Sunday Igboho: Agbẹjọ́rò ajìjàgbara fún Yoruba Nation sọ̀rọ̀ lórí ‘èròngbà’ ìjọba láti pàá

Oríṣun àwòrán, others
Ẹnikan lara awọn agbẹjọro fun Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho, Amofin Yomi Aliyu, ti sọ pe irọ ni iroyin to ni ijọba Naijiria n gbero lati pa onibara oun.
Ọjọru to kọja ni Aliyu fi ikede sita ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu iwe iroyin Vanguard.
Ṣaaju ni ẹni to jẹ amugbalẹgbẹ Sunday Igboho fun eto iroyin ati ibanisọrọ, Olayomi Koiki, fi ikede sita ni ori ayelujara Facebook rẹ pe iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari n ṣeto bi wọ̀n o ṣe pa Igboho sinu ọgba ẹwọn to wa ni orilẹ-ede Benin.
Ṣugbọn ninu ọrọ, Amofin Aliyu sọ pe orekoore ni oun n ba iyawo Sunday Igboho, Ropo, sọrọ, ti ko si fi igba kankan sọ iru nkan bẹẹ fun oun.
O ni oun ko ni oye nipa erongba ijọba.
Aliyu ni: "Amọ ṣa, o dara ki ẹnikẹni to ba n gbero iru nkan bẹẹ tun ero rẹ pa. Nitori pe ti nkankan buruku kankan ba ṣẹlẹ si Igboho ninu ẹwọn, ijọba apapọ lao di ẹbi rẹ ru.
"Nitori ki wahala ma ba ṣẹlẹ la ṣe n kilọ fun awọn ọmọ ẹyin Sunday Igboho ati awọn ọdọ Yoruba pe ki wọn o ma ṣe idajọ lọwọ ara wọn, ṣugbọn to ba ni ẹni to fẹẹ wo nakn ti yoo ṣẹlẹ ti Igboho ba ku, ko da ero naa nu."
Ninu iroyin miran lo ti jẹyọ pe aṣaaju ipolongo fun idasilẹ orilẹ-ede Oduduwa, Sunday Igboho, ranṣẹ ọdun tuntun sita lati ọgba ẹwọn.
Agbẹjọro rẹ miran to fi ikede naa sita, Pelumi Olajengbesi sọ pe Igboho fi ọrọ ranṣẹ pe oun ko ba ijọba apapọ tabi awọn gomina mẹfa to wa ni Iwọ-oorun Gusu Naijiria jagun.
O ni ṣugbọn ibanujẹ lo jẹ fun oun pe ijọba Buhari ko tii wa ojutu si awọn ipenija to fa ipolongo fun Yoruba Nation.
Ninu ọrọ rẹ, Sunday Igboho sọ pe eto aabo to mẹhẹ ni agbegbe Ibarapa ati awọn agbegbe miran nilẹ Yoruba, nibi ti awọn darandaran ti n pa awọn agbẹ ni ipakupa, lo pilẹ ijijagbara oun.
"Gbogbo eeyan lo yẹ ko ni ifọkanbalẹ pe aabo wa fun oun, lai fi ẹ́yà tabi ẹ̀sìn ẹni naa ṣe.
"Nkan ẹyọkan ṣoṣo ti mo n beere lọwọ ijọba ni pe ki wọn o wa ọna abayọ si nkan to pilẹ ijijagbara fun Yoruba Nation."
Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje, ọdun 2021 ni awọn oṣiṣẹ alaabo mu Sunday Adeyemo ni papakọ ọkọ ofurufu Cadjèhoun nilu Cotonou lorilẹ-ede Benin.




















