Richest Beggars: Àsírí ọlà àwọn oníbárà tó lówó jùlọ ní àgbáyé rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iye ti osisẹ kọọkan n ri mu wọle labẹle nii ṣe pẹlu agbegbe tabi ilu to n gbe, ti awọn miran ko si pa ju ẹgbẹrun marun Naira si ẹgbẹrun marun un dọla lọ ni oṣooṣu tabi ọdọọdun.
Amọ iyalẹnu lo jẹ wi pe a ri awọn to n ṣe agbe, ti wọn n tọrọ owo kaakiri agbaye, ti wọn si ni owo ju awọn to n ṣiṣẹ oojọ lọ.
Iwadii fihan pe a ri awọn onibara ti wọn jẹ ọlọla, ti wọn si lowo bii ṣẹkẹrẹ, to si jẹ ni idi titọrọ owo yii ni wọn ti di ọlọla.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kìí ṣe nǹkan ìtìjú pé èmi ni mò ń gbọ́ bùkátà ẹbí mi - Nkechi Blessing
- Àwọn agbébọn ya wọ ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Oyo, wọ́n tú àwọn ẹlẹ́wọ̀n sílẹ̀
- Sunday Igboho ní òun tí gbúró olóṣèlú kan tó fẹ́ fi orúkọ rẹ̀ gbokùn lọ́dọ̀ ààrẹ, òkò ọ̀rọ̀ tó fi ránṣẹ́ síi nìyí
- Gbẹgẹdẹ fẹ́ gbiná láàrín Oluwo àtàwọn ìgbìmọ̀ Ìmáàmù àti Àlfáà ilẹ̀ Yorùbá, wọ́n ní Oluwo ń kọjá àyè rẹ̀
- Ẹ fi ọkàn balẹ̀, a o ṣàfihàn gbogbo àbájáde ìwádìí ìgbìmọ̀ Endsars - Babajide Sanwo-Olu
- Àwàdà kẹrí-kẹrì ni ẹ̀sùn ìgbésùnmọ̀mí tí Malami fi kan Sunday Igboho - Ilana omo Oodua
Pupọ ninu awọn to n tọrọ bara, ti wọn jẹ ọlọla yii wa lati orilẹede India, mẹwa ninu awn alagbe to lowo ree amọ ti wọn si n tọrọ agbe jẹun.
Bharat Jain:
Bharat Jain, ẹni ọdun mẹtalelaadọta yii wa lati ilu Mumbai, lorilẹede India, ti o si jẹ gbajugbaja onibara ti awọn eniyan mọ ni agbegbe Azad Maidan or Chhatrapati Shivaji Terminus ni Mumbai.
O kere tan owo to n pa wọle ni ojoojumọ laarin wakati mẹjọ si mẹwaa to fi n tọrọ bara yii jẹ ẹgbẹrun meji owo ilẹ India, to si le ni ẹgbẹrun kan dọla ni oṣooṣu, ti eyi ju owo oṣiṣẹ lọ lorilẹede India.
Ile nla meji lanti lanti ni Arakunrin Jian kọ ti awọn eniyan n gbe ibẹ, to si n mu owo to le ni ẹgbẹrun mẹwaa owo ilẹ India wọle fun un ni oṣooṣu.
Eisha ara Saudia Arabia:
Eisha to jẹ ẹni ọgọrun ọdun yii jẹ afọju to lo pupọ ninu igbe aye rẹ to le ni aadọta ọdun lati fi tọrọ bara, ti ọpọ eniyan si mọ ọ ni agbegbe to wa.
Eisha to doloogbe ni ọdun 2014 lo fi owo gọbọi silẹ fun awọn alaini, eleyii to ya ọpọ eniyan lẹnu.
Nitori ọpọlọpọ ohun ini to fi mọ ile, goolu, ẹgba ọrun ati ti ọwọ lo fi silẹ paapaa ni agbegbe Al-Balad ni Jedda, lorilẹede Saudia Arabia.
Awọn owo to fi silẹ yii le ni biliọnu mẹwaa owo ilẹ okeere, to si fi ọrọ ikẹyin silẹ pe awọn alaini ni ko ma a gbe ile ti oun fi silẹ.
Simon Wright:
Gbajugbaja onibara ni Simon Wright ni agbegbe Putney High Street, ni London, to si jẹpe aṣọ akisa lo ma n wọ pẹlu akọle ''Mi o nile, ebi si n pami'' lọwọ rẹ.
Fun ọdun mẹta, ni ojoojumo ni o ma n joko sibẹ titi di irọlẹ.
Ọlọpaa ti orukọ rẹ n jẹ Oliver lo ri ni alẹ ọjọ kan to si saanu re, lai mọ ibi to n gbe.
