Oyè Ibadan: Àwọn ọba 21 ní kí Olubadan yé fẹnu yẹpẹrẹ adé àwọn

Agba oye Lekan Balogun

Oríṣun àwòrán, Lekan Balogun

Awọn ọba nilẹ Ibadan ti koro oju si ilana ti Olubadan ilẹ Ibadan. Ọba Saliu Adetunji n gba tabuku wọn, ki oriade naa si tete wa idahun si awọn ẹsun tawọn fi kan.

Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan, Agba oye Lekan Balogun, ẹni to sọrọ lorukọ awọn ọba yoku salaye pe bi Olubadan se n fi ẹnu yẹpẹrẹ ade ori awọn ko jẹ itẹwọgba rara.

Bakan naa lo ni, asẹ ti ọba Adetunji pa pe ki awọn si ade ori awọn ko dara, gbolohun naa si n yẹpẹrẹ ofin to ti agbeyẹwo ilana oye jijẹ nilẹ Ibadan nidi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Bi Olubadan se ni ka si ade ori wa, to ni ‘ko bofin mu’, kii se ohun to dara. Dipo ki Olubadan fesi si awọn ẹsun ta fi kan, se lo tun n tabuku wa. "

Agba oye Balogun ni ọpọ ohun to n waye ni aafin Olubadan ko bojumu to, paapa nidi bi igbimọ Olubadan kii se seto ayẹwo mọ fawọn eeyan to fẹ jẹ Mọgaji ati Baalẹ, ko to di pe wọn jawe oye le wọn lori.

Àkọlé fídíò, Ayekofẹnifọrọ: Ó yá, ẹ fi àmì sórí ọ̀rọ̀ náà.

Bakan naa lo ni gbogbo awọn ọba yoku nilẹ Ibadan ni inu wọn kodun si ilana ‘owo ree, ọja ree’, tawọn eeyan n gba jẹ oye Mọgaji ati Baalẹ, eyi to n mu ki Mọgaji meji maa wa lati inu agbo ile kansoso.

Oloye Balogun tun ni Olubadan ti gbe asẹ to wa ninu aafin rẹ le Olori lọwọ, ohun to ba si wu olori lo n pa lasẹ.