Yoruba Nation: Ká má rí! Kò sí aàyè fún ìdìbò Gómìnà ní Osun àti Ekiti- Ilana Omo Oodua

Buahri ati Akitoye

Oríṣun àwòrán, Others

Bi ileri Ilana Omo Odua ba file di imusẹ, o seese ki idibo Gomina to yẹ ko waye nipinlẹ Osun ati Ekiti lọdun yi ma waye rara.

Egbẹ ọmọ Yoruba yi labẹ akoso ọjọgbọn Banji Akintoye sọ pe idibo kankan ko ni waye lawọn ipinlẹ mejeeji yi.

INEC n palẹmọ idibo ni Ekiti nibi ti Gomina Kayode Fayemin kogba saa keji rẹ nile ati Osun nibi ti Gomina Gboyega Oyetola ti fẹ dije dupo saa keji.

Ọjọgbọn Akintoye ninu ọrọ ikini ọdun 2022 sọ pe laarin awọn ajijagbara Yoruba erongba papọ lori pe ki idibo ile asofin ati Gomina ma se waye nilẹ kaarọ o jiire.

O ni: ''Idibo akọkọ ti a fẹ se leleyi ti a o se ninu orileede tiwa gan an''

Àkọlé fídíò, Big Abass gbadura ọdun tuntun fún gbogbo ololufe rẹ

Kaakiri ni Ọjọgbọn Akintoye ti n lewaju ipolongo iwọde ti wọn fi n pe fun idasilẹ Yoruba Nation pẹlu ajijagbara nii Sunday Adeyemo Igboho.

O sọ pe ''ọkan wa balẹ pe orileede Yoruba taa n wa ti de tan.

Nitori naa, ẹ jẹ ki a maa ronu lori nkan ti yoo mu ki ilẹ wa jẹ ibi to dara julọ lati gbe lagbaye.

Ati pe ẹ jẹki a maa ronu nipa awọn nkan ti yoo sọ orileede di ọrẹ atioluranlọwọ awọn alabagbe wa''

Àkọlé fídíò, O tó ìdá méjì àwọn ènìyàn àgbáyé to wà nínú ewu àìsàn ibà

Igba akọkọ ree ti Ilana Omo Odua yoo fi fi ọrọ lile silẹ pe awọn yoo tako eto isejọba bi idibo nilẹ Yoruba.

Ọrọ ikini ọdun ti alagba Banji Akintoye si ti sọ ọrọ yi jẹ ọna kn gboogi ti ikọ ajijagbara IPOB naa lo lati fi sọ laipẹ yi pe awọn ko fẹ ki awọn akẹkọọ maa ka orin orileede Naijiria nile ẹkọ mọ.

Àkọlé fídíò, New year prayers: Gbọgbọọgbọ lọwọ́ n yọ ju orí, gbogbo wa laó yọ ju ọ̀tá wa lọ

Ko daju boya wọn fẹ fi ipa di idibo yi lọwọ ni tabi pe wọn yoo se iwọde ni itako awọn orisi ifiyajẹni ti wọn ni awọn Ypruba n koju labẹ ijọba to wa lode yi.

Ọkan pato ninu ẹhonu wọn ni bi wọn se ni ogunagbongbo ọmọ Yoruba nii, Sunday Adeyemo Igboho ti se n koju ipenija orisirisi lọwọ ijọba amunisin.

Àkọlé fídíò, Ọdún tó súnmọ́ ìdìbò ni 2022, wọ́n ó ni ta ẹ̀jẹ̀ wa sílẹ̀

Wọn ni bẹrẹ lati igba ti ijọba Naijiria fi se ikọlu si ile rẹ to wa ni Ibadan pẹlu ikọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ ni Sunday Igbohho ko ti ri isinmi.

Ohun nikan kọ ni wọn darukọ, wọn ni ''ọmọ ile Ekiti kan naa ti wa ni ahamọ fun aimọye osu lati igba ti ikọlu ile Sunday Igboho ti waye.

Àkọlé fídíò, Prophet Hezekiah New Year Prayer: Gbogbo wa ni ká ṣiṣẹ́ fún ìdàgbàsókè Naijiria

Ko ba ku si ahamọ, ọpọlọpẹ Eledumare to pa a mọ.

Bẹrẹ lati ọdun 2022, a setan lati gbe awọn igbesẹ to lagbara lati tako ifiyajẹni awọn eeyan wa''

Àkọlé fídíò, Ṣé o mọ̀ ipò tí ìlú Owo l'Ondo ní lórí ìtẹ́ Ile Ife? Ẹ kálọ sí ìlú mi