Aisha Yerima: Ọdún márùn-ún ni mo fi fẹ́ ọkọ Boko Haram ní Sambisa, ohun tójú mi rí rèé

Aisha Yerima

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Obinrin kan, Aisha Yerima ti salaye fun akọroyin BBC nipa ibagbepọ rẹ pẹlu ikọ Boko Haram lati ọdun 2017 ati bo se sa kuro nibẹ.

Se ni ọpọ Mọlẹbi Aisha Yerima la ẹnu silẹ, ti wọn ko si le pa de nigba ti obinrin naa finnu findọ pada ahamọ Boko Haram lọdun 2017 lẹyin ti awọn ologun tu silẹ nibẹ

Amọ lẹyin ọdun mẹrin, obinrin ẹni ọgbọn ọdun naa sa kuro ni ahamọ Boko Haram, to si pada sọdọ awọn ẹbi rẹ ni Maiduguri.

Ẹni ọdun mọkanlelogun ni Aisha wa, tawọn ikọ Boko Haram fi ji gbe, ti wọn si fi lọkọ fun ọkan lara awọn adari wọn.

Ọkọ rẹ ọmọ ikọ Boko Haram yii lo wa fi ifẹ wọnu ọkan Aisha lati ipasẹ oniruuru ẹbun ati ọrọ ifẹ.

Ọkunrin naa si lo ti lọ jagun pẹlu awọn akẹẹgbẹ rẹ nigba tawọn ologun kọlu ibuba Boko Haram nigbo Sambisa, ti wọn si tu Aisha atawọn iyawo miran silẹ.

Idi ti Aisha fi sa pada sọdọ ikọ Boko Haram:

Ileesẹ ologun seto igbasagbo ọlọdun kan fun wọn amọ Aisha ko lo ju osu mẹrin lọ nibẹ to fi pinnu pe igbe aye oun pẹlu ikọ Boko Haram dara ju ibi toun wa lọ.

"O nira fun mi lati sisẹ oojọ, nnkan le fun mi awọn obi mi si ni mo gbe ara le."

Bakan naa lo nira fun Aisha lati bọ ọmọ ọdun meji to gbe lọwọ eyi to bi fun ọkọ rẹ Boko Haram.

"Mo pe ọkọ mi lori foonu, inu rẹ si dun lati gburo mi. O wa sọ fun mi igba to tun n bọ ni Maiduguri lati wa ra epo bẹntirolu ati gaasi, ti mo si gba lati lọ ba nibẹ.

Lọjọ tawọn mejeeji pade ara wọn, Aisha kuro lọdọ awọn obi rẹ pẹlu ọmọ rẹ lai sọ fun ẹnikẹni, to si mu ẹru diẹ lọwọ.

Àkọlé fídíò, Ooni: A kìlọ̀ fún Sunday Igboho pé kó dákẹ́ àmọ́ kò gbọ́, èébú ló ń bú wa

Ajọyọ pẹlu ibọn yinyin ni wọn fi ki mi kaabọ pada:

Aisha pade ọkọ rẹ nibi ti wọn fi adehun si, to si fun ni owo lati ra awọn asọ tuntun.

Aago meje abọ alẹ ni awọn mejeeji pade pada lọjọ naa nibi ti ọkọ rẹ atawọn ọmọ ikọ Boko Haram mii to to ogun niye ti pade rẹ pẹlu ọkọ bọọsi kan.

Gbogbo wọn si ni Aisha ni wọn dihamọra dẹnu pẹlu ibọn.

"Nigba ta de agọ wa, se ni ariwo ayọ gbalẹ kan, ti inu gbogbo wọn si dun lati ri mi pada, ti wọn si n yinbọn soke lati fi dawọ iduunu."

Aisha bẹrẹ igbe aye rẹ pada bii aya ọga Boko Haram, ko si pẹ lo tun ni oyun ọmọ keji amọ oyun naa wa ni osu meji ni ọkọ rẹ jade laye lasiko ijagudu kan pẹlu awọn ologun.

