Sunday Igboho Herbalist: Agbófinró mẹ́fà ló wọ́lé wá gbé ọmọ mi láì mọ́ ibi tó wà

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho Herbalist: Agbófinró mẹ́fà ló wọ́lé wá gbé ọmọ mi láì mọ́ ibi tó wà

O ti to oṣu mẹta bayii ti awọn eeyan kan ti wọn funra si bii ọtẹlẹmuyẹ DSS wọ ile Dada Fasoto Arifanlajogun, ti o jẹ oniṣegun ati Babaláwo Sunday Igboho n'ipinlẹ Ekiti, ti ẹnikẹni ko si mọ ibi to wa.

Iya Dada, Olomitutu Fasoto, ti o jẹ yeye Ọṣun lo sisọ loju ọrọ yii fun akọroyin BBC Yoruba nilu Ikere Ekiti

Yeye Olomitutu ni ẹni ọdun mejidinlọgbọn ni ọmọ oun ti awọn agbofinro naa wa gbe lọ lai fi ẹsun kankan kan-an.

Olomitutu ni ọmọ oun lo jẹ oniwatutu, to si n ṣe iṣẹ iṣegun ibilẹ rẹ pẹlu ibẹru Ọlọrun amọ o jẹ ohun iyalẹnu pe wọn le wa gbe tori pe o n ba Sunday Igboho rin.

O ni oun ti bọ èṣù, ti oun si tun gbe gbogbo igbesẹ to yẹ ki oun gbe gẹgẹ bi ẹlẹsin abalaye amọ to ja si pabo.

O wa ke sawọn ọmọ Naijiria lati gba ọmọ oun silẹ ko le pada sọdọ aya ati ọmọ rẹ, ọmọ ọdun marun.

Nigba ti BBC Yoruba kan si agbẹnusọ fun ileesẹ Ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Abutu Sunday, o ni awọn ko gbọ nipa isẹlẹ naa, o si jẹ iyalẹnu pe lẹyin osu mẹta ni wọn sẹsẹ nileesẹ ọlọpaa sẹsẹ n gbọ.