Oyo priosn break: Nǹkan bíi àádọ́ta èèyàn tó wọ aṣọ dúdú ló kọlu ọgbà ẹ̀wọ̀ Abolongo - Olórí ọdẹ Oyo

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Olori ikọ awọn ọlọde ibilẹ ni Oyo, Taoheed Olanrewaju ti ṣalaye bi awọn oniṣẹ ibi to ṣe ikọlu si ọgbà ẹwọn ṣe tu awọn ẹlẹwọn silẹ.
Arakunrin naa salaye pe awọn agbébọn naa wọ aṣọ dudu ti wọn sì dà aṣọ boju lasiko ikọlu ọhun.
Ninu ọrọ to sọ fun ileesẹ iwe iroyin Nigerian Tribune, Olanrewaju ni nnkan bii ago mẹwaa alẹ ni awọn oṣiṣẹ oun kesi oun pe awọn n gbọ iro ibọn ni ọgbà ẹwọn Abolongo.
- “Ẹkùn Àríwá rí sáà ìṣèjọba Buhari bíi àdánù ní wọn ṣe tako pínpín ipò ààrẹ”
- Pásítọ̀ Olatokunbo Shonubi wọ gàù ní US lórí ẹ̀sùn ṣíṣe ayédèrú ìgbéyàwó 38 fáwọn àjèjì àti ọmọ onílùú
- Ọmọ ''Mummy Calm Down'' di òṣèrè tíátà láti kékeré
- Èèyàn mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n jóná níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀pá epo tó fọ́ ní ìpínlẹ̀ Rivers
- Ṣé lóòtọ́ ni Iskilu Wakili, Balógun Fulani wà lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó sálọ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Abolongo l'Oyo?
- Olórí ìgbìmọ̀ aláṣẹ́ tó ga jù ní Sudan, Ọ̀gágun Burhan ti kéde ìlú ò fararọ
- IPOB kéde kónílé-ó-gbélé ọ̀sẹ̀ kan lásìkò tí ìdìbò gómìnà Anambara yóò wáyé
- "Àwọn ọ̀dọ́ ti ṣetán láti dá wàhálà sílẹ̀ fún ìdáǹdé Sunday Igboho"
- DSS 20, Sọ́jà 200 àti Babaláwo mẹ́ta ló kọlu ilé Sunday Igboho
O sọ pe "Mo ni kí àwọn èèyàn mi lọ sibẹ ni nkan bi ago mẹwaa abọ ku diẹ,a ba awọn oṣiṣẹ aabo ti wọn ti faragbọta, a si gbiyanju lati doola awọn ti a ribi doola."
"Níbi táa gọ pamọ́ si, a ri bi eeyan aadọta ti wọn wọ asọ dudu ti wọn sì dà aṣọ bò oju wọn, o daju pe awọn akoṣẹmọṣẹ ni wọn."
Olanrewaju ṣalaye siwaju si pe awọn lọ dena dé wọn ti awọn sí ribi yìnbọn pa meji ninu wọn.
O ni yato sí àwọn meji yii, oun fúnra oun pa mẹrin ninu wọn ṣugbọn o seni laanu pe gbogbo oku awọn tàwọn ri mu balẹ ni wọn gbe lọ.
"Koda wọn gbe ọkọ bọọsi ti wọn gbe wá salọ pẹlu taya rẹ ti ọta ibọn ba"
Nigba t'awọn akọroyin beere boya o le mọ ẹya ti awọn agbébọn yìí ṣé, o ni ko sí ẹni to le so iru ẹyà ti wọn jẹ.
"Bi mo ba so pe mo mọ ẹyà ti wọn jẹ, iro ni mo pa nitoriti inu okunkun birimu la wa ti wọn sì dà aṣọ bò oju."
O ni awọn ri ti wọn ṣugba èèyàn mẹta kan kuro ninu ọgbà ẹwọn.
"Wọn wà níwájú laarin ati ẹgbẹ awọn mẹtẹtaa yi"
Lakotan, o ni òun lòún ran olori ọgbà ẹwọn náà láti ko awọn ẹlẹwọn to lè ni igba padà sí àhámọ́.
Koda o so pe awon ri ẹlẹwọn mẹrin mu pada nibi ti wọn ti fẹ wọ ọkọ to n ko ero lati Ibadan lọ sí Ogbomosho.














