Sunday Igboho's lawyer: Pelumi Olajengbesi le gbàbọ̀dè fún wá lọ́dọ́ ìjọba Naijiria- Ilana Omo Oodua

Sunday Igboho, Pelumi Olajengbesi ati ami idanimọ ẹgbẹ Ilana Omo Oodua

Oríṣun àwòrán, others

Ẹgbẹ to n ṣakoso ipolongo fun idasilẹ Yoruba Nation, Ilana omo Oodua, ti fesi si ikede ti agbẹjọro kan, Pelumi Olajengbesi fi sita pe oun ko ṣiṣẹ gẹgẹ bi agbẹjọro fun Sunday Igboho mọ.

Ọjọ Aiku ni agbẹjoro naa, to fi ilu Abuja ṣe ibujoko kede lori ayelujara Facebook rẹ pe oun ko ṣiṣẹ naa mọ.

Eyi waye lẹyin ọjọ diẹ ti Oludari ẹgbẹ ilana omo Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye kede pe awọn ko nii gba ki idibo gomina waye ni ipinlẹ Osun ati Ekiti lọdun 2022.

Agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Maxwell Adeleye sọ ninu atẹjade kan pe kii ṣe ori ayelujara ni awọn ti gba Olajengbesi gẹgẹ bi agbẹjọro fun amugbalẹgbẹ Sunday igboho ti ajọ DSS ko loṣu Keje, ọdun 2021.

O ni nitori naa ni ko ṣe bojumu fun lati kọwe fi iṣẹ naa silẹ lori ayelujara.

Àkọlé fídíò, Orí Tẹlifísàn ni mo ti rí Sunday Igboho rí láyé mi, bí ìyà ṣe jẹ mi gbé láti Ibadan, dé Àtìmọ́lé DSS rèé - Ifasooto Dada

Ọgbẹni Adeleye sọ pe awọn fẹ ki gbogbo aye mọ pe Olajengbesi fi isẹ silẹ nitori bi gbogbo ọmọ Yoruba nile ati lẹyin odi ṣe koro oju si bo ṣe n tako Ọjọgbọn Banji Akintoye lori ayelujara nitori pe o ni idibo ko ni waye ni ipinlẹ Osun ati Ekiti lọdun 2022.

O ni ṣaaju ni agbẹjọro naa ti tọrọ aforiji lẹyin ti awọn pe akiyesi rẹ si ọrọ buruku to kọ, amọ to ṣe nkan to yatọ.

"A ko le gba ko ṣi ma a ṣoju awọn amugbalẹgbẹ Sunday Igboho, niwọn igba to ti sọ pe oun ko nii dasi ohunkohun to nii ṣe pẹlu Sunday Igbo tabi iponlongo fun Yoruba Nation."

"Ihuwasi Olajengbesi laarin wakati mẹrinlelogun to kọja ti fihan pe yoo gba ibọde fun wa, ti yoo si tà wa fun ijọba apapọ."

Ọgbẹni Adeleye sọ pe Olajengbesi kii ṣe agbẹjọro fun Sunday Igboho gẹgẹ bo sẹ n pe ara rẹ. O ni ẹgbẹ Ilana ọmọ Oodua lo gba a siṣẹ nipasẹ Yomi Aliyu to jẹ agbẹjọro Igboho.

O fi kun ọrọ rẹ pe agbẹjọro naa lo anfaani yii lati sọ ara rẹ di gbajumọ, to si ti n lo anfaani bo ṣe di ilumọọka lati sowọpọ pẹlu ijọba Naijiria lati ta Sunday Igboto ati ijijagbara ẹgbẹ naa nitori owo ati èrè oṣelu.

Agbẹjọ́rò Sunday Igboho kọ̀wé fẹjọ́ rẹ̀ sílẹ̀

Ọkan gboogi lara awọn agbẹjọro to n gbẹjọro fun oloye Sunday Igboho, Amofin Pẹlumi Ọlajẹngbesi ti kọwe fipo silẹ gẹgẹ bi agbẹjọro rẹ.

Amofin Ọlajẹmgbesi ko ipa ribiribi ninu ilakaka ati gba awọn eeyan ti awọn agbofinro DSS ko ni ile oloye Sunday Igboho loṣu keje ọdun 2021 ti wọn kọlu ile rẹ lọganjọ oru.

Àkọlé fídíò, Ooni: A kìlọ̀ fún Sunday Igboho pé kó dákẹ́ àmọ́ kò gbọ́, èébú ló ń bú wa

Mejila ninu awọn eeyan naa ni wọn ti gba silẹ ti meji miran ṣi wa ni ahamọ awọn DSS lẹyin ti wọn fi ẹsun igbesunmmi kan wọn nile ẹj giga apapọ to wa nilu Abuja.

Bakan naa lo tun ko ipa ribiribi ninu itusilẹ Faṣootọ Dada ti wọn mu pe o n ṣe oogun fun Sunday Igboho.

Àkọlé fídíò, Ayinla Kollington: ọ̀rẹ́ ni èmí àti Barrister kó tó jáde láyé

Amofin Pẹlumi Ọlajẹngbesi ṣalaye ninu atẹjade to fi sita loju opo Facebook rẹ lọjọ Aiku pe oun n yọwọ ninu gbigbẹjọro fun ohunkohun to ba niiṣe pẹlu Sunday Igboho atawọn to n ja fun idasilẹorilẹede Yoruba ti a mọ si Yoruba nation.

Pelumi Olajengbesi atawọn kan lara awọn eeyan tawọn DSS ko ni ile Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Pelumi Olajengbesi/facebook

Bi o tilẹ jẹ pe ko sọ idi kan ni pato ti o fi n jawọ lọrọ Igboho atawọn ajijagbara fun orilẹede Yoruba,

Amofin Pẹlumi yan an ninu atẹjade naa pe 'lootọ loun nigbagbọ ninu iṣejọba tiwantintiwa to n bọwọ fun ofin.

Sugbọn emi kii ṣe ọkan lara awọn ajijagbara fun idasilẹ orilẹede Yoruba tabi ẹgbẹ yoowu to ba fi ara pẹ ẹ."

Àkọlé fídíò, Èmi nìkàn kọ́ ni mó n ṣe àkójọ orin- Fasoyin

Bakan naa lo tun ṣalaye pe ọrọ kan ti oun sọ fesi si ọjọ Ọjọgbọn Banji Akintoye lori ijijangbara fun idasilẹ Yoruba kii ṣe lati domi ọka ijijangbara naa da sina bikoṣe ero oun gẹgẹ bi oun ṣe lẹtọ sii labẹ ofin.

Àkọlé fídíò, Ohun mẹ́jọ tóo ní láti mọ̀ bí o bá fẹ́ lọ ilé ọdun