Annual Festival Osun: Wàhálà bẹ́ sílẹ̀ níbi ayẹyẹ ọlọ́dọọdún ní ìpínlẹ̀ Osun

Oríṣun àwòrán, city mirror
Ile iṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Osun ni oun ko le fi idi rẹ mulẹ pe lootọ ni wọn yin ẹnikẹni ni ibọn ni ibi ti wahala ti bẹ silẹ ni agbegbe Igbaye nijọba ibilẹ Odo-Otin nipinlẹ Osun lọjọ Aje.
Ṣaaju ni iroyin kan ti n tan ka pe wọn yin ọkunrin kan ni ibọn nibi ayẹyẹ ọlọdọọdun ti o ma n waye ni agbegbe naa ti awọn ẹgbẹ alatako meji kan si fi ija pẹẹta.
Ninu ọrọ rẹ, agbẹnusọ ọlọpaa ni ipinlẹ Osun Yemisi Opalọla ṣalaye fun BBC Yoruba pe lootọ ni ile iṣẹ ọlọpaa gbọ pe idarudapọ waye ni ilu Igbaye ti wọn si pe akiyesi ọlọpaa sii.
- Àwọn wò ló jí àna Gómìnà Okorocha gbé nílé ìjọsìn lọ́jọ́ kejì Kérésìmesì?
- Kí ló ṣẹlẹ̀ tí a fi ń pé ọjọ́ kejì Kérésì ní 'Boxing Day'?
- Wo ọ̀nà mẹ́fà láti dènà ìkọlù ejò afàyàfà bí o ṣe ń lo ìsinmi ọdún Kérésìmésì yìí ní abúlé rẹ
- Ṣé lóòótọ́ ni Garba Shehu, àwọn amugbalegbe Ààrẹ Buhari ti fara kásáa Covid-19?
O fi kun un pe bakan naa ni wọn ran awọn osiṣẹ ọlọpaa lọ si ibi iṣẹlẹ ọhun lati lọ pẹtu si aawọ to n waye nibẹ ṣugbọn titi di asiko yii, ọga ọlọpaa to n moju to agbegbe naa ko tii jabọ pe, wọn yin ẹnikẹni ni ibọn lasiko iṣẹlẹ naa.
Sugbọn gẹgẹ bi awọn ti ọrọ naa ṣẹlẹ loju wọn se lasiko ti ayẹyẹ ọlọdọọdun naa n lọ lọwọ ni awọn ẹkan kan nibẹ fẹsun kan pe awọn ko nifé si iru orin ti wọn gbe jade, ti o si gbiyanju lati da orin naa duro.
Iroyin sọ pe, awọn ẹgbẹ keji fariga lori igbesẹ yii ti wọn si jọ fi ija pẹẹta.
Lasiko ija yii ni wọn ni wọn yin ibọn mọ ọkunrin kan ti wọn ko mọ orukọ rẹ, eyi si lo mu ki gbogbo ara ilu maa sa kijokijo fun aabo ara wọn.
Ọkan ninu awọn to ba oniroyin sọrọ ti ko si fẹ ki orukọ oun jade ti ṣaaju sọ pe ija oye wa nilẹ ninu ilu naa ṣaaju asiko yii.
" Ọrọ ija oye ti o ti wa nilẹ tẹlẹ lo sokunfa iru iṣẹlẹ yii, wọn n ja lori ẹni ti yoo jẹ ọba, wọn yinbọ pa ẹni kan nigba ti awọn miiran fi ara pa pẹlu ọgbẹ ada".
Titi di asiko yii, ọlopaaa ni awọn ko le fi idi rẹ mulẹ iye eniyan ti o ku tabi farapa, ṣugbọn awọn ọlọpaa ti lọ sibẹ lati pẹẹtu si aawọ to n waye.
















