Vitiligo: Síkẹ̀ẹ̀tì tó gùn ni mo máa ń wọ̀ bíi eégún tórí yẹ̀yẹ́

Àkọlé fídíò, 'Àjẹ́, eégún, kí ni wọn ò pè mí tán tórí Vitiligo lára mi'

Wọ́n fi itiju karun, wọn jade sita nigba ti wọn ri ẹlẹgbẹ wọn loke okun t'oun naa ni iru abawọn yii lara to si di di gbajugbaja arinrin oge.

Temilola OmoobaJesu ati Kehinde Taiwo ṣaa dede ri i ti awọ ara wọn bẹrẹ si ni yi pada lọjọ kan.

Temilola ri i funra rẹ ṣugbọn Kehinde ko tilẹ ṣakiyesi bi ko ṣe igba ti ọga rẹ kan nile iwe bi i pe ki lo ṣe e nibi to da bii pe eṣo gun un lara...

Ọpọlọpọ ero lo maa n wa sọkan awọn to ba ri iru ayipada awọ ara yii lara ẹlomiiran ati awọn to ṣẹlẹ lagọ ara wọn gan.

Alebu ati ohun ti wọn n foju ri ladugbo kii ṣe kekere.

Ni ọpọlọpọ igba, wọn a ti rin jina de ibi ti ko yẹ ki wọn to mọ pe kii ṣe ọwọ aye bi ko ṣe pe ni ilana ilera, Vitiligo maa n ṣẹlẹ.