Lagos NURTW Crisis: Àwọn ọmọlẹ́yìn MC Oluomo àti alága ẹgbẹ awakẹ̀kẹ́ Marwa kọju ìjà síra wọn

Awọn ọmọ ẹgbẹ ọlọkọ ero ti ij

Oríṣun àwòrán, RRS Lagos

Egbinrin ọtẹ ni ọrọ aawọ abẹnu to n waye ninu ẹgbẹ awọn awakọ ero NURTW, ẹka tipinlẹ Eko, bi wọn se n pa ina ọkan, ni omiran n ru.

idi ni pe rogbodiyan mii tun ti bẹ silẹ ninu ẹgbẹ awọn awakọ ero NURTW ipinlẹ Eko bayii, ti nnkan ko si rọgbọ laarin wọn.

Rogbodiyan naa waye laarin awọn ọmọlẹyìn alaga ẹgbẹ naa, Musiliu Akinsanya ti ọpọ mọ si ni MC Oluomo at'awọn ọmọlẹyìn alaga kẹkẹ Maruwa, TOOAN, Azeez Abiola (Istijabah) ti wọn ṣẹṣẹ yan.

Ni agbegbe Miran, Alomosho, Abule Egba ati Command ni ikọlu naa ti waye ni Ọjọbọ.

Ni Ọjọru ni a gbọ pe awọn adari ẹgbẹ NURTW niluu yan Istijabah gẹgẹ bi alaga awọn awakọ kẹkẹ Maruwa, TOOAN, ẹka ti ipinlẹ Eko.

Àkọlé fídíò, Bad Boy Timz: Fásitì ni mo wà tí mo fi kọrin ‘Gbẹ́sẹ̀ lọ́kọ̀ọ́ọ̀kan’ tó sọ mi di gbajúmọ̀

Ki lo fa ikọlu laarin MC Oluomo ati Istijabah, alaga tuntun fẹgbẹ awọn onikẹkẹ Marwa?

Iroyin fidi rẹ mulẹ pe, abẹ ẹgbẹ NURTW ipinlẹ Eko l'awọn awakọ kẹkẹ Maruwa wa ṣaaju akoko yii.

Ṣugbọn ni Ọjọru, ọjọ kẹsan an oṣu keji ọdun 2022 yii, nkan yi pada lẹyin ti awọn alaṣẹ ẹgbẹ NURTW buwọlu iyansipo Azzez Abiola gẹgẹ alaga TOOAN nipinlẹ Eko.

Igbesẹ yii ni a gbọ pe ko dun mọ MC Oluomo ninu bo tilẹ jẹ pe o mọ sii.

Aarẹ apapọ fun NURTW, Alhaji Tajudeen Baruwa pàṣẹ pe ki alaga tuntun TOOAN l'Eko maa ṣiṣẹ pọ pẹlu MC Oluomo.

Amọ, iroyin kan fidi rẹ mulẹ pe kete ti MC Oluomo pada silu Eko lati Abuja lo sọ fun awọn ọmọlẹyìn rẹ, awọn igbimọ alaṣẹ NURTW nipinlẹ Eko at'awọn to n wa kẹkẹ Maruwa lati ma ri Istijabah gẹgẹ bi alaga TOOAN.

MC Oluomo Ati Istijabah

Oríṣun àwòrán, RRS Lagos

Bawo ni ikọlu ṣe waye laarin MC Oluomo ati Istijabah, alaga tuntun fawọn onikẹkẹ Maruwa?

Ohun ti a gbọ ni pe MC Oluomo lo ranṣẹ pe Istijabah fun ipade ni olu ileeṣẹ NURTW ni Ọjọbo.

Kete ti Istijabah yọjú si olu ileeṣẹ NURTW ni a gbọ pe awọn ọmọlẹyìn MC Oluomo bẹrẹ si ni ju oko ati igo mọ ọn.

Ọjọ́bọ̀ lo yẹ ki Istijabah bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bí alaga tuntun fun ẹgbẹ TOOAN sugbọn awọn janduku kan ti n duro de e ni ọọfisi NURTW.

