Ajimobi: Alaye Ọmọwe Gbade Ojo ti o jẹ olori oṣiṣẹ ni ọfisi gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹri ṣe lori ọrọ oye Olubadan

Oro ẹni ti Oba kan ni ilu Ibdan lo ti n bi Ige ati Adubi loriṣiiriṣii bayii.
Eyi ko ṣẹyin bi Oba Saliu Adetunji ṣe waja lọjọ Aiku to kọja.
Bi awọn kan ṣe n ni Oloye Lekan Balogun, ọkan lara awọn ọba mọkanlelogun to gbade lọwọ Gomina Ajimobi nigba naa ni ipo naa kan ni awọn mii n ni ọrọ kor i bẹẹ.
Eyi lo n jẹ ki awọn mii ru ẹbi ọrọ naa ru Ajimobi lori, ni eyi ti Omowe Gbade Ojo ti o jẹ olori oṣiṣẹ ni ọfisi gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹri sọrọ lori eyi fun BBC Yoruba.
- Oloye Ladoja nìkan ló le sọ bóyá Lekan Balogun yòó di Olubadan tuntun-Moses Orogade
- Ṣé lóòtọ́ ni wọ́n rọ Oba Ijeru, Onpetu Sunday Oladapo lóyè?
- Ọmọkùnrin tó fẹ́ kọ́ṣẹ́ Yahoo wá sọ́dọ̀ wa lẹyìn tó mu Colorado tán ló bá kú- Afurasí ọmọ Yahoo
- Ọmọkùnrin kan bẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin tó lóyún lórí nítorí pé...
- Wo àwọn agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà tó ti dé fún ìgbáradì àti ibi tí ọ̀rọ̀ dé dúró lóri AFCON 2022
Omowe Gbade Ojo ni pe Ajimọbi ko deede ṣe atungbeyẹwo bi a ṣe n jẹ oye Olubadan.
Awọn agbaagba kan nilẹ Ibadan lo ke si i lati gbe igbesẹ naa, ṣugbọn o bani lọkan jẹ pe awọn eeyan naa ko foju han nita lati gbe lẹyin Ajimọbi.
Bakan naa lo menuba Ọpọlọpọ alaye ti Ajimọbi ṣe fun igbimọ Olubadan ti awọn eeyan ilu ki o to gbe igbesẹ naa".
Erongba Ajimọbi ni pe atungbeyẹwo naa yoo mu igbega ba oye Olubadan, bẹẹ sini yoo tun bu ọla fun Olubadan laarin awọn ọba ti o ku.
Omowe Gbade Ojo ni pe Ajimọbi o fẹ ko jẹ pe awọn arugbo lo n jẹ oye Olubadan. Ọ fẹ ki awọn ọdọ to ni oye ti wọn si kawe bẹrẹ sini de ipo Olubadan gẹgẹ bi o ṣe n waye ni awọn ilu nla mii".
O di ọjọ iwaju ki awọn eeyan to mọ iyi igbesẹ ti Ajimọbi gbe.
Ewe ti agbejọro kan kọ ranṣẹ si gomina Ṣeyi Makinde ko le ṣe idiwọ kankan fun ẹni ti o kan lati jẹ oye Olubadan. Ijọba nikan lo lẹtọ lati yan ẹni ti o kan si ipo.





















