Portable Zazuu: ‘Wèrè Olórin’ rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Davido láti bá ṣe àwo orin papọ̀

Oríṣun àwòrán, Portable/instagram
Gbajumọ olorin ti ọbẹ rẹ n ta lẹnu lagbo orin taka sufe lọwọlọwọ bayii, Habeeb Okikiọla Omoolami ti ọpọ mọ si Portable, ti kan si agba ọjẹ orin takasufe, David Adeleke ti ọpọ mọ si Davido, pe ko da si orin tuntun ti oun n po pọ bayii.
Olorin Zazzu naa n rọ Davido pe ko kan kọ ẹsẹ kan ninu awo orin naa loun nfẹ ki irawọ orin naa tun le tan, bii ti Zazzu to gbe e saye.
Ninu fidio kan to fi soju opo Instagram rẹ, Portable n gbọ orin tuntun to fẹ kọ naa labẹnu, lasiko to fi n fi ohun ẹbẹ ranṣẹ si Davido pe ba oun kọ ẹsẹ kan ninu orin naa.
- Èmi kìí mu oògùn olóró tàbí ọ̀tí àmọ́ wèrè gidi ń bẹ lára mi – Portable Zazzu
- Ìyá Sunday Igboho wà lórí àìsàn torí kò rí ọmọ rẹ̀ - Agbekoya
- Mo fẹ́ ṣe ìyàwó pẹ̀lú ọmọọbabìnrin Ado Bayero ní Kano àmọ́ ń kò tíì mú ọjọ́ - Oluwo
- Kọmísánnà ọlọ́pàá ní London kọ̀wé fi ipò sílẹ̀ torí ìkéde a kò nígbẹkẹ̀lé nínú rẹ mọ́
- "Ìná tó ń ṣe àkóso ojú pópó ló dá ọkọ̀ agbówórìn dúró, tí adigunjalè fi kọ lù ú"
- Ìjà abẹ́nú bẹ̀rẹ̀ lẹ́gbẹ́ NURTW l‘Eko, nǹkan kò fara rọ
- Ẹ wo bí ‘dókítà’ ṣe yọ àpò ẹyin ilé ọmọdébìnrin kan lásìkò iṣẹ́ abẹ́
- Afurasí ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn yìnbọn pa akẹ́kọ̀ọ́ tó ń múra NYSC àti ọlọ́kadà l'Ẹdẹ
- Àwọn tó ní mi ò lè bímọ lárùn ọpọlọ, ó nídìí tí mo fi ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ - Yomi Fabiyi
Ohun to kọ niyi: "Zazuu ṣe ki n zeh eleyii pẹlu Davido. Ẹsẹ orin kan ni mo nilo, a wi bẹẹ ṣe bẹẹ. Jẹ kaa Bizza Bizza. Ọlọrun a bukun yin daadaa sii Zauu."

Oríṣun àwòrán, portablebaeby/Instagram
Itan atapata dide Portable, olorin Zazuu
Ni ipari ọdun 2021 ni Habeeb Okikiọla kan lu agbami wọ kilu mọ nigba ti orin to k pẹlu gbajumọ olorin Ọlamide ati gbajumọ onijo kan ti ọpọ mọ si Pocolee.
Orin naa ti di gbajugbaja kaakiri agbaye to si ti yi igbe aye rẹ pada.
Lati igba ti orin rẹ naa si ti di aigbọdọ maa kọ nibi ariya ati ile ijo gbogbo ati lẹnu tonile talejọ, Portable ti ṣe alabapade awọn agbaagba onkrin bii Wizkid ati Davido.














