Ibadan Mogajis and Baales: Lẹyìn o rẹyin, ìjọba gbadé lórí àwọn baálẹ́ àti Mogaji Ibadan

Oríṣun àwòrán, Facebook/Olubadan of Ibadan
Adajọ agba ipinlẹ Oyo, adajọ Munta Abimbola ti pasẹ pe ki awọn Mogaji ati baalẹ ti wọn ṣe agbega fun tẹlẹ, pada si ipo ti wọn wa ṣaaju agbega yii.
Igbimọ kan ti Gomina Abiola Ajimobi gbe kalẹ labẹ idari adajọ Akintunde Boade, lo daba, to si fofin de agbega fawọn baalẹ ati Mogaji wọnyi.
Ọdun 2017 ni Gomina tẹlẹ Abiola Ajimobi gbe igbesẹ yii.
Ninu idajọ to gbe kalẹ NI Ọjọbọ, ni idahun si igbẹjọ awọn baalẹ ati Mogaji mẹrinlelọgbọn wọn yi, adajọ Abimbola sọ pe oun ko ri awijare kankan ninu ẹjọ wọn.
- Òfin nìkan ló lè gbadé lórí àwa Ọba ìlú lbadan- Oba Lekan Balogun
- Seyi Makinde kò leè gba adé lórí àwa ọba 21, iléẹjọ́ ni yóò là wá níjà - Lekan Balogun
- Ajimobi kò déédé yan Oba 21, àwọn àgbààgbà ilẹ̀ Ibadan ló bẹ̀ẹ́ láti gbé ìgbésẹ̀ náà- Omowe Gbade Ojo
- Wọ́n ti gbé Olubadan wọ káà ilẹ̀, bí ìsìnkú Ọba Adetunji ṣe lọ nìyí
- Oyè Mọ́gàjí àti Báálẹ̀ ti di owó rèé, ọjà rèé ní Ibadan - Lekan Balogun
- 'Ẹ̀ ń fi ẹ̀wọ̀n run imú o' Ẹ̀yin Olóyè Ibadan mọ́kànlélógún tẹ ń pe ara yin lọ́ba
- Ìsọkúsọ ni Olúbàdàn ń sọ, àwa la lè yọ́ lóyè. òun kò le è yọ́ wá - Lekan Balogun
- A kò ní fi adé wa sílẹ̀ nítorí Olubadan - Àwọn Ọba 27
- Adájọ́ Munta Abimbola ti da ẹjọ́ tí àwọn Oloye Ibadan tó gba adé lọ́wọ́ Ajimobi nú
Tori naa, o wọgile ẹjọ ti wọn pe lati maa jẹ ọba lọ, to si ni oun pa a laṣẹ pe ki wọn mase de ade tabi wọ ilẹkẹ ti yoo ṣafihan wọn gẹgẹ bi Oba.
O tẹsiwaju pe, gbogbo igbesẹ wọn lati wakati yii lọ, gbọdọ wa ni ibamu pẹlu aṣẹ ati ofin ti ijọba gbe kalẹ ni ipinlẹ Oyo.
Aṣẹ ti ijọba Oyo si sọ ni pe ki awọn Baalẹ, Mogaji ati abọbajiroro ti wọn sọ di Oba ati onilẹkẹ, pada si ipo ti wọn wa tẹlẹ ṣaaju ọdun 2017.
Ki lawọn baalẹ yii n beere fun?
Awọn olupẹjọ wọnyii ti pe Gomina ipinlẹ Oyo Seyi Makinde ati awọn mẹrin miran lẹjọ ṣaaju.
Wọn ni idajọ ajumọṣe to wọgile atunto to ṣe agbega awọn ko fẹsẹ mulẹ nitori awọn ko ba wọn lọwọ si adehun ajumọṣe lati yọwọ ninu ẹjọ ti awọn ọba kan ṣe.
Awọn mẹjọ ninu awọn Oba ti Gomina Ajimobi ṣagbega fun, ti ṣaaju sọ fun agbẹjọro wọn, Kunle Sobaloju, pe ko yọwọ ninu ẹjọ ṣiṣe pẹlu Gomina Makinde.
Wọn ni awọn yoo pada si ipo wọn gẹgẹ bi abọbajiroro ti wọn wa ṣaaju ki igbimọ Ajimobi to sọ wọn di Oba.
Awọn baal taa n wi yi sọ pe adehun ati afnuko ti wn ṣe lati ma tsiwaju pẹlu ọjọ yi ko kan awọn tori naa awọn ṣi f ki wọn fi awọn si ipo agbega tawn wa.
Amọ bayi ti wọn ti yanju ọrọ ti adajọ si ti paṣẹ, ko ni si eeyan kankan ninu awọn baal tabi Mogaji wọn yi to le lo ipo Oba lagbegbe wọn bi ti t
Iku Olubadan to waye laipẹ yi lo ṣebi ẹni mu ki wọn pada wa wa nkan ṣe si ọrọ yi nitori pe wn ti n pe lori yiyan ọba tuntun.
Kaka ki ọrọ wa di pe Ibadan ko ni Olubadan lo mu ki awọn abọbajiroro pamọran pọ pe ki wọn ju ipoOba ti Ajimobi fi wọn jẹ silẹ ki ilu baa le to.
Kini o ti kọ́kọ́ sẹlẹ sẹyin lori oye ba jijẹ ni Ibadan?Saaju ni iroyin gbode kan wi pe o ṣeeṣe ki rogbodiyan mii tun ṣẹyọ lori ẹni ti oye Olubadan kan nitori pe ẹjọ ti wọn pe lori ọrọ naa ṣi wa nilẹ ẹjọ.
Ninu igbẹjọ to waye lọjọ kẹrinla, oṣu kini ọdun yii, Adajọ Munta Abimbọla to jẹ adajọ agba n'ipinlẹ Ọyọ kesi awọn ti ẹjọ naa kan lati wa wi tẹnu wọn.
O ni pe nipasẹ awọn agbẹjọro to n ṣoju fun wọn lori erongba wọn nipa lilọ ile ẹjọ kotẹmilọrun lori ọrọ naa.
Ṣugbọn nibayii ti awọn oloye naa ti kesi agbẹjọro wọn lati wọgile ẹjọ naa, o ti han gbangba wi pe gbogbo rogbodiyan ti o rọ mọ ẹni ti o kan lati jẹ oye Olubadan ti ilẹ Ibadan ti tẹnubodo.
Eyi si tumo si pe ko si ejo mo nile ejo lori yiyan olubadan.
Bi adajọ se da ẹjọ awọn oloye Ibadan to di ọba naa nu, lo mu ki asẹ to pa kan awọn baalẹ to di ọba pẹlu.




















