 'emoji' ifẹ fesi.
Bi awọn kan ṣe n bu Mercy pe o gba ọkọ ọlọkọ, ni wọn n fi ẹsun kan an pe nkan ti ko le gba lọdọ ọkọ rẹ tẹlẹ, Gentry, lo ṣe fun obinrin miran.
Amọ awọn kan tun n sọ pe ko si nkan to buru ninu nakn to sẹ, nitori pe pẹlu ọjọ ori rẹ, o nira lati ri ọkunrin ti ko ni iyawo nile fẹ.
Taa ni Kazim Adeoti?
Alhaji Adeoti Kazim ni orukọ rẹ, ṣugbọn Adekaz ni ọpọ eeyan mọ ọ si.
Adekaz yii ni orukọ ileeṣẹ rẹ to n gbe sinima jade, Adekaz Production.
Yatọ si eyi, oun tun ni oludasilẹ Ibaka TV, ẹrọ ori ayelujara ti awọn eeyan ti n sanwo lati so sinima.
Ọmọ ilu Orokun nipinlẹ Kwara ni Ọgbẹni Adeoti, amọ ilu Eko ni wọn bi si.
Fasiti ilu Jos lo ti kawe nipa amojuto okoowo.
Ọdun 2002 lo fẹ iyawo rẹ akọkọ.














