Nimota Akanbi: Ọlọ́pàá tó gbé oúnjẹ tẹ̀lé ènìyàn nínú fọ́nrán tó gba ìgboro yóò fojú winá òfin

Oríṣun àwòrán, Others
Ọlọ́pàá tó gbé oúnjẹ tẹ̀lé ènìyàn nínú fọ́nrán tó gba ìgboro yóò fojú winá òfin
Láti bí ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn ni fọ́nrán kan gba orí ẹ̀rọ ayélujára kan léyìí tó ti ń fa awuyewuye láàárín àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Nínú fọ́nrán náà, ọlọ́pàá kan ń gbé oúnjẹ tẹ̀lé aṣojú orílẹ̀ èdè Netherlands tẹ́lẹ̀ rí, Nimota Akanbi níbi ètò ìnáwó kan.
- Ayé lee! Báwo ni obìnrin ẹni ọdún 22 yìí ṣe dédé dàwátì nínú ọkọ̀ BRT l'Eko?
- Wo àwòrán bí Ukraine ṣe rí tẹ́lẹ̀ ṣáájú ìkọlù Russia àti bó ṣe rí báyìí
- Wo àwọn asọ ìgbèyàwó àràmọ́ndà, kóo fojú lóúnjẹ òpin ọ̀sẹ̀
- Ohun ìṣeré abánilòpọ̀ há sójú ara mi, mo kú tán - Obìnrin ológun kan
- Eré orí ìtàgé ni à ń ṣe nínú fọ́nrán CCTV tí wọ́n ti sọ pé mo fẹ́ bá ọmọdé lòpọ̀ - Baba Ijesha
- Kí ni mo ṣe tí ìkórira fi pọ̀ tó èyí? - Davido ń bèèrè
- Ìdí rèé tí mo ṣe fẹ́ jẹ ààrẹ Nàíjíríà - Tinubu
- Ẹ sọ́ra fún wíwá owó òjijì ẹ̀yin ọ̀dọ́, ìgbẹ̀yìn rẹ kìí dára- Alake Egba
- Wàhálà tí kò ní lópin ni ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá fẹ́ dá sílẹ̀ lórí kí ọlọ́pàá obìnrin máà lo Hijab - Adegboruwa
Kini fidio yii bi jade nileese olopaa Naijiria?
Ìwà yìí ni àwọn ọmọ Nàìjíríà ti ń kùn lé lórí wí pé báwo ni ọlọ́pàá yóò ṣe ojúṣe láti máa dá ààbò bò ará ìlú tí yóò wá gbaṣẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ nínú aṣọ ọlọ́pàá?.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá korò ojú sí ọlọ́pàá tó gbé oúnjẹ tẹ̀lé Nimota Akanbi
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti korò ojú sí ọlọ́pàá kan tí fọ́nrán gba orí ẹ̀rọ ayélujára níbi tó ti gbé oúnjẹ tẹ̀lé aṣojú orílẹ̀ èdè Netherlands tẹ́lẹ̀ rí, Nimota Akanbi níbi ètò ìnáwó kan.
Nígbà tó ń júwe ìwà tí ọlọ́pàá yìí hù bíi èyí tí kò bá òfin àti ìlànà iṣẹ́ ọlọ́pàá mu, agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Muyiwa Adejobi ni àwọn ti ráńṣẹ́ sí ọlọ́pàá náà láti wá sí Abuja láti wá wí tẹnu rẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Adejọbi ní àwọn gbọ́dọ̀ korò ojú sí irúfẹ́ ìwà ìdójútì báyìí kí àwọn ènìyàn yé tẹ àwọn òṣìṣẹ́ àwọn lójú mọ́lẹ̀.
Oúnjẹ ara rẹ̀ ni ọlọ́pàá tó wà nínú fọ́nrán yẹn gbé dání kìí ṣe tèmi - Nimota Akanbi
- Kíni àjọ ECOWAS ilẹ̀ Adúláwọ̀ ń sọ báyìí lórí ìjà Russia àti Ukraine?
- 416 àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà ní Ukraine ló ti dé sílé báyìí-Abike Dabiri tó ń mójútó ọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè
- Sé Nàìjíríà le fi Abba Kyari ráńṣẹ́ sí Amẹ́ríkà pẹ̀lú bó ṣe ń kojú ìgbẹ́jọ́ àjọ NDLEA? – Àlàyé rèé
- Ibá Lassa fojú hàn ní ìpínlẹ̀ Oyo, ó ti mú ẹ̀mí Dókítà méjì lọ
- Bàbá Adesola Adedeji, ọ̀kan lára àwọn afurasí méje ń fẹ́ rọ́pò ọmọ rẹ̀ nínú ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke
Kini Nimota Akanbi so lori fidio naa?
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí fọ́nrán tó gba orí ẹ̀rọ ayélujára, aṣojú orílẹ̀ èdè Netherlands tẹ́lẹ̀ rí, Nimota Akanbi ní òun kọ́ ni òun ni oúnjẹ ti ọlọ́pàá náà gbé dání.
Akanbi nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́jọ́rú ní lóòótọ́ ní òun àti ọlọ́pàá tó ń ṣọ́ òun jọ lọ síbi ìnáwó kan ní ìlú Ìlọrin ṣùgbọ́n irọ́ tó jìnà sí òòtọ́ ni pé òun gbé oúnjẹ fún un láti gbe dání fún òun.
Ó ní òun mọ pàtàkì iṣẹ́ ọlọ́pàá àti pé ẹlẹ́kọ̀ọ́ ni òun, òun kò lè hu irú ìwà bẹ́ẹ̀.















