Nigeria's borrowing: A tún fẹ́ yá N12 Tiriliọ̀nù láti ilẹ́ òkèrè kí gbèsè Nàìjíríà di N50 tiriliọnu- BMO

Oríṣun àwòrán, Muhammadu Buhai/Instagram
Ijọba orilede ni awọn yoo tun ya tiriliọnu mejila naira kun gbese ti o ti wa nilẹ tẹlẹ.
Ni bayii gbogbo gbese Naijiria yoo di aadọta tiriliọnu Naira, eyi ti ti abẹle yoo jẹ tiriliọnu mejidinlọgbọn din diẹ naira nigba ti ti ilẹ okere yoo si jẹ tiriliọnu mọkanlelogun ati diẹ naira.
Gẹgẹ bi iwoye ile isẹ to n seto ọrọ ilu se ro o fun ọdun 2021 si 2025.
- DDS ní kí n di ológbò bíi Sunday Igboho, ojú mi rí tó ní àhámọ́ DSS l'Abuja- Ifasooto
- Desmond Tutu, Àlùfáà tó wú ni lórí àti ajìjàgbara eléyàmẹ̀yà tó jáde láye, ohun tẹ́ẹ ní láti mọ̀ rèé
- Mọ̀ síi nípa Olorì Abibat Nihinlola Adeyemi tó ti lo ọdún 60 gẹ́gẹ́ bíi olorì láàfin Alaafin Oyo
- Olùkọ́ni ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù U-17 ní Gabon di èrò àtìmọ́lé fún ẹ̀sùn fífipá bá àwọn agbábọ́ọ́lù ọ̀kùnrin sùn
Ẹka to n ri si amojuto gbese ni Naijira ṣalaye pe, ni bayi Naijria ti jẹ gbese tiriliọnu mejidinlogoji ni aarin osu mẹsan ọdun 2021, eyi ti o si pọju ninu rẹ waye laarin oṣu keje si ikẹsan ọdun 2021.
Eyi tumọ si pe ijọba aarẹ muhammadu Buhari yoo ti ya tririliọnu mejila laarin ọdun meji to jẹ 2021 si 2023.
Ẹwẹ, gẹgẹ bi ipinu ijọba, wọ́n fẹ mu adinku ba gbese ilẹ okere ni ọdun 2025.
Awọn onimọ nipa eto ọrọ aje Omosuyi Temitope ṣalaye pe nigba ti yoo fi di ọdun 2022, owo ti ijọba yoo maa ri ko ni to san gbese owo ti wọn ti ya.
O salaye pe nigba ti yoo fi di ọdun to n bọ (2022) ida ọgọrin owo to n wọle ni wọn yoo maa fi san gbese, ṣugbọn bi ọrọ se n lọ yii, ijọba ni idi pataki ti wọn fi nya owo.
O ni bi o tilẹ jẹ pe ni ọpọ igba ti orilede ko ba ya owo, o le maa ri awọn nkankan to se pataki ṣe fun ara ilu, ti o si jẹ pe orilede Naijiria nilu awọn eto kan ki o wa nilẹ lati mu idagbasoke ba ara ilu.
Ẹwẹ, o fi kun un pe ki ijọba na owo naa lati se agbekalẹ awọn eto ti yoo maa mu owo wa ki wọn baa le ni anfani lati san owo naa pada.
Bakan naa ni ọjọgbọn Fasiti OOU Ago Iwoye, Sheriffdeen Tella to jẹ onimọ nipa eto ọrọ aje ṣalaye pe bi ijọba se n ya owo yii jẹ nnkan ti ko fi 'ni lọkan balẹ rara.
Ati pe nibi ti ọrọ de yii ko yẹ ki ijọba tun maa ronu ati ya owo mọ, "o jẹ nnkan ti o ba ni lọkan jẹ pe ijọba saba maa n ronu pe awọn fẹ yawọ ni ṣaa, kaka ti wọn yoo fi ronu ọna miiran lati ri owo".
O ni kaka ti ijọba yoo fi maa ya owo ni gbogbo igba, o ṣe pataki ki ijọba fun ina mọ awọn to jẹ orilẹede ni gbese, bi apẹrẹ laipe yii ni ile isẹ NEITI tu aṣiri awọn owo ilu kan ti o wa lọwọ awọn olowo ọmọ orilẹede yii.
Owo to le ni triliọnu ṣugbọn ẹgbẹ kan ni ijọba n gboju si.
O tun ṣalaye pe alafo asiko ti ijọba fi n ya owo kii se eyi ti o ba oju mu rara, pe ati ri i san ko si daju.
















