Garba Shehu: Ẹ ò kàn mọ̀ ni, Ààrẹ Buhari ń ran ètò ìjọba àwa ara wa lọ́wọ́ ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmad
Oluranlọwọ pataki fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Garba Shehu tun ti tanmọlẹ si eredi ipinu Aarẹ lati ma fọwọ si atunṣe iwe abadofin fun ọdun 2021.
Ninu ọrọ to fi sita lọjọ Iṣẹgun, Ọgbẹni Shehu ni ipinu yii wa lara akitiyan lati da abo bo eto ijọba awa ara wa lorilẹede Naijiria bẹẹ si ni aarẹ yoo ṣe ohunkohun to ba gba lati da abo bo o.
"O tọ ka sọ pe ẹgbẹ oṣelu APC to wa lori alefa lọwọ to si jẹ ọkan lara awọn ẹgbẹ oṣelu to tobi ju lorilẹede Naijiria jẹ ọkan lara awọn ti yoo jẹ anfani iru abadofin bayii amọ kii ṣe iṣẹ ijọba yii lati da abo bo ẹgbẹ oṣelu APC bikoṣe lati da abo bo Naijiria atawọn eeyan rẹ.
Ni ọjọ Iṣẹgun to kọja ni Aarẹ Buhari kọ lati buwọlu atunṣe abadofin kan to ni ṣe pẹlu oṣelu.
Ninu esi to fi ṣọwọ si ile igbimọ aṣofin, aarẹ tọka si oniruuru kọnu-n-kọhọ to wa ninu abadofin naa to fi mọ nipa ofin, ọrọ aje ati ipenija abo.
Bakan naa o fi kun un pe o maa ni ipa buruku lori ẹtọ awọn araalu lati le kopa ninu iṣejọba gẹgẹ bo ṣe wa ninu alakalẹ ofin.
Lara awọn amugbalẹgbẹ aarẹ mii, Femi Adesina ti ṣaaju tẹnu mọ ohun to n mumu lọọkan aya aarẹ to si ni o ti beere fun ero awọn ti ọrọ kan ko to ṣe ipinu yii.
O ṣalaye nipa okun ti Naijiria ni gẹgẹ bii orilẹede ati ipo rẹ gẹgẹ bi ọkan lara awọn orilẹede ti ọrọ aje wọn pọ yanturu ni Naijiria wa gẹgẹ bi nkan iwuri to si ni gbogbo eyi ti wa ninu iwe abadofin oṣẹlu ti ọdun 2010.
"Abadofin yii kan naa ni wọn gbe wa ti wọn fẹ ka ṣe atunṣe rẹ lojuna ati mu agbegba ba ilana ijọba awa ara wa". Amọ ileeṣẹ aarẹ ni lẹyin ayẹwo kikun awọn woye pe kii ṣe bẹẹ lori.
Wọn ni ipinu bi ijọba ṣe kọjalẹ lati buwọlu abadofin ọhun ti la aarin awọn tọrọ kan nipa iroyin ati oṣelu kọja.
Torinaa ileeṣẹ aarẹ ni igbesẹ ti wọ́n gbe yii yoo ko ipa rere ni aye gbogbo ọmọ Naijiria. Wọn ni awọn ni eto to wa nilẹ ti yoo fara kan ilana ofin, isuna, ọrọ aje, ipenija aabo fun Naijiria lara eyi to lee mu nkan gbowo lori sii nigba ti awọn ẹgbẹ oṣelu yoo fi maa ṣe idibo.
Ibeere ti wọn beere ni pe "ta ni yoo gbe ọwọngogo yii lori? Awọn to n san owo ori nii, awọn wo ni yoo wa janfani? Awọn to lowo laarin oloṣelu".
Wọn ni ko lee ṣeeṣe lasiko yii ti orilẹede n gbiyanju lati yọ ara rẹ kuro ninu ẹrẹẹ ibajẹ ọrọ aje, ipenija ilera lagbaye, ti wọn si woye pe asiko yii kii ṣe fun nina owo lori awọn nkan yẹpẹrẹ ti yoo tun dakun iṣoro to wa nilẹ.
"Fun awọn to si jẹ pe ifẹ wọn ni ki a maa na iye owo ilu to ku lori ọrọ oṣelu lasiko ti iṣoro gba ile aye kan yii, a n sọ fun yin pe: ẹ jawọ ninu ere gele yii. Ẹ sọ ohun tẹẹ fẹ gan jade fun awọn ọmọ Naijiria nipa owo wọn".


















