2022 Prophecies: Àwọn ólọ́pàá Ghana kìlọ̀ fáwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run làti ṣọ́ ẹnu wọn nípa sísọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ọdún 2022

Mọsalasi ati Sọọsi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Ghana ti kilọ fun awọn olori ẹlẹsin gbogbo lorilẹede naa lati ṣọ ẹnu wọn pẹlu sisọ asọtẹlẹ fun ọdun 2022.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita ti wọn pe akori rẹ ni "sisọ asọtẹlẹ ati atubọtan rẹ la ẹ ofin" ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede naa jawe ikilọ fawọn ojiṣẹ Ọlọrun ninẹ lati ṣọra fun gbingbin ẹru si ọkan araalu.

Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Ghana ṣalaye pe ọpọ awọn asọtẹlẹ atẹyinwa lo ti fa wahala, hilahilo ati ibẹrubojo laarin araalu nibẹ.

O fi kun un pe lootọ lawọn ijọ ati ẹgbẹ ẹlẹsin ni ẹtọ ati jọsin ari lati sọ ti ẹnu wọn laisi idiwọ tabi idena, sibẹ wọn tun gbọdọ bọwọ dun ẹtọ awọn araalu yoku naa.

Àkọlé fídíò, Orí Tẹlifísàn ni mo ti rí Sunday Igboho rí láyé mi, bí ìyà ṣe jẹ mi gbé láti Ibadan, dé Àtìmọ́lé DSS rèé - Ifasooto Dada

Awọn ọlọpaa lorilẹede Ghana ṣalaye bi awọn asọtẹlẹ atẹyinwa ṣe fa ọpọlọpọ ijamba ati ifẹmiṣofo, ti o si tun fa hilahilo ba igbe aye awọn araalu miran.

Atẹjade naa tun ran awọn eeyan orilẹede naa leti pe ẹṣẹ nla ni labẹ ofin orilẹede naa lati gbe iroyin, gbọyisọyi tabi ọrọ to lee fa ibẹruboju tabi ipayinkeke sita.

Bakan naa lo jẹ ẹṣẹ nla lati gbe iroyin aṣinilọna tabi ofege to lee fa ikunsinu tabi pagidina iṣẹ awọn ajọ adoola ẹmi tabi to lee mu wahala ba igbayegbadun araalu.

"A wa rọ gbogbo ọmọ Ghana, paapajulọ awọn olori ẹsin lati ṣọ ọrọ ẹnu wọn paapaajulọ to ba niiṣe pẹlu sisọ asọtẹlẹ eleyii to lee fa wahala tabi awọn ohun to lee tigi bọ oju ẹtọ awọn araalu miran. "

Àkọlé fídíò, Bi mo ṣe fi Ọtí, Igbó, Sìgá mímu sílẹ̀ tí mi ò kó obìnrin tó máa ń ba ayé awọn olórin jẹ́ - J.A Adelakun tó kọ orin "Amona tete