Ọkọ Aisha ku, to si tun bi oku ọmọ:

O tun se ni laanu pe Aisha bi oyun inu rẹ lẹyin osu meje ti ọkọ rẹ ku amọ ọmọ naa ku ni ọjọ ikunlẹ.

Awọn ikọ Boko Haram yii ni Aisha lẹtọ lati pin ninu ogun ti ọkọ rẹ fi silẹ, ti wọn si duro ki o bimọ, ki wọn to pin ogun naa.

Wọn fẹ mọ boya ọkunrin abi obinrin ni yoo fi oyun inu rẹ bi nitori ilọpo meji ni ogun ti ọkunrin yoo jẹ si ti obinrin.

Ọmọkunrin ni Aisha bi lootọ amọ oku ọmọ lo bi, eyi to ba lọkan jẹ pupọ.

Àkọlé fídíò, 'Mi ò yàtọ sí Krìstẹni tàbí Mùsùlùmí tóun náà da ẹsìn rẹ pọ mọ jíjẹ Dokita, Babaláwo Dókítà l'èmi'

Wọn fi tipa fa Aisha fun ọkọ keji:

Lẹyin ti wọn pin ogun ọkọ rẹ fun tan ni Aisha di olowo rẹpẹtẹ, ti ọpọ awọn ọmọ ikọ Boko Haram si n bi leere pe se oun nikan ni yoo maa da owo ọkọ rẹ na.

Wọn fi tipa tipa fa fun ọkọ keji bi o tilẹ tako igbesẹ naa, ti ọkọ rẹ keji naa si jẹ olokoowo to ni owo lọwọ tori o maa n wa ta ọja fun ikọ Boko Haram ni.

Ko pẹ ni Aisha tun loyun fun ọkọ tuntun, ti ẹru si n ba pe oun tun le padanu ọmọ naa sinu igbop Sambisa.

O wa bẹ ọkọ rẹ pe ko jẹ ki oun maa lọ gbe ni Maiduguri amọ onitọun ko gba fun.

Aisha sa kuro ninu igbo Sambisa pẹlu oyun ninu:

Sugbọn ipinnu lati kuro nigbo Sambisa n le koko si ni ọkan Aisha nitori bi awọn ologun se n dana bo ibuba Boko Haram ninu igbo naa lojoojumọ.

Ni aago mẹta oru ninu osu kẹjọ, Aisha mu ọmọ rẹ atawọn iyawo meji miran to fẹ gbe igbe aye ọtọ, wọn si kuro ninu igbo naa.

Amọ ikọ Boko Haram ri wọn mu, ti wọn si da wọn pada si agọ wọn.

Bakan naa ni ọkọ Aisha gba ọmọ rẹ lọwọ rẹ, to si mu lọ si ibi ti ko mọ, ko maa ba gbiyanju lati sa kuro ni igbo Sambisa mọ,

Bi wọn se n wọ ọmọ naa lọ, Aisha ni nse lo n sunkun pe ki oun mase fi oun silẹ amọ Aisha tun sa lẹẹkeji kuro ninu igbo Sambisa lai mu ọmọ rẹ lọwọ.

Aisha fun eeyan kan ni gbogbo owo to wa lọwọ rẹ lati mu oun at awọn eeyan rẹ jade ninu igbo, to si pada sile awọn obi rẹ.

In awọn aladugbo ati ẹbi rẹ dun lati ri, ti wọn si da owo jọ fun lati maa gbe igbe aye ọtun.

Ko gburo ọkọ rẹ mọ amọ o gbọ pe igun ọlọtẹ Boko Haram miran ti mu, ti ko si le sọ ohun to n sẹlẹ si.

Aisha wa gbadura pe ki Ọlọrun ba oun sọ ọmọ oun pada wa sile amọ oun ko ni lọ si ibudo Boko Haram mọ laelae.

Àkọlé fídíò, ṣé ẹ lè gbàgbá pé Ajá gidi kọ́ leléyìí tẹ́ẹ bá kòó lọ́nà? Àwọn agbárí tó ṣeé bá BBC sọ̀rọ̀