2023 election date: INEC kéde ọjọ́ tí ìdìbò sípò Ààrẹ, gómìnà àti ilé aṣòfin ọdún 2023 yóò wáyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n ri si eto idibo ni Naijiria, INEC, ti kede awọn ọjọ ti idibo gbogbogbo ọdun 2023 yoo waye.
Alaga ajọ naa, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu lo kede awọn ọjọ naa nibi ipade awọn akọroyin kan niluu Abuja.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, idibo sipo Aarẹ ati idibo sipo ile igbimọ aṣofin agba yoo waye lọjọ Abamẹta, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2023.
- Kí ni NATO ń ṣe sí ìkọlù Russia sí Ukraine?
- INEC kéde ọjọ́ tí ìdìbò sípò Ààrẹ ọdún 2023 yóò wáyé
- Ẹ gbàgbé pé mo lọ gba ìtọ́jú ní London, mo ní ọpọlọ pípé láti tukọ̀ Naijiria - Tinubu
- Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ń pèsè iná mọ̀nàmọ́ná olówó pọ̀ọ̀kù,wo ọgbọ́n tó dá síi
- Kíni ìkọlù Russia sí Ukraine ń se lórí búrẹ́dí títà àti rírà ní ilẹ̀ Adúláwọ̀?
- Ṣé lóòótọ́ làwọn ọ̀dọ́ ìlú Ubiaja dá adigunjalè tó jí owó ní báńkì lọ́nà ní ìpínlẹ̀ Edo?
- Igbo Olodumare rèé, níbi tí Ìgbín ti tóbi ju Ìjàpá lọ
- Ìwádìí tí tú àṣírí bí ọlọ́pàá àti ológun ṣé n lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn jàǹdùkú-Gómìnà El Rufai
Nigba ti idibo sipo gomina ati ile igbimọ aṣofin ipinlẹ yoo waye lọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun 2023 kan naa.

Oríṣun àwòrán, INEC
Yakubu sọ pe awọn ọjọ tuntun naa wa ni ibamu pẹlu ofin eto idibo ni Naijiria to sọ pe awọn gbọdọ kede ọjọ idibo laarin ọtalenigba ọjọ (260) ṣaaju ọjọ idibo naa.
O fikun pe awọn yoo kede bi eto idibo naa yoo ṣe waye laipẹ.
Ninu atẹjade ti INEC fi ṣọwọ si awọn akọroyin lọjọ Abamẹta, INEC ni gbogbo ẹgbẹ oṣelu ti yoo ba kopa ninu eto idibo naa gbọdọ ti ṣe eto idibo abẹnu wọn, ki wọn si ti yanju gbogbo aawọ to ba ṣẹyọ larin ọjọ kẹrin, oṣu Kẹrin, si ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, ọdun 2022.

Oríṣun àwòrán, InEC
Ọjọ ti iforukọsilẹ oludije sipo Aarẹ ati ile igbimọ aṣofin yoo wa sopin jẹ laarin ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹfa, si ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹfa kan naa ninu ọdun 2022.
Bẹẹ naa ni ti awọn to n dije du ipo gomina yoo wa laarin ọjọ kinni, oṣu Keje, si ọjọ karundinlogun, oṣu Keje, ọdun 2022.













