Toma Unu: Ọmọbìnrin tó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ ya àwọran nítori pe ó ni ìpènija ọpọlọ

Àkọlé fídíò, Toma Unu: Ọmọbìnrin tó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ ya àwọran nítori pe ó ni ìpènija ọpọlọ

Toma, ọmọbinrin tó n fi ẹṣẹ rẹ̀ ya àwọran tó jojú nigbese.

Toma Unu jẹ ẹni ìwúrí pẹ̀lú bí kò ṣe ro ti ìpèníjà rẹ̀ tó sì ń ṣe ohun ribi ribi to tayọ òye ènìyàn.

Láti ǹkan bii ọgbọn ọdun ni Toma tí ń ba àìsàn to jẹ mọ ọpọlọ yí nítori pe bẹ́ẹ̀ ni wọn se bii.

Bawo ni Toma se n gbe igbeaye rẹ̀ pẹ̀lú ailera yii?

Sùgbọ́n nígbà ti ó ri pe òun ko le lo ọwọ oun, ló ba bẹ̀rẹ̀ si ni kọ́ bi wọn se n fi ẹsẹ se orisirisi ǹkan.

Toma le fi jẹun, tẹ fóònù, bákan náà lo fi n ya aworan.

Toma sọ pe Olọrun ni ayaworan àkọkọ àti pe yiya aworan ti ran oun lọwọ láti fi èrò ìnu oun han ní ọpọ igba.