Àkọlé fídíò, Yinka Ayefele: Ìrọ́ ni pé ń kò le ṣe bíi ọkùnrin, mò ń ta pútú dàadáa

Ẹka Ileeṣẹ ọlọpaa RRS gbe Istijabah si ahamọ:

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fi ọwọ ofin mu alaga tuntun fawọn awakọ kẹkẹ Maruwa, TOOAN, Istijabah at'awọn mẹrin mii lori rogbodiyan to waye.

Awọn ọlọpaa kogberegbe RRS lo mú Istijabah, Yussuf Azeez, Kazeem Akinboade ati Moses Abiodun lagbegbe Abule Egba.

Agege ni a gbọ pe awọn RRS ti mu wọn nigba ti wọn ni wọn kọwọrin pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW kan lọ si olu ileeṣẹ NURTW l'Agege.

Koda, iroyin tun fidi rẹ mulẹ pe awọn ọlọpaa gba ibọn kan lọwọ awọn ọmọlẹyìn Istijabah, ti wọn salọ k'awọn ọlọpaa ma ba le ri wọn mu.

Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW ti ko darukọ ara rẹ sọ pe awọn alaṣẹ NURTW l'Abuja n wa ọna lati yọ MC Oluomo nipo, lo jẹ ki wọn yan Istijabah gẹgẹ bi alaga TOOAN l'Eko.

Ta ni MC Oluomo:

Musiliu Akinsanya, ti awọn eeyan tun maa n pe ni MC Oluomo lo jẹ alaga apapọ fun ẹgbẹ awọn awakọ ero NURTW, ẹka tipinlẹ Eko.

Ọmọ bibi ipinlẹ Ogun ni iya alaga NURTW naa nibi ti wọn ti fi jẹ oye Oluomo amọ ọmọ bibi ipinlẹ Eko ni baba rẹ.

Agbegbe Oshodi nilu Eko ni wọn bi MC Oluomo si

Ọjọ Kẹrinla osu Kẹta ọdun 1975 ni wọn bi MC Oluomo, to si jẹ ẹni ọdun mẹtadinlaadọta bayii.

Bi o tilẹ jẹ pe ko kawe ile ẹkọ alakọbẹrẹ tan to fi kuro nile ẹkọ, to si bẹrẹ si tẹle ọkọ ero kiri, sibẹ o ti di gbajumọ nilẹ Naijiria.

O lowo lọwọ, o ni aya ati awọn ọmọ, ti ọpọ wọn n kawe lawọn ile ẹkọ loke okun, ti wọn si tun tẹdo sibẹ pẹlu.

Amọ akọsilẹ nipa alaga tuntun fun ẹgbẹ awọn to n wa kẹkẹ Maruwa, TOOAN, Azeez Abiola ti wọn n pe ni Istijabah.

Iid ni pe orukọ rẹ sẹsẹ di mimọ fun ọpọ eeyan ni yatọ si aarin awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ ero to ti gbajumọ tẹlẹ.

Àkọlé fídíò, Plights of Widows in Nigeria: Abosede Ilori ní N16,000 ni òun ń gbà fi tọ́jú ọmọ méjì

Aawọ wo lo ti waye sẹyin ninu ẹgbẹ NURTW Eko?

Laipẹ la mu iroyin wa fun yin pe ijọba ipinlẹ Eko ti gbẹsẹle iṣẹ awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ, NURTW, ni Lagos Island, ni ipinlẹ Eko.

Awọn agbegbe ti ọrọ naa kan ni Eyin Eyo, Church Street ati Idumota,

Igbesẹ yii lo waye lẹyin ija igboro to waye lọsẹ to kọja.

Àwọn ọlọpaa RRS ninu atẹjade kan to fisita loju opo Facebook rẹ ni oun mu Abdulazeez Adekunle Lawal ti ọpọ eeyan mọ si Kunle Poly ati Mustapha Adekunle, to tun n jẹ Sego si ahamọ.

Kii si se igba akọkọ niyi, ti awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW yoo maa doju ija kọ ara wọn ni Eko, ti wọn yoo si maa da alaafia ilu ru.