Sudan Coup: Olóòtú ìjọba Sudan, Abdalla Hamdok ti kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́yìn ìwọ́de àwọn ará ìlú

Sudan

Oríṣun àwòrán, EPA

Olootu ijọba fun orilẹ-ede Sudan ti kọwe fi ipo rẹ silẹ pe o to gẹ.

Abdalla Hamdok kọwe fipo silẹ lẹyin ti awọn ara ilu ya si igboro ti wọn si n pariwo kiri olu ilu Sudan, Khartoum.

Ariwo agbara wa lọwọ ara ilu ti o n dari ni wọn n pa kaakiri Sudan, pe asiko ti to lati da iṣejọba pada fun awọn alagbada ni kikun.

O seni laanu pe eeyan meji lo ba iṣẹlẹ naa rin nigba ti awọn ologun lo ipa lodi si awọn olufẹhonuhan nibẹ.

Kini eyi tumo si fun Sudan?

Bi Hamdok ṣe kọwe fipo silẹ yii tumọ si pe awọn ologun ni wọn wa ni ijọba bayii ni Sudan.

Sudan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Eyi si ṣe lodi si igbiyanju awọn eekan kan ni Sudan ti wọn n poungbe fun ijọba Awa-ara-wa.

Ifehonuhan kan ni wọn ṣe ni Sudan ti Aare Omar Al bashir to ti n tuko Sudan fun ọpọlọpọ ọdun fi kuro lori oye nigba naa lọdun 2019.

Àkọlé fídíò, New year prayers: Gbọgbọọgbọ lọwọ́ n yọ ju orí, gbogbo wa laó yọ ju ọ̀tá wa lọ

Loju opo amohunmaworan Sudan ni Abdalla Hamdok ti ṣalaye idi to fi kọwe fipo silẹ pe ninu ewu ni ẹmi oun wa.

O ni oun ti gbiyanju agbara oun gẹgẹ bii eniyan lati yọ Sudan kuro ninu ajaga iparun ṣugbọn wọn ko bu ọla fun adehun ti wọn jọ ṣe.

Àkọlé fídíò, 'Òṣìṣẹ́ Bánkì ni mí l'Amẹ́ríkà kí n tó bẹ̀rẹ̀ Tíátà'

Awọn oloṣelu ati ologun jọ maa n ṣe ijọba orilẹ-ede Sudan papọ ni lẹyin iditẹ gbajọba to waye ni ọjhọ kẹẹdogun, oṣu kẹwaa.

Sugbọn wọn ko yanana odiwọn iye agbara ti ẹnikọọkan laṣẹ lati lo.

Àkọlé fídíò, Ọdún tó súnmọ́ ìdìbò ni 2022, wọ́n ó ni ta ẹ̀jẹ̀ wa sílẹ̀

O ti le ni aadọta eeyan lapapo to ti ku si iwọde lẹyin iditẹ gbajọba naa.

Pro Democracy Sudan Central Doctor's Committee to jẹ igbimọ tẹẹkoto tó wa nibẹ ni ọpọ ẹmi ti ba iṣẹlẹ naa rin.

Àkọlé fídíò, Prophet Hezekiah New Year Prayer: Gbogbo wa ni ká ṣiṣẹ́ fún ìdàgbàsókè Naijiria

Olori aditẹgbajọba ni Sudan, Abdel Fattah Al Burhan gbe sẹyin idite gabjoba to waye loṣu kẹwaa naa pe ologun ko fẹ ki ogun abẹlẹ ṣẹlẹ ni Sudan ni.

O ni awọn ologun ṣi n foju sona fun iṣejọba alagbada pẹlu eto idibo ti wọn n gbero pe ko waye lọdun 2023 ni osu keje.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa Ondo: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelo