Ilorin Cripple Couple: Ọṣẹ ìfabọ́ ni tọkọ-taya tó ní ìpèníjà ẹsẹ̀ ń tà láti bọ́ ara wọn àti ọmọ mẹ́ta

Àkọlé fídíò, Ilorin Cripple Couple: Ọṣẹ ìfabọ́ ni tọkọ-taya tó ní ìpèníjà ẹsẹ̀ ń tà láti bọ́ ọmọ mẹ́ta

Yoruba ni isẹ Oluwa, ko si ẹni to ye, awamaridi si ni pẹlu.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu tọkọ-taya kan nilu Ilorin, ti wọn ni ipenija ẹsẹ, ti wọn ko si le rin bo se yẹ.

Nurudeen Oseni ati aya rẹ yii, Kudirat, ni wọn pade ara wọn nibi eto kan ti wọn se fun awọn akande ẹda nilu Ilọrin, ti wọn si gba lati fẹ ara wọn.

Bi o tilẹ jẹ pe Kudirat ni oun kọkọ yari lati se aya fun ẹni to ni ipenija bi ti oun amọ o ni oun ko kabamọ pe oun fẹ ọkọ oun.

Obinrin naa ni ọkọ oun n tọju oun debi pe o loju abarapa to le se ju bẹẹ lọ fun aya rẹ.

Tọkọ-taya Oseni, ti Ọlọrun fi ọmọ mẹta jinki wọn, ti ọkankan awọn ọmọ yii ko si ni abuku kankan lara, ti awọn mejeeji si leri leka pe awọn ko ni se agbe jẹun laelae.

Nurudeen ni ọsẹ ifabọ ni oun n po fun tita, eyi ti oun fi n bọ aya atawọn ọmọ oun, kaka ki oun si se agbe jẹun, oun yoo yaa tẹpa mọ isẹ oun ni.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni tọkọtaya Oseni sọ iriri wọn nipa bi awọn eeyan se maa n dẹyẹ si wọn ni awujọ, bẹẹ ni wọn parọwa si awọn eeyan lati maa ri awọn akanda ẹda bii eeyan gidi gẹgẹ bi wọn ti n wo abarapa.