Benue: N kò le bímọ mọ́ torí àṣì'se ‘dókítà’ lásìkò iṣẹ́ abẹ

Iya ọmọdebinrin naa

Ara meeriri, mo ri ori ologbo lori atẹ ni isẹlẹ kan to le gba omije loju ẹni to sẹlẹ si ọmọdebinrin kan nipinlẹ Benue.

O si daju pe oju apa, ko le jọ oju ara fun wọn titi ti yoo fi jade laye nitori asise to ti ba agọ ara rẹ.

Gẹgẹ ba se mọ pe gbogbo obìnrin tó wà láyé ni ó máa ń ní ìrètí wí pé lọ́jọ́ ọjọ́ kan òun yóò dàgbà, tí yóò tó ẹni tó ń bímọ.

Èrò yìí ni ó ṣeéṣe kó má rí bẹ́ẹ̀ mọ́ fún Aneh (èyí kìí ṣe orúkọ rẹ̀ gangan), ọmọ ọdún méjìdínlógún, bí dókítà kan ṣe yọ ẹyin ilé ọmọ rẹ̀ sọnù lásìkò tó ṣe iṣẹ́ abẹ fún un.

Ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, nígbà tí Aneh wà ní ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún ló lọ ṣe iṣẹ́ abẹ láti fòpin sí ìnira tó ń fojoojúmọ́ bá a finra àmọ́ dípò bẹ́ẹ̀, inú làásìgbò mìíràn ló tún kó sí.

Aneh

Dókítà Agber Kwende, tó ṣiṣẹ́ abẹ náà fún un ní ilé ìwòsàn German Health Clinic tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Gaav Konshisha, ìpínlẹ̀ Benue, ni wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó yọ ẹyin ilé ọmọbìnrin náà lásìkò tó ṣiṣẹ́ náà.

Ìyá Aneh, Mgbatuman Lana, ní nígbà tí ara níni pọ̀ fún ọmọ náà tí àwọn sì lọ ṣe àyẹ̀wò ni ìwádìí fi hàn pé ilé ọmọ Aneh ti bàjẹ́.

Báwo lọ̀rọ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀?

Mgbatuman Lana, ìyá Aneh ṣàlàyé fún ikọ̀ ìròyìn BBC pé nínú oṣù karùn-ún ọdún 2019 ni àárẹ̀ ọmọ òun bẹ̀rẹ̀, tí inú yóò máa rún gan-an tó bá fẹ́ ṣe nǹkan àlejò lóṣóooṣù.

Ó ní èyí kò tẹ́ òun lọ́rùn ni òun bá mu lọ sí ilé ìwòsàn Gemanen Health Clinic fún àyẹ̀wò níbi tí wọ́n ti ṣe àwòrán inú fún-un tí dókítà sì ní "apendis" ló ń dà á láàmú.

Dókítà ní iṣẹ́ abẹ ni ó nílò láti dẹ́kun ìnira yìí, mo sì lọ yá owó ní ilé ìfowópamọ́ láti fi ṣe iṣẹ́ abẹ náà tí dókítà Kwende ṣe fun un ṣùgbọ́n kàkà kí ewé àgbọn dẹ̀ líle ló le si.

Wíwá ìwòsàn:

Ìyá Aneh ní líle tí àárẹ̀ Aneh ń fi ojoojúmọ́ le si jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn fún òun ni òun bá gbe lọ sí ilé ìwòsàn mìíràn tí wọ́n sì ṣe àyẹ̀wò fún-un.

Ó ní àyẹ̀wò yìí ló ṣàfihàn pé ibi tí wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abẹ fún un wú tó sì nílò àtúnṣe.

Bákan náà ló ní èyí ló fà á tí àwọn fi lọ sí ilé ìwòsàn St John níbi ti àyẹ̀wò ti fi hàn pé wọn ti yọ ẹyin ilé ọmọ Aneh.

Aneh ní ó jẹ́ òun ìbànújẹ́ fún òun pé òun kò nílè bímọ láyé.

Àkọlé fídíò, Water Generator: Ó leè ṣiṣẹ fún wákàtí mẹfà, kó tó sinmi

Àjọ ọlọ́pàá nawọ́ gán Kwende:

Àjọ ọlọ́pàá ẹ̀ka Gboko ti nawọ́ gán ẹni tó ni ilé ìwòsàn tí wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abẹ náà, Joseph Ugoh àti dókítà Kwende tó ṣe iṣẹ́ náà.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, Kwende ní láti ọdún 1982 ni òun ti ń ṣiṣẹ́ abẹ à ti pé ńígbà tí òun ṣe àyẹ̀wò fún un òun ri pé ẹyin ilé ọmọ rẹ̀ wú tó sì tún ní apendix.

Ó ní láti ìgbà tí òun ti ṣe iṣẹ́ abẹ náà ẹnì kankan kò kàn sí òun àyàfi ìgbà tí àwọn ọlọ́pàá dé lóṣù yìí láti wá mú òun.

Níbo ni ìwádìí dé?

Agbẹnusọ àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Benue, Catherine Anene ní àwọn yóò gbé wọn lọ sí ilé ẹjọ́ ní kété tí àwọn bá ti parí ìwádìí àwọn

Kọmíṣọ́nà ètò ìlera ìpínlẹ̀ Benue, Joseph Ngbea ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ ohun tó kọni lóminú.

Ó ṣàlàyé pé Kwende kìí ṣe akọ́ṣẹ́mọsẹ́ oníṣẹ́ abẹ kó tó dágbálé iṣẹ́ náà, ó ní lásìkò tí obìnrin bá ṣe nǹkan àlejò lọ́wọ́, ẹyin ilé ọmọ máa ń wú ṣùgbọ́n Kwende kò mọ èyí.

Ngbea ní iṣẹ́ ń lọ lọ́wọ́ láti mọ àwọn ilé ìwòsàn tí kò fi orúkọ sílẹ̀ lábẹ́ ìjọba tí wọ́n yóò sì póró òfin gbé wọn.

Àkọlé fídíò, Bad Boy Timz: Fásitì ni mo wà tí mo fi kọrin ‘Gbẹ́sẹ̀ lọ́kọ̀ọ́ọ̀kan’ tó sọ mi di gbajúmọ̀