2023 Presidential Election: CAN bẹ olóṣèlú láti máṣe káyà aráàlú sókè lásìkò ìpolongo ìbò

An asaajusin Kristni ati Musulumi

Oríṣun àwòrán, Rev Supo Ayokunle

Awọn adari ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria CAN, ti kilọ fawọn oloṣelu Naijiria lati maṣe da wahala silẹ nipa gbigbe oludije aarẹ ati igbakeji rẹ to jẹ ẹlẹsin kanna kalẹ fun idibo aarẹ 2023.

Ẹgbẹ CAN ni awn ko ni fara mọ pe ki oldije fun ipo aarẹ ati igbakeji rẹ jẹ Musulumi ati Musulumi tabi Kristeni ati Kristẹni.

Aarẹ ẹgbẹ naa Rev.Samson Ayokunle lo fidi ọrọ yi mulẹ lasiko ipade awọn olori ẹgbẹ naa pẹlu igbakeji aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnẹtọ Obarisi Ovie Omo-Agege ni ọfisi rẹ lỌjọbọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni ''nitori idibo 2023 to n bọ lọna a fẹ rọ ẹyin oloṣelu lati maṣe ka araalu laya soke nipa ipolongo ati ọrọ ti yoo ma jade lẹnu yin.

Ilu kan gogo lọwọ ta wa bayi paapa nitori ipenija aabo to wa nilẹ''

Àkọlé fídíò, Ogogo wá sí iléèwé wa, mo kéwì fún un ló sọ mi di èèyàn ńlá lórí ayélujára - Akinwumi Akewi

''Bẹẹ naa la fẹ ki ẹ ri pe lori ipo aarẹ, ẹ ri wi pe deede wa nibẹ. A ko fẹ tikẹẹti Musulumi pẹlu Musulumi tabi Kristẹni ati Kristẹni''

O tẹsiwaju nipa fifi ẹdun ọkan rẹ lori bi eto ọrọ je sẹ dẹnu kọlẹ ati ipa ti eleyi ni lori iṣakoso ilẹ yi to fi mọ inira to n ba araalu lori rẹ.

O rọ ijọba lati wa ọna ti wọn yoo fi mu idẹrun ba araalu.

O ni ''Ọwọngogo nkan to gbode yi n kan ile ijọsin lominu ti pupọ awọn eeyan wa ko si niṣẹ lọwọ.

Bo ti lẹ jẹ wi pe a mọ riri ile aṣofin nipa kikesi awọn ẹka alaṣẹ lati mu iyipada wa, a fẹ ki wọn tubọ pese ọna ti awọn oniṣowo yoo fi ẹ ri iṣẹ ṣe daada.

Lara rẹ ni ki wọn foju fo awọn owo ori kan fawọn to ba n pese ọja labẹle''

Igbakeji aarẹ ile aṣofin agba Sẹnẹtọ Obarisi Ovie Omo-Agege wa dupẹ lọwọ wọn fabẹwo yii, to si ni iru ifikunlukun bẹẹ yoo mu ki ibaṣepọ to gun rege wa laarin CAN ati ile aṣofin Naijiria.

"Ọrọ ẹni ti yoo di ipo aarẹ mu ni Naijiria jẹ eleyi ti ọpọ maa n foju si, paapa nibi ti awọn ti maa n wo ọrọ ẹya ati ẹsin ki wọn to dibo fun ẹnikẹni.

Àkọlé fídíò, Ooni: A kìlọ̀ fún Sunday Igboho pé kó dákẹ́ àmọ́ kò gbọ́, èébú ló ń bú wa

Yatọ si CAN to mẹnu ba ọrọ yii, ni bayi ti ọjọ idibo ti n sunmọ, o ṣeeṣe ki awọn ẹgbẹ mi naa maa dide lori afojusun wọn nipa ẹni ti yoo dipo aarẹ ati igbakeji mu ni Naijiria.

Lọpọ igba awọn ẹgbẹ oloṣelu a maa fẹnukọ laarin ara wọn nipa yiyan musulumi ati Kristeni lati dije dupo aarẹ ati igbakeji labẹ asia wọn.

Iwe ofin Naijiria ko fi ti ẹya tabi ẹsin ṣe nipa ẹni to le du ipo yii tabi ti ẹgbẹ kankan le fa kalẹ.

Amin iyasọtọ kan

Saraki sọ̀rọ̀ lórí bó yá òun lè darapọ̀ APC láti dupò ààrẹ

Bukola Saraki

Oríṣun àwòrán, Facebook/Bukola Saraki

Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja tẹlẹ rẹ, Bukola Saraki ti ṣi aṣọ loju eegun lori bo ya o le fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ lọ APC.

Saraki fi ọrọ yii lede ninu ifọrọwerọ rẹ lori ileeṣẹ amohunmaworan Arise News lọjọ Iṣẹgun.

Saraki ni ko lo boju mu ti oun ba fi PDP silẹ lọ si APC nitori oun kii ṣe oni imọ tara ẹnikan ẹda.

''Lori ibeere wi pe ṣe mi o lo lọ si ẹgbẹ oṣelu APC ti PDP ko ba yan mi gẹgẹ bi oludije aarẹ fun ibo ọdun 2023, ko si ohun to jọ bẹẹ rara.

Mo gbiyanju lati dupo aarẹ lọdun 2015 ninu ẹgbẹ PDP ṣugbọn n ko ni anfani lati ṣe bẹẹ.

Lẹyin naa ni mo jẹ oluṣakoso ipolongo ibo fun Atiku Abubakar to jẹ oludije ipo rẹ fun ẹgbẹ PDP nigba naa.

Mo ṣiṣẹ takun takun fun Atiku ṣaaju ibo ọdun 2015.

Mo ni awọn ọmọ ati ọmọ ọmọ, ohun to jẹ mi logun bayii ni pe ki a fi orilẹede to dara silẹ fawọn ọmọ wa.

Mo fẹ Naijiria ti iṣẹ yoo ti pọ lọpọ yanturu fawọn ọdọ wa ti Eledua jogun ọpọlọ pipe fun un.

Lootọọ ni mo sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ PDP kan maa ya lọ si ẹgbẹ miran amọ iyẹn ko tumọ si pe mo maa ya lọ,'' Saraki lo sọ bẹẹ.

Saraki ko sọ ni pato bo ya yoo dije fun ipo aarẹ lọdun 2023.

O ni bi nkan yoo ti ṣenu ire fun PDP ninu eto idibo to n bọ lo jẹ oun logun bayii gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ PDP.

Saraki ṣalaye pe idi niyii ti oun fi wa lara awọn to n ri si ati pari aawọ to wa laarin awọn ọmọ ẹgbẹ kan.

Gomina ipinlẹ Kwara nigba kan sọ pe lẹyin ti ẹgbẹ ba fẹsẹ mulẹ daadaa ṣaaju eto idibo ọdun 2023 lawọn ọmọ ẹgbẹ to le maa sọ nipa bo ya wọn fẹ dije fun ipo kan tabi omiran.

O ni oun yoo kede ipinnu oun faye gbọ lori bo ya oun yoo dije fun ipo aarẹ lọdun 2023 amọ ko tii to asiko bayii.