Ikoyi Collapsed Building: Dele Momodu bẹ̀bẹ̀ adura ki awọn to ha sabẹ ile to da wo jade l'ayọ

Oríṣun àwòrán, delemomoduovation/Instagram
Oniruuru iroyin lo ti n jade sori ayelujara nipa akikanju ọkunrin kan, Wale Bob-Oseni, to fi ilẹ Amẹrika se ibujoko pẹlu iyawo ati ọmọ.
Amọ irinajo to gbe wa silẹ Naijiria lo dabi nnkan, nibi to ti se agbako ile to da wo ni Ikoyi, to si ha si abẹ ilẹ titi di akoko yii.
Ọjọ kinni, osu Kọkànla, ọdún 2021 yìí ni Wale Bob-Oseni, n rinrinajo rẹ pada silẹ Amẹrika to ti wa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọwọ́ tẹ oníṣègùn níbi tó ti ń sin ọmọ tuntun láàyè pẹ̀lú ọfọ̀ àti àyájọ́
- Ọta ìbọn ń já bọ́ láti òrùlé ilé Banji Akintoye
- "Pásítọ̀ onímọ̀ ẹ̀rọ kan àti lébìrà 18 tó kó wá láti Ibafo sì wà lábẹ́ ilé Ikoyi "
- Tinubu, àtúntò Nàíjíríà ni ko wá ná, ko tó du ipò ààrẹ - Pa Adebanjo
- "Bí ọmọ rẹ kò bá gba First Class ní fásitì Ibadan, máṣe yọjú fún ayẹyẹ ìkẹkọọjáde"
- Buhari ti já kulẹ bí ìbò Anambra bá forí ṣánpọn - Onímọ òṣèlú
- Ọkùnrin kan wọ gàù torí ó fi sísọ́ọ̀sì gún aya rẹ̀ pa
Amọ ipe kan to gba lórí agọ rẹ lati ọdọ ọrẹ rẹ, Femi Osibona lo mu ko ya bara duro nibi ile to da wo naa.
Wale Bob-Oseni wa lára àwọn èèyàn tí ilé alájá mọkanlelogun da wo le lórí lagbegbe Ikoyi, nílùú Eko.

Oríṣun àwòrán, Dele Momodu
Ọkunrin naa ti ọjọ ori rẹ kò ju bíi àádọta ọdún lo wa pẹlu awọn èèyàn mii tile da wo lori ni Ikoyi, ti ọrẹ rẹ, Femi Osibona n kọ.
Isẹlẹ ile to da wo naa, ti Wale Bob-Oseni ha sinu rẹ jẹ eyiti o se ni laanu gidigidi nítorí oun ati ẹbi rẹ ko ronu irufẹ isẹlẹ yii rara.
Titi di akoko ti a n ko iroyin yii jọ, kò sí ẹni tó tíì le sọ ibi tabi irufẹ ipo ti ẹni tó n kọ ile ọhun wa ati ọrẹ rẹ yii.
Ilẹ Amẹrika ni Wale Bob-Oseni n lọ, ko to gba ipe lati yọju sí ilé náà, ti ko si pada sile rẹ mọ tàbí lọ sí Amerika to ti pinnu rẹ lati lọ bákan náà.
Nínú fídíò kan to jade lẹyin iṣẹlẹ náà, ni ọkunrin kan ti ọpọ gbagbọ pe òun ni awakọ Wale Bob-Oseni tí n pohunrere ẹkun.
Awakọ naa, ti oun naa wa nibi ile to da wo yii ni "Amẹrika lo n lọ o, èmi ni mo sì n gbe lọ."
Ọpọlọpọ awọn gbajumọ niluu Eko lo ti bẹrẹ sí n tara poro lori isẹlẹ yii tori bi awọn eeyan se ha sabẹ ilẹ tabi ba iṣẹlẹ ọhun lọ.

Oríṣun àwòrán, delemomoduovation/Instagram
Ẹ kunlẹ adura ki awọn to ha sabẹ ile to da wo jade l'ayọ - Dele Momodu
Ogbontarigi akọroyin, Dele Momodu wa lára àwọn èèyàn tí ọrọ ile to da wo náà kan gbọngbọn.
Ṣaaju ni Dele Momodu ti kọkọ ṣabẹwo sile naa ko to da wo, toun ti ẹni tó n kọ ilé náà, to fi mọ Olúwo ti ilu Iwo, Oba Abdulrasheed Adéwálé Akanbi.
Lẹyin iṣẹlẹ naa ni Momodu sọ loju opo Instagram rẹ pé "Ẹ ba mi máa gbàdúrà fún Femi Osibona, Wale Bob-Oseni, atawọn mii to ha sabẹ ile naa to da wo, ki wọn le jade layọ, ki Ọlọrun si tẹ awọn to ti jade laye sí afẹfẹ rere."
Dele Momodu tun fi fídíò kan lede nibi ti awọn ọmọ Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ti sabẹwo si nílé rẹ to wà lorilẹ-ede Ghana.
Gẹgẹ bíi ohun tó sọ, awọn aṣofin ọhun fi akoko naa ṣadura fún àwọn tó fara gba níbi ilé to da wo náà.

















