Lamellar Ichtyosis: Kóòmù ni wọ́n fi ń họra fún Amida nítorí bí àwọ̀ rẹ̀ ṣe rí
Arun ti ko gboogun, ki Eledua ma fi kan wa.
Bẹẹ lo jọ pe ọrọ ọmọdebinrin kan ti BBC ṣe alabapade ti ṣe ri nitori arun to mu ki awọ rẹ maa ṣi bi ti ẹja.
Arabinrin Latifat Sulaiman ni Eledua fi ọmọ yi kẹ ṣugbọn lati igba to ti ni oyun rẹ sinu ni o ti n mọ inira.
- Genesis Global: Sáká lara Woli Israel Ogundipe dá, kìí ṣe àìlera ló mú kí wọn fi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n
- TAMPAN pàṣẹ pé 'director' kankan kò gbọdọ̀ pe Nkechi Blessing àti Adams Kehinde sí iṣẹ́ mọ́
- Wọn ò bí Baba Ijesha dáa kó sọ pé kò mọ mí rí - Agbẹjọ́rò Adesina Ogunlana
- Àbàwọ́n funfun ló sún Temilola di arìnrìnoge Vitiligo
- Leprosy Day: 'Kọ̀ńgílá ni mí kí ń tó di adẹ́tẹ̀ ni 1996'
- Ojú mi gún régé àmọ́ wọ́n ń sá fún mi - Arẹwà Àkàndá
- ‘Mo ké bòòsí tòò bí mo ṣe bí ìbejì, ti ọ̀kan jẹ́ àfín, ìkejì jẹ́ dúdú’
- 'Mo lè fi ẹsẹ̀ mi jẹun, fọṣọ, mó tún lè fi gbá ẹni tó bá ṣẹ̀ mí létí'
''Niṣe ni inu mi maa n gbona nigba ti mo loyun Hameeda. Nigba ti wọn yoo yọ ọ jade naa bi igba pe o jade lati inu omi gbona ni''
Awọn onimọ iṣegun Dokita Ayesha Akinkuugbe pe orukọ aarun to n mu ki awọ Hameeda maa ṣi bi ti ẹja yi ni Lamellar Ichtyosis.
Oniṣegun itọju awọ ara yi tẹsiwaju pe o ṣọwọn ki eeyan to ri iru rẹ ko mu eeyan.

Koko kan pataki ti wọn sọ fun BBC ni pe ko ni oogun ti wọn le fi wo o itori pe ko le lọ lara ẹni to ba mu.
Idẹyẹsi ati itabuku jẹ nkan ti arabinrin Latifat Sulaiman n koju nitori ipenija to de ba ọmọ rẹ yii.
O ṣalaye pe ko le lọ si ileewe mọ nitori awọn akẹgbẹ rẹ maa n fi ṣe yẹyẹ lọpọ igba ni.
''Iṣẹ ransọransọ ni mo n ṣe ṣugbọn nitori Hameeda pupọ awọn alabara mi ni ko wa si ṣọọbu mi mọ''
Lọwọlọwọ inu inira ni Hameeda wa nitori awọ rẹ a maa yun ti o si ni lati maa fi koomu họ ara.
Yatọ si eleyi, o tun n ko ipenija oju ati ẹsẹ rẹ ti wọn ko duro deede.
