Davido: Láti ọdún méje, ń kò rí ẹni ràn mí lọ́wọ́ lágbo amúlùúdùn àfi ìkórira àárọ̀ di alẹ́

Oríṣun àwòrán, Davido/Instagram
Ẹni ti a ko fẹ, aalọ ko ran, inunibini ko si kan ti aimọ iwa hu.
Gbajumọ akọrin takansufe kan, David Adeleke, ti ọpọ eeyan mọ si Davdo, ti ke gbajare sita lori idi tawọn eeyan kan se korira rẹ.
Davido, ẹni to gbajumọ bii isana ẹlẹẹta nidi orin kikọ, lo n mẹnuba pe awọn eeyan kan lagbo amuludun ti orin kikọ ni ko fẹ ri imi oun lori aatan.
- Davido sí Yomi Fabiyi: Mùmú ni ẹ́
- Davido, bá mi kọ ẹsẹ orin kan nínú àwo orin mi, jẹ́ ká da ayé láàmú - Portable Zazzu
- "Davido kò ran èmi gbajúmọ̀ lọ́wọ́, ọmọ òrukàn ló fẹ́ kó ₦250 fún"
- Davido gbààyè kó tó kúro láàgọ agùnbanirọ
- Kí ló dé tí Wema Bank ń pe Davido fún ìpàdé nítorí ẹ̀dáwó N1milion tó pè sí àṣùwọ̀n wọn?
- Davido fi mọ́tò N45M dá Chioma lọ́lá
- Mo ti ṣetán láti pín ₦250m sí ilé àwọn ọmọ aláìníyàá káàkiri Naijiria - Davido
- Ọjọ́ ìbí bàbá mi ni aàrùn ọkàn ṣekúpa màmá mi lójijì- Davido
- Davido, Pasuma àti Yinka Ayefele dábírà lópin ọ̀sẹ̀, aráyé múgbe bọnu
Ninu fidio kan to ti lu ori ayelujara pa ni Davido ti sisọ loju ọrọ yii.
Ki lo de ti Davido fi pariwo sita?
O ni lati igba ti oun ti bẹrẹ orin kikọ, ko si alatilẹyin kankan fun oun gẹgẹ bi wọn se maa n se fawọn akọrin mii to jẹ akẹẹgbẹ oun.
Akọrin naa salaye pe fun odidi ọdun meje ti oun ti wa ni agbo amuludun, ikorira ni wọn n fi han si oun lati aarọ di alẹ.
Davido wa n beere pe se nitori pe baba oun jẹ olowo ati ọlọrọ ni oun se n gba ọta pupọ abi ki ni oun se gan?
O ni se ẹbi oun ni bi baba oun se ni owo ni?
"Mo sisẹ kara kara funra mi o, mo gbe awọn awo orin to jẹ itẹwọgba sita, ti mo si sisẹ ri owo funra mi.
Ki ni mo wa se ti ọta fi pọ to eleyi fun mi?"
Davido sọrọ yii lẹyin to ti ta gbogbo awọn tikẹẹti iwọle si gbọngan ile ijo to ti fẹ kọrin tan eyi ti wọn pe ni O2 Arena Music Concert.
Ọla ọjọ Satide, ọjọ Karun osu Kẹta ọdun 2022 si ni orin kikọ naa yoo waye.
Ta ni David Adeleke, ti ọpọ mọ si Davido?
David Adeleke, ti ọpọ mọ si Davido jẹ gbajumọ akọrin takansufe lorilẹede Naijiria.
Ọmọ bibi ilu Ede nipinlẹ Osun ni Davido, ti baba rẹ, Deji Adeleke si jẹ olowo ati ọlọrọ.
Amọ lai fi ti owo baba rẹ se, Davido naa sisẹ kara nidi orin kikọ to yan laayo, to si ti gbe ọpọ awo orin to gbajumọ, to si tun jẹ itẹwọgba sita.
Awọn obinrin mẹta lo ti bimọ fun Davido, to si ti gba ami ẹyẹ lorisirisi nidi isẹ to yan laayo.


















