2021 Year end: Sunday Igboho Yoruba Nation, Ikú TB Joshua, Oniduro Mi, fídíò ìbálòpọ̀ Tiwa Savage àti ìgbẹ́jọ́ Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Manigbagbe ọdun ni 2021 jẹ fun ọpọ kaakiri agbaye ṣugbọn ni Naijiria ara ọtọ ni ọdun yi jẹ.
Ni ibẹrẹ ọdun ni ọpọ n ṣadura pe ki wahala ati iporuru ọkan to ba 2020 wa ma ṣe tẹsiwaju ni 2021.
Ni bayi ti ọdun 2021 ti wa n de opin lọ diẹdiẹ, a ni ka gbiyanju lati ṣe agbeyẹwo awọn iṣẹlẹ manigbagbe to waye ni Naijiria lapapọ ati ilẹ Kaarọ jiire ni pato.
Apa kini ree ninu awọn iṣẹlẹ manigbagbe taa n ko jọ. Ẹ tẹti lekolati maa fi ọkan ba wa lọ lori eyi to ku.

Iku mu TB Joshua lọ

Oríṣun àwòrán, odas
Ikede iku gbajugbaja oniwaasu yi da bi ala fun ọpọ awọn ọmọlẹyin rẹ.
Oludasilẹ ati wolii agba Synagogue Church of All Nations (SCOAN), Temitope Balogun Joshua jẹ ọkan lara awọn oniwaasu Naijiria to lokiki.
Lọjọ karun un oṣu kẹfa ni ile ijọsin rẹ kede iku rẹ loju opo ayelujara ni bo ṣe ku ọjọ diẹ ko ṣe ọjọ ibi rẹ.
Kaakiri agbaye ni iranṣẹ ibanikẹdun ti wa lẹyin to jade laye lẹni ọdun mẹtadinlaadọrin
Ijọba Naijiria fofin de lilo Twitter

Oríṣun àwòrán, Tweet
Loṣu Kẹfa ọdun 2021 ni ijọba Naijiria sọ pe o to gẹ. Awọn ti gbegi dina oju opo ibaraẹnisọrọ Twitter.
Minisista feto aṣa ati iroyin Lai Mohammed lo kede igbegidina Twitter ninu atẹjade kan nilu Abuja.
Mohammed sọ pe awọn gbe igbesẹ yi nitori pe igbesẹ ileeṣ naa n tapa si igbe aye orileede Naijiria
Titi di baa ṣe n sọrọ yi, agadagodo ṣi wa lẹnu Twitter, ko ribi fọhun ni Naijiria.
Yoruba Nation di orin apilẹkọ nilẹ kaarọ o jiire

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho/Instagram
Sunday Igboho Igboho ooṣa baba Dami di ilumọọka ni Naijiria lọdun 2021.
Kaakiri ilẹ Yoruba ni ipolongo rẹ lori idande ẹya Yoruba ti gbalẹ bi oṣumare.
Ọrọ yi kan ara ile o kan ara oko titi de bi pe awọn ajọ ọtẹlmuyẹ Naijiria DSS ṣe ikọlu si ile rẹ.
Abalọ ababọ, ijọba Naijiria lawọn gbegi dina akoto owo Igboho ti Sunday Igboho si sa kuro nilu l si Benin Republic.
Cotonou ni ọwọ awọn agbofinro ilẹ naa ti tẹ Igboho ti wọn si ti i mọle pe o tapa si ofin ilẹ naa.
Ni ilẹ oni to mọ yi, Sunday Igboho ṣi wa ni ahamọ ni Benin Republic ti ọpọ si n kesi ijọba ilẹ naa lati tu silẹ
!["Nnamdi Kanu arrested today": [Ipob news] 'Nnamdi Kanu extradition arrest' in Nigeria ', go appear for Nigeria court - 'Abubakar Malami'](https://ichef.bbci.co.uk/ace/ws/640/cpsprodpb/C1F5/production/_119135694_nnamdikanuarrestinnigeria.jpg.webp)
Oríṣun àwòrán, Other
Ba ṣe n wi ti Igboho nilẹ Yoruba ni awọn eeyan ẹya Igbo naa n ke pe ki ijọba tu ajijagbara ti wọn naa Nnamdi Kanu silẹ.
Lẹyin nkan bi ọdun meji ti ijọba Naijiria lawọn ti n wa Kanu ni wọn ṣadede kede pe ọwọ awọn ti tẹ.
Minisista feto idajọ Abubakar Malami lo fi ikede yi sita pe awọn pawọpọ pẹlu agbofinro mii lagbaye lati le mu Kanu ni.
Wọn da Kanu pada si Naijiria to si ti n jẹjọ lori sun igbesunmọmi ti ijọba fi kan an.
Ile alaja pupọ to da wo ni Ikoyi

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Lọjọ Kini oṣu Kọkanla ọdun 2021 ni iroyin kan pe ile alaja mọkanlelogun kan da wo lagbegbe Gerard ni Ikoyi da wo.
Ile naa ti wọn si n kọ lọwọ da wo lulẹ nigba tawọn eeyan kan to fi mọ ẹni to ni ile naa ha si abẹ rẹ.
Iṣẹl yi fọwọ kan ọpọ eeyan lẹmi ti ijọba si gbe igbimọ kal lati wadii ohun to ṣokunfa ti ile yi fi wo.
Ọpọ eeyan lo padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ naa ti o si mu iriwisi ọtọọtọ wa lati ọdọ awọn eeyan Naijiria ati awọn mii lagbaye.
Fọnran fidio ibalopọ Tiwa Savage to lu sita