Amọ iyalẹnu lo jẹ fun un pe ile nla ni Simon Wright n gbe, eleyii to mu ki ọlọpaa naa fi panpẹ ọba gbe.
Wọn mu lọ si ileẹjọ, ti adajọ si ni ko gbọdọ tọrọ bara mọ, amọ lẹyin ọsẹ kan o tun pada si agbegbe miran lati lo ma a tọrọ bara.
Ọrọ naa su adajọ ni wọn ba ju si gbaga, ti wọn ko si gba beeli rẹ mọ, amọ iwadii fihan pe o kere tan ẹgbẹrun lọna aadọta pọun ni ọwọ to n wọle fun un ni ọdọọdun, eleyii to ma fi n jẹ igbadun ni alaalẹ ni awọn ile igbafẹ.
Krishna Kunar Gite:
Ọmọ orilẹede India miran to tun wa lati ilu Mumbai to gbajumọ fun titọrọ bara ni Krishna Kumar Kite.
Ọpọlọpọ eniyan lo ma n ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi akinkanju eniyan to mu iṣẹ titọrọ owo gẹgẹ bi iṣẹ oojọ rẹ.
Ko gbẹyin ninu awọn onibara to ni owo bii ṣẹkẹrẹ, o tilẹ gba aburo rẹ gẹgẹ bi akapo isuna rẹ lori iṣẹ bara to yan laayo gẹgẹ bi iṣẹ oojọ rẹ.
Sambhaji Kale:
Ọpọlọpọ ẹlomiran to n lọ si agbegbe Mumbai ko lọ lati lọ wa iṣẹ, niṣe ni wọn lọ wo arakunrin Sambhaji Kale to jẹ gbajugbaja onibara.
Sambhaji ba iṣẹ titọrọ owo ni ile ni, ti awọn ẹbi rẹ mẹrin si jẹ ilumọọka onibara to n pa to ẹgbẹrun owo ile India wọle ni ojoojumọ.
Ko tan si bẹ, Sambhaji ni awọn idokowo pẹlu awọn ileeṣẹ nla nla lagbaye ti owo si n wọle fun un lore-koore.
Bakan naa ni ile nla, to fi mọ ile ati ọkọ ko gbẹyin ninu awọn ohun ini rẹ.
Saravatia Devi:
Gbajugbaja onibara ni agbegbe Patna ti o si jẹ ọkan lara awọn ọlọla to n tọrọ bara ni agbaye.
Awọn eniyan mọ si ọga-ọga ni agbegbe to ti n tọrọ bara, ti ko si ni ẹni to le e gbena woju ẹkun wa sibẹ lati wa tọrọ owo.
O ti le ni ọdun marundinlogoji to ti n ṣiṣẹ yii, pẹlu owo atojutosi to wa ni apo iṣuna ni ile ifowopamọsi rẹ.
Opo eniyan mọ Devi si pe o fẹran lati ma a rin irinajo paapaa lọ si awọn ilẹ mimọ lati igba de igba.
Ohun ti o jẹ iyalẹnu ni pe kii san owo tikẹẹti ninu ọkọ nitori o jẹ aparaba, ti yoo si tun tọrọ bara titi yoo fi de ibi to n lọ.
Massu:
Ilu Mumbai naa ni Massu n gbe ti ọpọ eniyan si mọ ọ nibẹ gẹgẹ bi arakunrin ẹni ọgọta ọdun to n tọrọ bara.
Aṣọ to ti ya, pẹlu omije loju ni o ma fi n tọrọ bara, eleyii ti o jẹ ki o ṣoro fun awọn eniyan lati maṣe fun ni owo.
Lati aago mẹjọ alẹ si aago meji tabi mẹta oru ni Massu ma n ṣiṣẹ , to si n ri o kere tan ẹgbẹrun kan aabọ si ẹgbẹrun meji lojoojumọ.
Amọ ohun to yanilẹnu pe, ki ilẹ to su ni Malana Khan to n di Massu lalẹ ma n jade, ti yoo si wọ aṣọ bi ẹni to n lọ si ileeṣẹ ijọba nla pẹlu ọkọ bọgini.
Ohun ti Malana ma n ṣe nipe, yoo wo ọkọ bọgini ati aṣọ mimọ rẹ de ibi to ti fẹ lọ tọrọ bara, ti yoo si paarọ aṣọ si eleyii ti yoo sọ ọ da Massu lalẹ.
Bakan naa ni ko si ẹnikẹni to le e ba du agbegbe naa gẹgẹ bi oni bara, pẹlu ile nla nla ati dukia to yanturu to ti ni, ni idi titọrọ bara yii.


















