US Fake Marriage Pastor: Ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún ni ìkọ̀ọ̀kan ẹ̀sùn jìbìtì àti irọ́ pípa tí wọn fi kan Pásítọ̀ gbérù

Oríṣun àwòrán, facebook
Olusọagutan kan ni Maryland lorilẹede Amẹrika, tii se ẹni aadọta ọdun, Joshua Olatokunbo Shonubi ni wọn ti fi ẹsun kan pe o se ọpọ ayederu igbeyawo laarin awọn mẹkunnu nilẹ Amẹrika atawọn ajeji lọna ati gba iwe igbelu.
Wọn fi ẹsun kan Pasitọ naa pe o se magomago loju ọna ati gba iwe igbelu ni Amẹrika, to si n se ayederu igbeyawo, ayederu iwe igbelu ati genje iwe adehun gbigba ile.
Joshua Olatokunbo Shonubi, to tun n jẹ Olatokunbo Joshua Shonubi, ni awọn agbẹjọro ijọba nilu naa wọ lọ sile ẹjọ pe o n lu jibiti nipa igbeyawo ati iwe asẹ iwọlu taa mọ si Visa, to si tun ko awọn genje iwe ẹri awọn ileesẹ ijọba silẹ.
Atẹjade tawọn agbefọba naa fisita ni Shonubi gbe nilu Bowie, to si tun jẹ Pasitọ ijọ New Life City to wa lẹba Hyattsville ni Maryland yii kan naa amọ maili mejila ni ilu mejeeji fi jinna sira wọn.
Atẹjade naa ni lati ọdun 2014 titi di ọdun 2021 ni Pasitọ Shonubi fi se magomago yii, to si gba ẹgbẹlẹgbẹ dọla lati ọwọ awọn ajeji ni orilẹede miran pe oun yoo bawọn seto igbeyawo pẹlu awọn ọmọ ilẹ Amẹrika.
Bakan naa ni wọn tun fi ẹsun kan Shonubi pe gẹgẹ bii Pasitọ, o n gba awọn eeyan ti ko ni agbara lati tọju ara wọn sọdọ rẹ, to si n kọ wọn lati maa se igbeyawo pẹlu awọn ọmọ ilẹ Amẹrika, eyi to ni yoo tete jẹ ki wọn ni iwe igbelu.
Nigba mii, Shonubi yii ni wọn lo maa n seto igbeyawo yii funra ara rẹ nile ijọsin rẹ tabi ko ran tọkọ taya naa lọ si Virginia fun ayẹyẹ igbeyawo nla.
Awọn agbefọba naa ni ni kete tawọn eeyan naa ba ti se igbeyawo tan, ti wọn si san owo nla fun Shonubi, oun ni yoo ba wọn seto iwe ti wọn yoo fi sọwọ si ileesẹ to n ri si ọrọ iwe igbelu, ti yoo si fi adirẹsi rẹ sibẹ, ọwọ rẹ si ni iwe tabi iroyin nipa igbesẹ naa yoo maa de si.
Shonubi yii tun ni wọn ni yoo fi awọn ayederu iwe sọwọ si ileesẹ naa pẹ́lu iwe sọọsi rẹ, ti yoo si sọ nipa bo se mọ tọkọ taya naa si, to si maa n tọ wọn sọna ninu ẹmi ati bi igbeyawo wọn se da lori ifẹ pipe.
Wọn ni o to iru ayederu iwe ẹri bayii bii mejidinlogoji ti Shonubi ti se fawọn ofege lọkọ laya, ti yoo si tun pese ẹbu iwe to fihan pe awọn tọkọ tiyawo naa dijọ n gbe papọ ni.
Ikọ agbẹjọro agbefọba naa ni Shonubi ni ọwọ ti tẹ bayii, to si ti yọju siwaju adajọ ni Baltimore lọjọ, to si seese ko fi ẹwọn ọdun marun marun jura lori awọn koko ẹsun lilu jibiti ati irọ pipa ti wọn fi kan.
