Oríṣun àwòrán, Tiwa Savage
Ọrọ naa dabi ere ṣugbọn nigba ti fọnran fidio naa yoo fi lu sita, awọn eeyan mọ pe lootọ ni.
Gbajugbaja akọrin takasufe Tiwa Savage ni eeyan kan n dunkoko mọ pe oun yoo lu fidio ibalopọ rẹ sita ti ko ba fun oun lowo.
Tiwa ni ko ṣe oun to ba wu afi bi ẹni naa si ṣe fi fidio ibalopọ Tiwa ati ọrẹkunrin rẹ sita.
Ọrọ yi da awuyewuye silẹ ti awọn kan si ni o da bi ko ṣe san owo fun ẹni naa.
Awọn to n ba Tiwa da owo pọ kan taa mọ si sponsors yọwọ kuro ninu ibaṣepọ pẹlu akọrin yi nitori fọnran fidio naa.
Igbẹjọ Baba Ijesha ati Princess lori ẹsun ifipabọmọde lo pọ
O loju igbẹjọ to mu iriwisi wa bi ti eleyi to ni ṣe pẹlu ẹsun ti wọn fi kan oṣere tiata Yoruba nii Baba Ijesha.
Laarin igba ti wọn fi bẹrẹ ẹjọ yi, ko fẹẹ si nkan tawọn eeyan ko sọ tan lori ẹjọ yi.

Oríṣun àwòrán, Princess Comedian, Baba Ijesha
Bẹrẹ lati ọrọ lori beeli titi dori agbẹjọro ti Ijesha gbe wa si ile ẹjọ to fi mọ awọn oṣere to gbaruku ti Ijesha ati awn to gbe lẹyin Princess, ẹjọ yi mu awuyewuye wa to pọ.
Titi di baa ṣe n sọr yi wọn ko ti yanju ọrọ naa.
Ẹkunrẹrẹ bo ṣe n lọ wa loju opo wa.
Adeyinka Alaseyori di ilumọọka tori itasi (Oniduro Mi)

Oríṣun àwòrán, Alaseyori/Tope Alabi
Gbajugbaja olorin ẹmi ni a n pe Adeyinka Alaseyori bayii tori ni ibẹrẹ ọdun yii, oun funra rẹ lee fọwọ sọya pe "ko sẹni to mọ mi" amọ ni ipari ọdun yii ko lee ka ore ati iyi to ti ri gba.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ni oṣu melo kan sẹyin ni agba olorin ẹmi ti agbaye mọ, Tope Alabi sọ jade ni ibi kan to ti n kọrin pe ko yẹ ki ẹni to kọ orin Oniduro mi pe Ọlọrun Ọba ni Oniduro tori o ti foju kere Ọlọrun ju.
Afi bi igba ti ina ran ni ọrọ yii ṣe bẹrẹ si ni ran lori ayelujara Naijiria to fi ta ka de agbaye leyi ti awọn eeyan gbe e sori gidi gan ti wọn n sọ oniruuru ero wọn ati fifi ọrọ ranṣẹ si awọn mejeji ti ọrọ kan.
BBC Yoruba tan ina wa kulẹ kulẹ ọrọ yii, loju ọna hun gan la tun ti ri i pe ẹni ti Ọlọrun fun ni orin "Oniduro Mi" ọhun gan yatọ amọ oju ẹni to kọ ọ jade ti aye fi mọ ọ ni awọn eeyan bẹrẹ si ni gbe gẹẹ gẹ a si ṣe ifọrwanilẹnuwo pẹlu arabinrin naa.
Bo tilẹ jẹ pe ọrọ ti di ọrọ iya ati ọmọ ninu orin ẹmi bayii tori Adeyinka Alaseyori ti ni iya oun ni Tope Alabi torinaa ko si ọrọ ija kankan mọ laarin awọn to ti pa awọn eeyan lẹnu mọ yala wọn wa lẹyin Tope ni tabi Alaṣeyori.
Amọ ipa ti iṣẹlẹ yii ti ko laye Alaseyori ko ṣee ko kuro mọ tori di asiko ti a n sọrọ yii, oniruuru ẹbun lo ti gba tori ipo nla to di mu lọkan awọn eeyan lagbaye bayii tori ohun orin ti Ọlrun fi ta a lọrẹ ti aye baa pariwo. Ẹbun ọkọ, oniruuru ẹbun, kikọ orin fun awọn eeyan nla nla koda, irinajo lọ si oke okun pẹlu ọkọ ati ọmọ rẹ lati lọ kọrin wa ninu awọn ore ti iṣẹlẹ ọhun ti ko rọ ọ lara ti ko si ṣee ko kuro mọ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Joshua Iginla Ministries
Nibi ni a o fi adagba rọ si lori awọn iṣẹlẹ manigbagbe lọdun 2021.
Ẹ ma gbagbe pe oku nibọn n ro.
A o maa tẹsiwaju pẹlu awọn iṣẹlẹ mii loju opo wa.
Ẹmi wa yoo rẹyin ọdun!



















