Anthony Olatunfe: Ọlọ́pàá ní Pásítọ̀ náà ta fóónù ẹni tí wọn ń wá ní ₦1,500

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG
Akẹkọ ileẹkọ fasiti agbele-gboye (Open University) kan, Anthony Olatunfe di awati logunjọ osu kejila ọdun 2019, lasiko ti wọn ran nisẹ lọ si Ilupeju.
Kọmisana ọlọpa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu si ti pasẹ pe ki wọn tanna wadi isẹlẹ naa, to si ti fa iwadii ọhun le ẹka to n gbogun ti iwa idigunjale labẹ ileesẹ ọlọpa, SARS lọwọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Obìnrin tó ń ṣiṣẹ́ ẹrú ní Oman tó bá fẹ́ òmìnira, yóò bá ọ̀gá rẹ̀ ṣùn - obìnrin méjì tó ti oko ẹrú dé
- Ẹ fi ọkàn balẹ̀ lórí àrùn Coronavirus, à ń ṣa ìpa wa láti dènà ìtànkálẹ̀ rẹ̀ - Buhari
- Ẹ́ fún ọmọ Nàíjíríà ní ẹ̀kọ́ tó yè kooro dípò kẹ rán Boko Haram tó ronúpìwàdà lọ kàwé lókè òkun - Serap
- Buhari,nígbà wò ló fẹ́ bá ọmọ Nàìjíríà sọ̀rọ̀ nípa Coronavirus-PDP
- Ìtàn ayé Taiwo Oredein rèé, àgbà òṣèlú tó parí ayé rẹ̀ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n
- Buhari ò, àwáwí rẹ ṣú wa, aáyan ìjọba rẹ̀ mẹ́hẹ lórí ètò ààbò - Ìjọ Aguda figbe ta
- Pa Kasumu,gbajúgbajà òṣèré tíátà Yorùbá jáde láyé
Baba Anthony, Augustine Olatunfe, lo ke gbajare lọ si ọdọ amugbalẹgbẹ gomina ipinlẹ Eko kan, ti ọmọ naa n ba sisẹ pe, oun ko ri ọmọ oun nile, ti onitọun si fi ọrọ yii to awọn ọlọpa leti.
Atẹjade kan ti osisẹ alarena ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Eko fisita lọjọ Aiku ti salaye pe, gbogbo aayan awọn lati se awari Anthony lo ja si pabo amọ awọn ti tọpinpin ẹrọ ibaraẹnisọrọ rẹ lati mọ ibi to wa.

Oríṣun àwòrán, @sportingshina
Eyi si lo mu ki wọn sawari pe, foonu naa wa lọwọ obinrin kan, Monsurat Gbadegẹsin, ẹni ọdun mẹtalelogun. Lasiko to n salaye fawọn ọlọpa, ni obinrin naa ti jẹwọ pe ọkọ afẹsọna oun, Abiodun Abiola lo fun oun ni foonu naa, ti wọn si lọ gbe Abiola pẹlu.
Abiola ni ọkunrin kan, Tolu Olurotimi lo ta foonu naa fun oun, ti wọn si gbe ọkunrin ọhun, ẹni to jẹwọ pe ọwọ Pasitọ ijọ Sẹlẹ kan, Ejiro Ologonla loun ti ra foonu naa. Idi si ree tawọn ọlọpa fi gbe pasitọ yii.
Atẹjade naa ni, lasiko ti wọn n fọrọ wa Ologonla lẹnu wo lo ti n ka pe, lootọ ni oun pade Anthony to sọnu yii leti okun, to si ti yo fun ọti lile, to si n le awọn eeyan kiri eti okun naa.

Oríṣun àwòrán, Others
Lẹyin naa lo ni oun ri Anthony yii, to n bọ asọ to wa lọrun rẹ, bata ẹsẹ rẹ, ati foonu ọwọ rẹ silẹ, ko to gun ọkọ oju omi awọn apẹja kan, to si lọ sori agbami okun, nibi to ti bẹ sinu okun.
Ologonla ni wọn lo sọ pe, oun fi ọrọ naa to awọn agbofinro to wa leti okun leti, toun si tun pe awọn ọlọpa lori aago lati fi isẹlẹ naa to wọn leti.
Amọ sa, lẹyin o rẹyin ni oun ko asọ, bata ati foonu Anthony lọ sile, ti oun si ta foonu rẹ fun Tolu Olurotimi ni ẹẹdẹgbẹjọ (₦1,500) naira.

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG
Ileesẹ ọlọpa sọ pe, gbogbo awọn eeyan ti pasitọ naa darukọ pe oun sọ fun nipa Anthony to wọ okun lọ, ni wọn ko ri ohun kankan to giriki sọ nipa isẹlẹ naa, tawọn agbofinro to wa leti okun si ni ọkunrin naa ko fi isẹlẹ ọhun to awọn leti rara.
"Awọn asọ ati bata ẹni to sọnu naa la ri nile Pasitọ. Lootọ si ni a fidi rẹ mulẹ pe Anthony lọ si eti okun Oniru, ko to di pe o di awati, Pasitọ Ologonla si ni ẹni to ri i kẹyin, bẹẹ ni a ko lee sọ boya ọkunrin ta n wa yii wa laaye abi o ti ku, ti gbogbo ẹri to wa niwaju wa si n fihan pe, Pasitọ naa mọ nkan nipa bi Anthony se di awati."













