Sunday Igboho's Priest: Ìyá Babaláwo Igboho ní agbófinró gbé Arifanlajogun láì mọ ibi tó wà láti oṣù mẹ́ta

Oríṣun àwòrán, Dada Arifanlajogun
O ti to oṣu mẹta bayii ti awọn eeyan kan ti wọn funra si bii ọtẹlẹmuyẹ DSS wọ ile Dada Fasoto Arifanlajogun, ti o jẹ oniṣegun ati Babaláwo Sunday Igboho n'ipinlẹ Ekiti, ti ẹnikẹni ko si mọ ibi to wa.
Iya Dada, Olomitutu Fasoto, ti o jẹ yeye Ọṣun lo sisọ loju ọrọ yii fun akọroyin BBC Yoruba nilu Ikere Ekiti
.Yeye Olomitutu ni ẹni ọdun mejidinlọgbọn ni ọmọ oun ti awọn agbofinro naa wa gbe lọ lai fi ẹsun kankan kan-an.
- DSS 20, Sọ́jà 200 àti Babaláwo mẹ́ta ló kọlu ilé Sunday Igboho
- "Àwọn ọ̀dọ́ ti ṣetán láti dá wàhálà sílẹ̀ fún ìdáǹdé Sunday Igboho"
- Àwàdà kẹrí-kẹrì ni ẹ̀sùn ìgbésùnmọ̀mí tí Malami fi kan Sunday Igboho - Ilana omo Oodua
- Ṣé lóòtọ́ ni Sunday Igboho ń gbowó ìgbésùnmọ̀mí lọ́wọ́ agbódegbà Boko Haram kan gẹ́gẹ́ bí Malami ṣe sọ?
- Sunday Igboho fún Abubakar Malami àti ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà lési ẹ̀sùn ìgbésùnmọ̀mí tí wọ́n fi kàn án
O salaye pe gbogbo igbiyanju awọn lati se awari Abọrẹ naa lo ja si pabo, ti gbogbo ileesẹ agbofinro ti awọn lọ si n sẹ pe awọn ko mọ nipa irin ọmọ oun.
O wi pe "ohun gbogbo lo tọka si pe ajọ DSS lo gbe ọmọ mi lọ nitori awọn ajọ ẹṣọ alaabo yoku ni ko si ọmọ oun ni ọdọ awọn, ti awọn ko si mọ ohunkohun nipa rẹ.
Olomitutu ni ọmọ oun lo jẹ oniwatutu, to si n ṣe iṣẹ iṣegun rẹ pẹlu ibẹru Ọlọrun amọ o jẹ ohun iyalẹnu pe wọn le wa gbe tori pe o jẹ babalawo fun Sunday Igboho.
O ni oun ti bọ èṣù, ti oun si tun gbe gbogbo igbesẹ to yẹ ki oun gbe gẹgẹ bi ẹlẹsin abalaye amọ to ja si pabo.
O wa ke sawọn ọmọ Naijiria lati gba ọmọ oun silẹ ko le pada sọdọ aya ati ọmọ rẹ, ọmọ ọdun marun.
Bawo ni Babalawo Sunday Igboho se poora:
Nigba ti oun naa n ṣàlàyé bi iṣẹlẹ naa se waye, Aderonke Apalara to jẹ ana Dada sọ pe awọn ẹṣọ alaabo ti wọn ko wọ aṣọ ara ni wọn wa mu Arifanlajogun.
Apalara ni awọn ẹsọ alaabo naa ti gbogbo wọn jẹ mẹwa lo di ihamọra ogun, ti wọn si wọle wọn pẹlu ọkọ hilux funfun meji.
O fikun pe nnkan bii agogo marun ọjọ kẹrindinlogun oṣu keje ọdun 2021 ni wọn ti wa gbe Arifanlajogun naa.
Àwọn iròyin tì ẹ le ní ìfẹ̀ síí:
- Ọmọ onílẹ̀ mẹ́ta kó sí páńpẹ́ ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn
- Darandaran kan rí ẹ̀wọ̀n gbéré he ní Ekiti
- Nǹkan yan! Pásítọ̀ dáwọn ọmọ ijọ̀ dùbúlẹ̀ lórí pẹ̀pẹ́, ó ń nà wọ́n pẹ̀lú bẹ́lítì
- Bí ìgbẹ́jọ́ Naira Marley ṣe lọ lọ́jọ́ Iṣẹ́gun rèé
- Boko Haram fi tipa fẹ́ mi fún ọkọ àmọ́ ìfẹ́ rẹ̀ gbóná lọ́kàn mi ni ń kò fi sá kúrò
- Kí ló dé tí Fayemi kò fí tẹ̀lé àwọn Gómìnà Yorùbá lọ kí Tinubu nílé?
- Wo àwọn gbajúmọ̀ míràn yàtọ̀ sí Tiwa Savage tí ọ̀rọ̀ fídíò ìbálòpọ̀ wọn ti bọ́ sí orí ayélujára ...
- Ó ṣe é ṣe ká má kópa nínú ìdìbò 2023 tí àtúntò Naijiria kò bá wáyé - Afenifere
- Àwọn amòfin ní ẹ̀yà Igbo dara pọ̀ mọ́ ẹjọ́ tí àwọn àgbààgbà Àríwá pè lórí Kanu àti IPOB
Aderonke ni "nigba ti awọn ẹṣọ naa ri pe awa ẹbi ko jẹ ki wọn gbe Arifanlajogun lọ, ni wọn lo ọgbọn alumọkọrọyi pe agọ ọlọpa ni Okesha ni wọn n gbe lọ, ki a si wa pade rẹ nibẹ.
Amọ nigba ti a de Okesha, ni a to mọ pe irọ funfun balawu ni wọn pa pe ọlọpa lawọn ati pe gbogbo igbiyanju mọlẹbi lati mọ ibi to wa lati oṣu mẹta sẹyin lo ja si asan."
Ki ni ileesẹ ọlọpaa ati DSS ni Ekiti sọ nipa isẹlẹ naa:
Nigba ti ikọ iroyin BBC Yoruba kan si Alukoro ọlọpa n'ipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu, o ni ileesẹ ọlọpaa ko mọ ohunkohun nipa isẹlẹ naa.
O wa rọ awọn mọlẹbi Arifanlajogun lati lọ fi ẹjọ sun lọna to tọ ni agọ ọlọpa to ba sunmọ wọn ju lọ.
Bakan naa, nigba ti a kan si ileesẹ agbofinro DSS to wa nipinlẹ Ekiti, wọn sọ fun BBC Yoruba pe awọn ko le sọ ohunkohun nipa isẹlẹ naa, amọ ka kan si olu ileesẹ awọn to wa nilu Abuja.
Bi ọrọ naa ba si se lọ, a maa mu wa fun yin.


















