Ikoyi Collapsed Building: Àwọn ohun pàtàkì nípa Femi Osibona rèé

Femi Osibona

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Ni irọlẹ ọjọbọ, ọjọ Kẹrin osu Kskanla ọdun 2021 ni iroyin gba ilẹ kan pe ikọ to n se awari awọn eeyan to ha si abẹ ile to da wo ni Ikoyi nilu Eko ti ri oku ẹni to ni ile to wo naa.

Oluwa rẹ ni gbajugbaja akọleta, Femi Osibona.

Oun si ni alasẹ ati Oludari ileesẹ akọleta ati abani ra ilẹ Fourscore.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lati ọjọ Aje, ọjọ Kinni osu Kọkanla ọdun 2021 ti ile alaja mọkanlelogun ti wọn n kọ lọwọ naa si adugbo Ikoyi, ti da wo lulẹ, ni ariwo ti sọ pe ẹni to ni ile naa wa nibẹ.

Odu ni Femi Osibona, kii se aimọ fun oloko ni awujọ awọn to n ta ilẹ ati ile ati awọn to n ra pẹl.

Ẹ wo ohun to yẹ kẹ mọ nipa oloogbe Femi Osibona

Àkọlé fídíò, Mesach Oyediran: Ọba ni Dafidi tó ń lu dùùrù, tó sì kọ sáàmù, ta ni èmi tí kò ní le yin

Ohun pataki nipa Femi Osibona:

  • Femi Fourscore ni ọpọ́ eeyan maa n pe Femi Osibona to ni ileesẹ Fourscore
  • Ọdun 1966 lo dele aye nilu Ikenne nipinlẹ Ogun, tii se ọdun marunfinlọgọta
  • Ile ẹkọ girama Mayflower lo lọ nilu Ikenne lẹyin to pari ile ẹkọ alakọbẹrẹ rẹ tan
  • O kọja si fasiti Croydon nilẹ United Kingdom nibi to ti kẹkọ gboye imọ nipa okoowo ati akoso owona
  • Lọdun 1991 to pada sile, o n ta bata ati asọ kootu lọna ati ri ọwọ mu lọ sẹnu
  • Lọdun 1997 lo bẹrẹ si ni kọ ile ta, to si n bawọn eeyan nla lawujọ se
  • Osibona jẹ ọmọ ẹgbẹ awọn akọleta, NHBRC (National Home Builders Registration Council) ni orilẹ-ede South Africa
  • Bakan naa lo jẹ ọmọ ẹgbẹ Zurich Building Guarantee nilẹ Yuroopu
  • Femi Osibona ni ẹka ileesẹ rẹ si orilẹede South Africa ati Naijiria, to si n kọ ile nlanla kaakiri agbaye
  • Osibona ni akọleta ọmọ ilẹ Afirika akọkọ to kọ ile alaja meje lorilẹ ede UK, to si kọ ile to le ni aadọta niluu London ati Manchester.
  • Ileeṣẹ Fourscore mi lo kọ ile 360 Tower ni Ikoyi ati awọn ile miran niluu Eko
  • Nipari, Osibona jẹ ojisẹ Ọ́lọrun ati ọmọlẹyin Kristi tootọ, to n waasu ihinrere lori ijọ.

Ọpọ eeyan lo ti n se idaro nipa akọni akọsẹmọsẹ akọleta naa to lọ, a si n gbadura pe ki Ọba Oke tẹ si afẹfẹ rere.

Amin iyasọtọ kan

Wọn tí rí òkú Femi Osibona yọ kúrò nínú ilé tó wó ní Ikoyi

Femi Osibona ati ile to da wo

Lẹyin ọjọ kẹrin to ha sabẹ ile to wo ni Ikoyi, wọn ti ri oku Femi Osinbona yọ kuro ninu ile ọhun.

Oṣibọna ni baba olowo to n kọ ile to wo naa ti ọpọ eeyan si ku ninu rẹ ni ọjọ Aje lopopona Gerard ni Ikoyi.

Akọroyin BBC jabọ pe awọn oṣoju mi koro ti ṣaaju sọ pe arakunrin Osibona wa ninu ile naa lasiko to wo ṣugbọn lati igba ti wọn ti n gbe oku jade wọn ko ti ri oku rẹ.

Amọ bayi awọn mọlẹbi rẹ ti sọ pe awọn ti ri oku rẹ ninu awọn ti wọn gbe jade lọjọbọ

Ẹwẹ, Kọmisana ọlọpaa Hakeem Odumosu tun fidi ọrọ yi mulẹ fun BBC pe lootọ ni wọn ti ri oku rẹ.

O ni wọn ti gbe lọ sile iwosan awọn ologun to wa ni Ikoyi.