World's 500 Influential Muslims: Buhari, Dangote, El-Zakyzaky wà lára Mùsùlùmí tó lààmì laaka lágbàáyé

Awn musulumi to laami laaka julọ ni agbaye

Oríṣun àwòrán, The Muslim 500/Screen shot

Aarẹ Muhammadu Buhari ni wọ̀n ti kede pe o wa lara awọn musulumi to laami laaka julọ jakejado agbaye.

Gẹgẹ bi ẹni to tẹ akọsilẹ iwe nipa awọn musulumi to laami laaka lagbaye naa sita ti wi, ipo kẹrindinlogun ni aarẹ Buhari wa laarin wọn.

Awọn ọmọ Naijiria yoku to tun wa ninu akọsilẹ naa ni Sultan tilu Sokoto, Muhammad Sa'ad Abubakar III, Aminu Ado Bayero ati Sheikh Ibrahim Saleh.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn yoku ni Alhaji Aliko Dangote, Sheikh Dahiru Bauchi, Sheikh Yakubu Musa Katsina, Sheikh Ibrahim Zakzaky, atawọn mii.

Aarẹ Muhamadu Buhari to gba ipo kẹrindinlogun ni ọdun yii si ni wọn lo seese ko gba ipo kẹtadinlogun lọdun to n bọ laarin awọn musulumi to laami laaka lagbaye.

Àkọlé fídíò, Ogogo wá sí iléèwé wa, mo kéwì fún un ló sọ mi di èèyàn ńlá lórí ayélujára - Akinwumi Akewi

"Ẹnikẹni to ba ni agbara ni ọnakọna, boya nipa ti asa ni tabi imọ, abi o ni owo lọwọ, agbara oselu tabi ohunkohun to jẹ agbara to le nipa nla lori awọn musulumi la n ka orukọ wọn bi ẹni to laami laaka julọ lagbaye.

Ba se mu awọn eeyan ta tẹ orukọ wọn sinu atẹjade yii ni ko sọ pe a fi ara mọ ero wọn amọ a se odiwọn bi wọn se lagbara si ni agbaye ni."

Wo awọn Musulumi mẹwa to lagbara julọ ni agbaye:

Agbabọọlu fun ikọ Liverpool, Mohammed Salah, Sadio Mane, Paul Pogba ati Zinedine Zidane wa lara awọn musulumi to laami laaka julọ lagbaye.

Àkọlé fídíò, 'Mi ò yàtọ sí Krìstẹni tàbí Mùsùlùmí tóun náà da ẹsìn rẹ pọ mọ jíjẹ Dokita, Babaláwo Dókítà l'èmi'

Awọn yoku to tun laami laaka lagbaye laarin awọn musulumi niyi:

  • Aarẹ Recep Tayyip Erdoğan ti orilẹede Turkey.
  • Ọba Salman bin Abdul-Aziz Al-Saud, ti orilẹede Saudi Arabia, to tun n se akoso mọsalasi mimọ meji
  • Ayatollah Hajj Sayyid Ali Khamenei, Asaaju orilẹede musulumi ti Iran
  • Ọba Abdullah II Ibn Al-Hussein, tii se ọba Hashemite Kingdom lorilẹede Jordan, to tun n se akoso awọn ibudo mimọ nilu Jerusalem
  • Adajọ Sheikh Muhammad Taqi Usmani, olukọni ati asaaju Deobandi
  • Ọba Mohammed Kẹfa, ọba orilẹede Morocco
  • Ọgagun Sheikh Mohammed bin Zayed Al-Nahyan, Ọmọọba Abu Dhabi ati igbakeji oludari ileesẹ ologun UAE
  • Aarẹ Ayatollah Sayyid Ali Hussein Sistani, Marja ti Hawza, Najaf, Iraq
  • Ọlọla Sheikh Al-Habib Umar bin Hafiz, olukọni ati oludari Dar Al Mustafa, Tarim to wa ni Yemen.
  • Sheikh Salman Al-Ouda, Olukọni ati oniwaasu

O din diẹ ni biliọnu meji awọn musulumi (1.9 billion) to wa ni agbaye loniii, ti wọn si ko ida mẹrindinlọgbọn awọn eeyan to wa lorilẹ aye.

Bakan naa la le ni awọn musulumi yii lo ko ida kan ninu mẹta awọn eeyan to wa nile aye.

Gẹgẹ bi awọn to se akọsilẹ iwe naa ti wi, "lara awọn eeyan to laami laaka naa ni orilẹede wọn, ni wọn tun wa lara awọn musulumi to wa lagbaye.