Iyabo Ojo: Tiwa Savage fun ní N500,000, àwọn míì fi màálù méjì, ọtí wáìnì ránṣẹ

Iyabo Ojo ati apo paali iwe apejẹ sibi ayẹyẹ iranti ọdun kan mama rẹ

Oríṣun àwòrán, iyaboojofespris/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Yoruba ni bu fun mi, ki n bu fun ọ, ni ọpọlọ n ke lalẹ odo, ka rin, ka pọ, yiyẹ si lo maa n yẹ ni.

Bo se ri fun gbajumọ osere tiata, Iyabo Ojo ree nibayii to n gbaradi fun ayẹyẹ iranti ọdun kan ti mama rẹ, Victori Olubunmi Fetuga dagbere faye.

Nigba to n fi iwe ipe sibi apejẹ naa ransẹ sawọn ọrẹ ati ololufẹ rẹ, paali to da bi apoti ni Iyabo Ojo fi se iwe ipe ransẹ sawọn eeyan yii.

Enoho Peggy Ovire (Ego Oyibo) si lo se afihan awọn eroja to wa ninu apoti naa fun araye ri loju opo Instagram rẹ.

Lara awọn ohun to kun inu apoti paali naa ni asọ ẹbi olomi buluu ati goolu pẹlu gele asọ oke buluu, ọti waini ti wọn tẹ aworan oloogbe naa si lara ati orukọ rẹ.

Bakan naa ni ni ẹrọ to n lo oorun lati sọ saaji batiri foonu wa ninu apoti iwe ipe naa pẹlu iwe ipe gan funra rẹ, ko si si ẹni to gba paali naa, ti ori rẹ ko ni wu.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Ko tan sibẹ o, Bakan naa ni gbaju gbaja akọrin takansufe nni, Tiwa Avage fi ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira ransẹ si Iyabo Ojo gẹgẹ bi ẹbun fun igbaradi ayẹyẹ naa.

Iyabo Ojo funra rẹ si lo sisọ loju ọrọ yii loju opo Instagram rẹ nigba to n ki akọrin naa pe o seun, o ku anawọsi.

Tun wẹ, ni Iyabo tun kede pe ọkunrin kan to pe ni aburo rẹ, Ade Smith ati ileesẹ kan to n ta ẹsọ goolu fi maalu kọọkan ransẹ si lati lo fun ayẹyẹ naa.

Owo ti Tiwa Savage fun Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, iyaboojofespris/Instagram

Bakan naa ni ileesẹ kan to n se bata fi ọpọ ọti waini ransẹ ransẹ si ọmọlooku ọhun, to si n ki gbogbo wọn pe wọn seun.

Ọpọ ololufẹ Iyabo Ojo to fesi si awọn ikede naa lo salaye pe eeyan to lawọ ni Iyabo Ojo funra rẹ, o si ti ran ọpọ eeyan lọwọ sẹyin.

Wọn wa n sọ fun pe oun naa ti da omi siwaju, o di dandan ko tẹ ilẹ tutu nitori ẹni to ba saanu, yoo maa ri aanu gba.

Maalu meji ati ọti waini ti wọn fun Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, iyaboojofespris/Instagram